Ọba alayé tí wọ́n jí gbé ní Kwara gba ìtúsílẹ̀

Oba Kamilu Salami, Ojibara ti ilu Bayagan Ile, ipinlẹ Kwara

Oríṣun àwòrán, Buhari Olatunde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Kabiyesi Kamilu Salami, Ojibara ti ilu Bayagan Ile ti awọn ajinigbe ji gbe nipinlẹ Kwara, ijọba ibilẹ Ifelodun, ti gba itusilẹ lakata wọn .

Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun ana ti i ṣe ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila ọdun 2025 ni Kabiyesi gba idande.

Agbẹnusọ ilu naa, Ayinla Lawal, fidi ẹ mulẹ pe Ọba Kamilu Salami ti kuro ni akata ajinigbe.

Bakan naa si ni aburo Kabiyesi ti wọn pe orukọ rẹ ni Aliyu, naa fidi ẹ mulẹ pe ọba ti gba itusilẹ.

Ominira Kabiyesi naa n waye lẹyin ọjọ mẹẹẹdọgbọn to ti wa ni ahamọ ajinigbe.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla ọdun 2025 ni awọn ajinigbe gbe Ojibara ilẹ Bayagan lọ, lasiko ti ọba naa n ṣiṣẹ ninu oko rẹ.

Ṣé ọ̀fẹ́ ni itusilẹ Kabiyesi bá dé àbí wọ́n sanwo?

Gẹgẹ bi ẹka iroyin Vanguard ṣe ro o, nigba to n ṣalaye nipa bi Ọba Salami ṣe gba itusilẹ, agbẹnusọ ilu naa, Ayinla Lawal, sọ pe ọfẹ kọ ni itusilẹ naa ba de.

O ni awọn sanwo fun awọn ajinigbe naa, koda, ẹẹmeji ni awọn sanwo itusilẹ ọhun.

O tun ṣalaye pe ilu nikan lo da owo ti wọn fi gba Kabiyesi silẹ lọwọ ajinigbe.

Gẹgẹ bi Ayinla ṣe wi:

"Inu mi dun lati sọ fun yin pe wọn ti yọnda ọba wa, wọn yọnda rẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun.

" Awọn agba ilu ti bẹ wa pe ka ma sọ iye ti a san, fun idi eyi, mi o ni i le sọ ọ fun yin, ṣugbọn owo nla ni.

"Ijọba ibile ati ti ipinlẹ ko ran wa lọwọ titi ti rogbodiyan naa fi pari, awọn araalu nikan lo dawo, o si nira fun wa gan-an niluu, idi to fi pẹ ka too ri ọba wa gba pada niyẹn.''

Ṣugbọn ni opin ohun gbogbo, agbẹnusọ ilu sọ pe awọn dupẹ lọwọ Ọlọrun to jẹ ki ọba awọn pada sile laaye, awọn si mọ riri awọn ilu fun aduroti wọn.

Ọna awọn ajinigbe naa jin pupọ, ẹ̀rù ijinigbe ba emi gan-an ti mo lọ gbe Kabiyesi wale- Aburo Ojibara.

Ninu ọrọ tirẹ, aburo Ọba Ojibara, ẹni ti wọn pe orukọ rẹ ni Aliyu, to lọ gbe ọba naa wale lati akata awọn ajinigbe, ṣọ pe ibi ti awon agbebon naa wa jinna gidi.

Aliyu to gbe kabiyesi lọ sile iwosan adani kan n'Ilorin laaarọ Ọjọru, ṣalaye pe :

"Ibi ti awọn ajinigbe naa wa jinna gidi, ẹru n ba emi gan-an ti mo lọ gbe wọn, ki wọn ma lọ ji mi gbe.

"Eeyan ko tiẹ le sọ pe ipinlẹ Kwara ni ibi ti wọn wa yẹn naa, nitori wọn n rin kiri ni, wọn ki duro loju kan.

"Foonu Kabiyesi ni wọn fi maa n ba mi sọrọ, mi o si le da ẹnikẹni mọ ninu wọn."

Aliyu ṣalaye pe oun ko tilẹ fẹ lọ mọ lasiko kan, oun sọ fun ilu pe oun ko lọ mọ, nitori ẹru n ba oun.

O ni ṣugbọn awon araalu sọ pe oun naa ni ẹnikan ṣoṣo to le lọ, nigba to jẹ oun nikan naa ni aburo Ojibara ti wọn bi tẹle e.

Kabiyesi naa ko ti i ni anfaani lati ba akọroyin kankan sọrọ, nitori wọn ni o n sinmi lọwọ.

Ki lo ṣẹlẹ ṣiwaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn ajinigbe kan tun kọlu agbegbe Bayangan nijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara, ti wọn si ji Ori Ade ilu naa gbe lọ.

Nnkan bi ago mẹsan an abọ owurọ ọjọ Satide ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti Oba, Ojibara ti ilu Bayangan, Alhaji Kamilu Salami wa ninu oko rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Ọgbẹni Buhari Ọlatunde to jẹ ọmọ agbegbe naa sọ pe, awọn Ọba alaye to ku ni ìjọba ibilẹ Ifẹlodun ti n se ipade lati jiroro lori igbesẹ ti wọn yoo gbe lori iṣẹlẹ naa.

Ọgbẹni Ọlatunde tẹsiwaju pe awọn ajinigbe naa ti kan si mọlẹbi kabiyesi, ti wọn si n beere fun aadọjọ miliọnu naira, owo itusilẹ ki wọn to yọnda Ọba alaye naa.

Lasiko to n akọroyin BBC Yoruba sọrọ, kansilọ to n soju ilu Bayangan nijọba ibilẹ Ifẹlodun, Hon. Quadri Ọlaitan sọ pe, kabiyesi wa ninu oko pẹlu awọn ọmọ isẹ rẹ lasiko ti awọn ajinigbe yabo wọn .

Hon. Quadri ni, awọn ajinigbe naa ti pe, ti wọn si bere fun aadọjọ miliọnu naira.

"Pẹlu alaye pe, wọn tun ti pe ni irọlẹ ana ti wọn din owo itusilẹ naa ku si ọgọrun kan million naira."

Hon. Quadri ni gbogbo ilu naa n sa sokesodo ni bayii lati wa ọna ti wọn fẹ gbe ọrọ owo naa gba.

O fikun pe, awọn ọdẹ ilu naa ti wọ inu igbo lọ lati ọjọ Ṣatide ti iṣẹlẹ naa ti waye, sugbon wọn o ko ti ri kabiyesi, Ọba Ojibara ilu Bayangan, Alhaji Kamilu Salami.