"Kó tó di ọjọ́ Kérésì la ti fẹ́ yín àdó olóró mọ́ àwọn agbébọn, síbẹ̀, Amẹrika ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò"

Aarẹ Donald Trump wọ kootu alawọ buluu pẹlu tai lọrun rẹ

Oríṣun àwòrán, US Department of Defense/Anna Moneymaker/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Akọwe ileeṣẹ ologun orilẹede Amẹrika, Pete Hegseth, ti sọ pe Amẹrika yoo tun yin ado mii sawọn agbesunmọmi lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria.

Ikede yii waye lẹyin ado oloro ti ileeṣẹ ologun Amẹrika yin si akata awọn agbesunmọmi ni Sokoto lalẹ ọdun Keresimesi.

Hegseth sọ loju opo X rẹ pe ''Aarẹ Donald Trump ti kilọ ṣaaju wi pe iṣekupani awọn kristẹni ni Naijiria gbọdọ dopin.

Ileeṣẹ ologun Pentagon ko fi igba kankan tura silẹ, ẹgbẹ agbesunmọmi ISIS naa si ti mọ bayii ni Naijiria.

Awa, a ṣẹṣẹ bẹrẹ ni, Amẹrika ṣẹṣẹ n mẹyẹ bọ lapo ni.

A dupẹ lọwọ ijọba Naijiria fun atilẹyin ati iranwọ wọn lori ado oloro ti Amẹrika yin sawọn agbesunmọmi ni Naijiria.''

Ẹwẹ, ṣaaju lọjọ Ẹti ni minisita fọrọ ilẹ okeere ni Naijiria, Yusuf Tuggar, sọ pe ajọṣe ijọba Amerika ati Naijiria ni ado oloro to dahun ni Sokoto.

Aarẹ Trump naa sọ pe lati aarin ọsẹ l'Ọjọru ni ileeṣẹ ologun Amẹrika ti fẹ yin ado oloro naa sawọn agbesunmọmi ni Naijiria.

Amọ, Trump sọ pe oun loun paṣẹ fun wọn pe ki wọn duro di ọjọ Ẹti ki wọn to yin in.

Wọn o lero wi pe ado oloro naa n bọ, o bawọn lojiji - Trump

Trump ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe wi pe ''ileeṣẹ ologun ko ba ti yin ado oloro naa ṣaaju akoko ti wọn yin in.

Amọ, mo ni rara, ẹ jẹ ka duro ki a fi ṣe ẹbun ọdun Keresimnesi.

Wọn o tiẹ lero wi pe ado oloro naa n bọ, o ba wọn lara gan an, gbogbo akata wọn lo jona raurau.

Naijiria jẹ orilẹede ti oniruuru ẹsin wa, awọn musulumi ni Naijiria ko ida 53% nigba tawọn kristẹni ko ida 45%.

Iwa ipa sawọn kristẹni ni Naijiria ti di nnkan to n kọ ijọba Amẹrika lominu eyi ti wọn ri bii inunibini awọn alakatakiti ẹsin islam sawọn kristẹni.

Ọpọ awọn ọmọlẹyin Trump lo ri ado oloro ti Amẹrika yin sawọn agbesunmọmi ni Sokoto gẹgẹ bii igbesẹ to dara.

Amọ, ijọba apapọ ti sọ pe ati kristẹni ati musulumí lawọn agbesnmọmi n ṣekupa ni Naijiria.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Gumi fọnmú lórí ìkọlù ọmọ ogún Amẹ́ríkà sáwọn agbésùnmọ̀mí ní Sokoto, ó ní Ìgbésùnmọ̀mí yóò burú jáì si

Sheik Ahmad Gumi wọ aṣọ Alfa aláwọ̀ búlúù, we láwàní funfun, fi ìgò sójú, jókòó ní yàrá igbalejo rẹ.

Gbajúmọ̀ onímọ̀ nípa ẹṣin Islam kan, Sheikh Ahmad Gumi tí rọ ààrẹ Bola Tinubu láti tètè fòpin sṣí àjọṣepọ̀ táwọn ológun ń ṣe pẹ̀lú ìjọba Amẹ́ríkà.

Gumi fi ìkéde yìí sójú opo Facebook ni àárọ̀ ọjọ́ Ẹtì nítorí ìkọlu tí ọmọ ogún Amẹ́ríkà ṣe nilu Sokoto sáwọn agbésùnmọ̀mí.

Gumi wá bù ẹnu atẹ lu ìkọlù sáwọn agbésùnmọ̀mí ISIS náà, ó sì kìlọ̀ pé ìkọlù sáwọn agbésùnmọ̀mí yìí lè dunkoko mọ òmìnira Nàìjíríà, tí ètò ààbò tó mẹ́hẹ yóò sì burú jáì sì.

"Ìkọlù ojú ofurufu nìkan kò lè fòpin siwa ìgbésùnmọ̀mí, ó yẹ kí Naijiria gbọkan le àwọn òagbófinró tiẹ̀ dípò kó máa bẹ ọ̀wẹ̀ láti ìta"

Onimọ nipa ẹṣin Islam náà ṣàlàyé pé báwọn ilẹ̀ òkèèrè bá dá sí ọrọ Naijiria, ó lè sọ orílẹ̀èdè yìí di ibùdó ogún.

Bákan náà, ó ní ìgbésẹ̀ yìí lè pín orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni ìlànà ẹ̀sìn èyí tó le mu ẹmi ọ̀pọ̀ ọmọ Naijiria lọ.

"Ìkọlù láti ojú ofurufu nìkan kò lè fòpin siwa ìgbésùnmọ̀mí, ó sì yẹ kí ilẹ Naijiria gbọkan le àwọn òṣìṣẹ́ agbófinró tiẹ̀ dípò kó máa bẹ ọ̀wẹ̀ láti ìta.

Àṣẹ wo gan nílẹ̀ Amẹ́ríkà ni lati da si ọ̀rọ̀ Naijiria, maa daba pé yóò dára ká béèrè fún atilẹyin ológun lọdọ àwọn orílẹ̀èdè bíi China, Turkey tàbí Pakistan."

Gumi tẹsiwaju pé ìkọlù tí ilẹ Amẹríkà ṣe yìí ló fi kọlu ikọ agbésùnmọ̀mí ISIS tí wọn fẹ̀sùn kan pé wọn ń dójú ìjà kọ àwọn Kristẹni.

"Àjọṣe láàrin ológun Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà ni ìkọlù sáwọn agbésùnmọ̀mí tó wáyé lálẹ́ ọjọ́ Kérésì, kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ẹ́sìn"

Iná sọ nibudo àwọn agbésùnmọ̀mí lasiko ìkọlù àwọn ológun Amẹ́ríkà.

Oríṣun àwòrán, US State Department

Ileeṣẹ ìjọba to wa fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè tí fìdí rẹ mulẹ pe àjọṣepọ̀ ńlá ló wáyé láàárín àwọn ológun Nàìjíríà àti ti Amẹ́ríkà.

O ni ifọwọsowọpọ ikọ̀ ológun orílẹ̀èdè méjèèjì náà sì lo fa àṣeyọrí ìkọlù sáwọn agbésùnmọ̀mí tó wáyé lálẹ́ ọjọ́ Kérésì.

Atẹjade kan tí iléeṣẹ́ to wa fọrọ ílẹ̀ òkèèrè fisita laarọ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹrindinlọgbọn oṣù Kejìlá ọdún 2025, èyí agbẹnusọ ileeṣẹ náà, Kimiebi Ebienfa buwọlu, lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí.

Ọrọ ti ileeṣẹ to wa fọrọ ílẹ̀ òkèèrè ni Naijiria fisita

Oríṣun àwòrán, Ministry of foreign affairs

"Ìkọlù sáwọn agbésùnmọ̀mí kò ní nǹkan ṣe lórí bóyá èèyàn kan jẹ Kristẹni àbí Musulumi"

Atẹjade náà ni àwọn aláṣẹ Naijiria sì ń sọ̀rọ̀ pọ pẹlu awọn alatilẹyin rẹ nílẹ̀ òkèèrè, tó fi mọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

"Nibamu pẹlu ìlànà ni agbaye, lára àwọn ọ̀nà tí a ń gbà ní ifowosowopo ni ṣíṣe pàṣípààrọ̀ Ìmọ̀, akoso, àti àwọn ọ̀nà miran to wa lábẹ́ òfin èyí tó dé ibọwọ fún òmìnira orílẹ̀èdè kọọkan."

Atẹjade náà wà fọwọ́ gbaya pe gbogbo aáyán rẹ láti gbógun tawọn agbésùnmọ̀mí ni yóo tẹle ìlànà òfin agbaye.

" A máa dáàbò bo àwọn aráàlú àti ìṣọ̀kan Naijiria, tí a sì mú ẹtọ àwọn aráàlú lokunkundun"

Iléeṣẹ́ náà wà tẹnumọ pé ìkọlù àwọn agbésùnmọ̀mí ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò ní nǹkan ṣe lórí bóyá èèyàn kan jẹ Kristẹni àbí Musulumi.

Àwọn ọpọ agbébọn to dá aṣọ bójú na ìbọn wọn sókè.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army

Ṣáájú là tí fi tọ yín létí ni wákàtí díẹ̀ sẹ́yìn pé ikọ̀ ológun orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà tí kọlu àwọn agbésùnmọ̀mí ISIS ní Nàìjíríà.

Ààrẹ Amẹ́ríkà, tíí tún ṣe adari àgbà fún iléeṣẹ́ ológun Donald Trump fúnra rẹ lo kéde bẹẹ làwọn ojú òpó ayélujára rẹ.

"Ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá orílẹ̀èdè Nàìjíríà sì ni ìkọlù náà tí wáyé"

Trump ṣàlàyé pé òun gẹ́gẹ́ bí olùdarí àgbà fún iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà, lo pàṣẹ fáwọn ológun orílẹ̀èdè náà láti kọlu àwọn ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ náà.

Ẹkùn ìwọ̀ oòrùn àríwá orílẹ̀èdè Nàìjíríà sì ni ìkọlù náà tí wáyé.

“Ní ẹkùn Naijiria náà, làwọn ikọ̀ agbésùnmọ̀mí yìí tí ń pa àwọn alaisẹ, pàápàá àwọn Kristẹni tí kì lẹ́sẹ̀ lọrun.

Ikọlu sawọn Kristẹni náà lágbára débi pé ń ko tíì rí irú rẹ rí tàbí gbọ irú ìkọlù agbésùnmọ̀mí báyìí rí láti ọdún dé ọdún sẹ́yìn.

Mo ti kede ṣáájú sẹ́yìn, tí mo sì ṣe kìlọ̀ fáwọn agbésùnmọ̀mí yii pé kí win so èwe gbejẹ mọwọ.

Mọ̀ sísọ fún wọn pé tí wọn kò bá jawọ nìdí pípa àwọn Kristẹni, wọn yóò jìyà, wọn yóò jẹ ewéiyá. “

Ọrọ ti ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump kọ soju opo Facebook rẹ

Oríṣun àwòrán, Donald Trump /Facebook

"Lábẹ́ ìdarí mi, orilẹede mi kò ní gbà àwọn alakatakiti ẹṣin láàyè láti ṣe rere"

Trump tẹsiwaju lójú òpó ayélujára rẹ pé, ní alẹ́ ọjọ́ Kérésìmesì, àwọn agbésùnmọ̀mí yìí jẹ ìyá ńlá, wọn si fi ikú ṣe ifá jẹ.

O ni ẹka to n ja ogún níléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà ṣe àìmọye ikọlu to so ẹ̀ṣọ́ rere niwon igba ti jẹ pe orílẹ̀èdè Amẹrika nìkan ló lágbára láti ṣe èyí.

"Lábẹ́ ìdarí mi, orilẹede mi kò ní gbà àwọn alakatakiti ẹṣin láàyè láti ṣe rere, kí Olúwa bukun àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà.

Mo kí gbogbo wa kú ọdún Kérésìmesì, to fi mọ àwọn agbésùnmọ̀mí to tí lọ sọrun.

Àmọ́ ikọlu yìí yóò máa tẹsiwaju bí àwọn agbésùnmọ̀mí yìí kò bá dẹkùn pípa àwọn Kristẹni."

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ ìjọba to wa fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè tí fìdí rẹ mulẹ pe àjọṣepọ̀ ńlá ló wáyé láàárín àwọn ológun Nàìjíríà àti ti Amẹ́ríkà.

O ni ifọwọsowọpọ ikọ̀ ológun orílẹ̀èdè méjèèjì náà sì lo fa àṣeyọrí ìkọlù sáwọn agbésùnmọ̀mí tó wáyé lálẹ́ ọjọ́ Kérésì.

Atẹjade kan tí iléeṣẹ́ to wa fọrọ ílẹ̀ òkèèrè fisita laarọ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹrindinlọgbọn oṣù Kejìlá ọdún 2025, èyí agbẹnusọ ileeṣẹ náà, Kimiebi Ebienfa buwọlu, lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí.

Atẹjade náà ni àwọn aláṣẹ Naijiria sì ń sọ̀rọ̀ pọ pẹlu awọn alatilẹyin rẹ nílẹ̀ òkèèrè, tó fi mọ́ ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

"Nibamu pẹlu ìlànà ni agbaye, lára àwọn ọ̀nà tí a ń gbà ní ifowosowopo ni ṣíṣe pàṣípààrọ̀ Ìmọ̀, akoso, àti àwọn ọ̀nà miran to wa lábẹ́ òfin èyí tó dé ibọwọ fún òmìnira orílẹ̀èdè kọọkan."

Atẹjade náà wà fọwọ́ gbaya pe gbogbo aáyán rẹ láti gbógun tawọn agbésùnmọ̀mí ni yóo tele ìlànà òfin agbaye.

" A máa dáàbò bo àwọn aráàlú àti ìṣọ̀kan Naijiria, tí a sì mú ẹtọ àwọn aráàlú lokunkundun"

Iléeṣẹ́ náà wà tẹnumọ pé ìkọlù àwọn agbésùnmọ̀mí ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò ní nǹkan ṣe lórí bóyá èèyàn kan jẹ Kristẹni àbí Musulumi.