Mo kábàámọ̀ pé mo ṣe àtìlẹyìn fún Tinubu ní 2023, èmi gan ní ohun tó yẹ láti di ààrẹ Nàìjíríà - Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Makinde/Facebook
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pé òun kábàámọ̀ pé òun ṣe àtìlẹyìn fún Ààrẹ Bola Tinubu níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2023.
Makinde àtìlẹyìn tí òun ṣe fún Ààrẹ náà kò so èso rere gẹ́gẹ́ bí òun ṣe fọkàn sí.
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kejìlá ni Makinde sọ̀rọ̀ níbi àpérò tó ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn nílé ìjọba tó wà ní Agodi, Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo.
Ẹ ó rántí pé Makinde wà lára àwọn gómìnà G5 tẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP tí wọ́n tako olùdíje sípò ààrẹ ẹgbẹ́ wọn nígbà náà, Alhaji Atiku Abubakar.
Àwọn gómìnà ọ̀hún nígbà náà sọ pé ẹkùn gúúsù Nàìjíríà ló kàn láti pèsè ààrẹ lẹ́yìn tí ààrẹ Muhammadu Buhari láti ẹkùn àríwá ti lo ọdún mẹ́jọ.
Mi ò lè ṣe àtìlẹyìn fún Tinubu mọ́
Makinde ṣàlàyé pé ìdí tí òun fi ṣàtìlẹyìn fún Tinubu tó jẹ́ olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC nígbà náà ni pé òun gbàgbọ́ pé Tinubu máa mú àyípadà ọ̀tun bá Nàìjíríà.
"Mo ti sọ tẹ́lẹ̀ pé èèyàn ni mí. Mo ṣe àtìlẹyìn fún ààrẹ tó wà lórí ipò bi ótilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹgbẹ́ òṣèlú míì ni mo wà nítorí mo rò pé ó máa ṣe ohun tó tọ́ fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà."
Ó fi kun pé òun rò pé ààrẹ máa mú àtúntò bá orílẹ̀ èdè nípa lílo àwọn èèyàn tó pójú owó káàkiri orílẹ̀ èdè láti kojú àwọn ìṣòro tó ń bá Nàìjíríà fínra ṣùgbọ́n tó ní ohun tó yàtọ̀ ni àwọn ń rí báyìí.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdúró ire ìṣèjọba àwaarawa, Makinde jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun kò ní ṣe àtìléyìn fún Tinubu níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.
"Wike sọ fún Tinubu pé òun máa dá PDP dúró fún-un ṣáájú ètò ìdìbò 2027 ló ṣokùnfà aáwọ̀ àárin wa"
Makinde tún sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ṣokùnfà àìgbọ́ra ẹni yé tó ń wáyé láàárín òun àti Mínísítà fọ́rọ̀ Abuja, Nyesom Wike. Ó ní ohun tó ṣokùnfà aáwọ̀ náà kò ṣẹ̀yìn bí mínísítà náà ṣe sọ fún ààrẹ Tinubu níbi ìpàdé kan pé òun máa mú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP dúró fún-un lọ́dún 2027.
Gómìnà náà ní ohun tí Wike sọ náà kìí ohun tí àwọn jọ fẹnukò lé lórí tó sì bí òun nínú.
"A wà nínú ìpàdé pẹ̀lú ààrẹ, èmi pẹ̀lú Wike àtàwọn míì, Wike sọ fún Ààrẹ pé òun máa mú PDP dúró ṣáájú ètò ìdìbò 2027. Mo sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé a fẹnukò lórí èyí?
Ó wòye pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Wike ní ẹ̀tọ́ láti ṣàtìlẹyìn fún Tinubu, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ míì náà ní ẹ̀tọ́ láti dá ààbò bo ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, kí wọ́n sì tako ohun tó bá le dènà ìṣèjọba àwaarawa.
Ó ní ohun tí Wike ṣe yìí ló mú àyípadà bá ìbáṣepọ̀ òun àti Wike, tó sì fẹ̀sùn kàn-án pé ó ń lo ipò rẹ̀ láti tàbùkù ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pàápàá ní àwọn ìpínlẹ̀ tí PDP ti ń ṣàkóso ìjọba ibẹ̀.
Ó tẹmpẹlẹmọ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà nílò ètò ìṣèjọba àwaarawa tó dúró ire pẹ̀lú níní ẹgbẹ́ alátakò tó gbóná, tó sì bu ẹnu àtẹ́ lu báwọn gómìnà àtàwọn èèkàn olóṣèlú ṣe ń fi ẹgbẹ́ òṣèlú wọn sílẹ̀ bó sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Tinubu ní òun fẹ́ yàn mí ni aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Oyo àmọ́ mo kọ̀
Gómìnà Seyi Makinde ní ààrẹ Tinubu tí gbèrò láti fi òun ṣe adarí ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo ṣùgbọ́n òun kọ̀ jalẹ̀ tí òun sì sọ fun pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni òun bá ṣe.
"Mo sọ fún ààrẹ pé tó bá jẹ́ pé kí Adebayo Adelabu le mú àtúntò bá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo ni wọ́n ṣe yàn-án sípò mínísítà, Adelabu kò ní ìkápá bẹ́ẹ̀.
"Ààrẹ sọ pé rárá ìwọ gan ni mo fẹ́ bá mi tún APC tò ní ìpínlẹ̀ Oyo, mo sì só pé rárá, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni mò ń bá ṣe."
Mo ní ohun gbogbo tó yẹ láti di ààrẹ Nàìjíríà
Seyi Makinde tún fi kún ọ̀rọ̀ pé òun ní àmúyẹ láti darí Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ààrẹ.
Ó ní òun ní gbogbo ìrírí àtàwọn àmúyẹ láti di ààrẹ bí ó ṣe jẹ́ pé òun ti ṣe gómìnà fún sáà méjì tí sáà òun bá ti parí ní ọdún 2027.
"Tó bá fi máa di ìparí ọdún 2027, mo máa ti ṣe gómìnà ìpinlẹ̀ Oyo fún sáà méjì, ààrẹ tó wà lórí ipò báyìí náà ṣe gómìnà ìpínlẹ̀ Eko fún sáà méjì ni."















