Èèyàn 5 kú, 35 farapa yánna-yànna lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ àdó olóró tó bú ní Mọ́ṣáláṣí ní Maiduguri - Ọlọ́pàá

Iná ń jó sókè fíofío pẹlu èéfín ńlá níbi tí àdó olóró tí bù nínú Mọsalasi, ọ̀pọ̀ èèyàn dúró, wọn ń wò rán.

Oríṣun àwòrán, bapphah

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọ́pàá nipinlẹ Borno ti kede pe èèyàn marun lọ kú, tí marundinlọgọjọ sì farapa lásìkò tí èèyàn kan sọ àdó ikú mora.

Wọn ni àdó oloro náà ni onítọ̀hún yín nínú Mọsalasi Al-Adum Juma'at to WA ninu ọjà Gamboru nilu Maiduguri nipinlẹ Borno.

Atẹjade tí iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá nipinlẹ Borno fi sita, èyí tí òṣìṣẹ́ alárinà rẹ, Nahum Kenneth Daso buwọ́lù lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí pẹlu àfikún pe déédéé aago mẹ́fà ni ibugbamu àdó olóró náà wáyé.

Iná ń jó sókè fíofío pẹlu èéfín ńlá níbi tí àdó olóró tí bù nínú Mọsalasi, ọ̀pọ̀ èèyàn dúró, wọn ń wò rán.

Oríṣun àwòrán, @bapphah

“A ti gbakoso agbegbe ti ibugbamu àdó olóró náà tí wáyé, tí a kò sì jẹ káwọn èèyàn rìn sì agbegbe naa"

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàlàyé pe ni kété tí àwọn ọlọ́pàá gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni wọn ti gbé àwọn ikọ̀ ọlọ́pàá adoola ẹ̀mí dìde, tí wọn sì ṣiṣẹ pọ̀ pelu ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nílẹ̀ wa, NEMA àti SEMA to wa fún ìpínlẹ̀ náà.

“A ti gbakoso agbegbe ti ibugbamu àdó olóró náà tí wáyé, tí a kò sì jẹ káwọn èèyàn rìn sì agbegbe naa.

Ìwádìí wá fihan pe èèyàn marun lo kú, tí marundinlogoji míì sì fara pa yannayanna.

A ti gbé àwọn èèyàn tó fara pa lọ sílé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn nilu Maiduguri, UMTH, àtàwọn ilé ìwòsàn miran fún itọju.”

Atẹjade iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá náà ni ó ṣeeṣe ko jẹ ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ tó ń sọ àdó ikú mọ́ra lo wa nìdí Ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

A ṣe àwárí àwọn èròjà kan bíi aṣọ penpe fẹsti to jẹ ti ẹni tó so àdó olóró náà mọ́ra"

O ni àwọn ṣe àwárí àwọn èròjà kan bíi aṣọ fẹsti to jẹ ti ẹni tó sọ àdó olóró náà mọ́ra, to a sì tún gbà ọ̀rọ̀ silẹ lẹ́nu àwọn èèyàn ti ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun soju wọn.

"A ti kọ eka iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá to ni imọ nípa àdó ikú dá síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Wọn tí ń ṣiṣẹ́ ìwádìí yíká agbegbe naa lati dena ibugbamu miran to lè wáyé."

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá wá kéde pé àlàáfíà tí ń jọba padà ní agbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé.

O wa rọ àwọn aráàlú láti bomi suuru, mú, kí wọ́n sì gbé jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn máa fi àwọn ìròyìn to bá yẹ to iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá létí

Àlàyé rèé lórí bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé

Ṣáájú là tí mú ìròyìn wá fún yín pe ọ̀pọ̀ ẹ̀mí lo tí bọ, nígbà táwọn èèyàn miran fara pa nínú Mọsalasi Gambarou Jumuat to WA nilu Maiduguri lásìkò irun maghrib.

Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé lásìkò tí àdó olóró ṣàdédé bù nínú Mọsalasi náà, tó sì pa ẹni tó agbésùnmọ̀mí to yín ado ikú náà àti ọ̀pọ̀ èèyàn.

Àwọn olùjọsìn to wa ninu mọsalasi náà, tí orí kò yọ nínú ìkọlù agbébọn ọhun ṣàlàyé pé agbésùnmọ̀mí náà yọ wọ inú Mọsalasi ọhun ni, to si yín Ado ikú náà bí irun ṣe bẹ̀rẹ̀.

Awon agbofinro kò ti kede iye èèyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn àmọ́ àwọn èèyàn kan ní èèyàn meje lo kú

Gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn ti ìṣẹ̀lẹ̀ ọhun soju 2on ṣe wí "Agbésùnmọ̀mí náà yín ado olóró ọhun nígbà tí wọn ń kí Raka àkọ́kọ́ níbi irun náà.

Ọpọ àwọn olùjọsìn kú, tí àìmọye sì fara pa."

Bi o tilẹ jẹ pe awon agborinro kò ti kede iye èèyàn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn àmọ́ àwọn èèyàn ti ìṣẹ̀lẹ̀ yìí soju wọn ní èèyàn meje lo kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ náà to gba orí ayélujára kan safihan àwọn èèyàn tó dúró lágbègbè náà to jẹ ọjà, tí eruku sì bo agbegbe naa.

Ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí kankan kò ti bọ síta láti kéde pé òun ni òun wà nìdí ìkọlù sì mọsalasi náà.

Àmọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí bíi Boko Haram áti ISIS lọ máa ń kọlu àwọn mọsalasi àti ibi tí èrò bá pọ sì láti ẹyin wá.