Sunday Igboho fọnmú bí afurasí Fúlàní ṣe ṣá àgbẹ̀ mẹ́ta pa nílùú rẹ̀, fi ewé ìkìlọ̀ mọ́ ìjọba létí

Sunday Adeyemo (Igboho ooṣa)

Oríṣun àwòrán, @Sunday Adeyemo (Igboho oosa)

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajijagbara to n pe fun idasilẹ orilẹede Olominira Yoruba, Sunday Adeyemo tawon eeyan mọ si Igboho ooṣa, ti kede pe awon afurasi Fulani darandaran pa eeyan mẹta niluu oun, Igboho lọjọ Aiku ọsẹ yii.

Ọjọ Aje ni Igboho ke gbajare si ijọba apapọ lori iṣẹlẹ naa, pẹlu alaye pe suuru awọn eeyan oun ti fẹ dopin.

Ninu atẹjade to fi sita ni Igboho ti sọ pe agbẹ ni awọn ọkunrin mẹta ti wọn pa naa.

Bàwo ni ìṣẹlẹ yii ṣe wáyé gan-an?

Igboho ni Aderoju Mukaila, Olawuwo Saka ati Ojeniyi Ojebayo, pade iku ojiji lọwọ awọn darandara to ṣa wọn pa nitori wọn kọ lati jẹ kawọn Fulani naa fi ẹran jẹ oko wọn.

Gẹgẹ bi alaye Sunday Igboho, ko si ẹṣẹ kan ti awọn ọkunrin mẹta ti wọn pa yii ṣẹ, ju pe wọn kọ lati jẹ ki awọn Fulani naa fi maaluu jẹ oko wọn lọ.

Nigba ti wọn ko gba awon darandaran naa laye lati ba iṣẹ òógùn oju wọn jẹ ni wọn ṣa wọn pa.

Bo si tilẹ jẹ pe awọn eeyan sare gbe wọn lọ sileewosan, wọn pada dagbere faye latari ohun to ṣe wọn latọwọ awọn Fulani.

Ninu alaye Sunday Igboho lori ikọlu naa, apa kan atẹjade rẹ ka pe:

"Lọjọ Aiku, wọn pa eeyan mẹta ti ko ṣe wọn lẹṣẹ kan niluu mi.

"Ohun ti mo n tori ẹ kilọ fun ijọba lati ọpọ ọdun sẹyin gan-an ree, ko ti i si ayipada kankan.

'Kawọn eeyan maa koju ikọlu, kawọn to n kọlu wọn si maa rin kiri lominira ara wọn.

"Ijọba atawọn tọrọ yii kan gbọdọ fi kun iṣẹ wọn lati ri i pe wọn da aabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan l'Oke Ogun, aabo ibẹ ti mẹhẹ."

"Ijọba apapọ gbọdọ gbe igbesẹ akin, ko too di pe awọn olugbe agbegbe naa yoo fi ofin sọwọ ara wọn, ti wọn yoo si maa da aabo bo ara wọn"

Sunday Igboho tẹsiwaju pe ọpọ igba loun ti n pariwo lori iṣẹ ibi awọn Fulani darandaran yii, awọn agbebọn ati awọn janduku to n wọ igbo ẹkun Guusu -Iwọ-Oorun ilẹ yii wa, ti wọn si ti wa lapa kan Kwara ati Kogi.

"O ti di dandan bayii fun ijọba apapọ, labẹ idari Aarẹ Bola Tinubu, lati ran ikọ alaabo jade ti yoo koju awọn ọdaran yii.

"Suuru awọn ti wọn n pa eeyan wọn nipakupa ti de opin bayii, wọn si ti wa nipo ipayinkeke.

"Ijọba apapọ gbọdọ gbe igbesẹ akin, ko too di pe awọn olugbe agbegbe naa yoo fi ofin sọwọ ara wọn, ti wọn yoo si maa da aabo bo ara wọn."

Bẹẹ ni Igboho wi.

Ki lo tí wáyé sẹ́yìn laarin Sunday Igboho àtàwọn Fulani darandaran?

Tẹ o ba gbagbe, Sunday Igboho ati awọn Fulani ti figba kan gbena woju ara wọn lagbegbe Oke Ogun

Ajijagbara naa le wọn kabakaba latari ifẹranjẹko ati ẹsun biba obinrin olobinrin lo pọ, titi kan pipa awọn agbẹ soko lọsan-an gangan.

Eyi naa si pẹlu ara idi ti Igboho fi n pe fun Yoruba Nation, nibi ti Fulani ko ni i si.

Ẹnu ọrọ naa lo wa to fi di ọran si i lọrun, to kuro lorilẹede yii, ti ijọba si fi orukọ rẹ si iwe awọn ti wọn n wa fun ẹsun iwa ọdaran.