Àwọn ajínigbé bínú tán, kọ̀ láti gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ ẹbí ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Arise
Awọn eeyan mẹwaa ti awọn ajinigbe ji gbe ni ilu Isapa, ipinlẹ Kwara ko ti i gba ominira titi di akoko yii, ohun to si tilẹ tun mu ọrọ naa le ni pe awọn to ji wọn gbe kọ lati gba owo itusilẹ ti ẹbi fi ranṣẹ si wọn.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrinlelogun osu Kọkanla ọdun 2025 ni awọn agbebọn ya wọ ilu Isapa, nijọba ibilẹ Ekiti, ti wọn si gbe awọn araalu mẹwaa lọ lẹyin ti wọn ti rọjo ibọn kalẹ
Lati igba naa ni idunaa-dura ti n lọ lori bi wọn yoo se doola awọn ti wọn n wa lakata awọn ajinigbe naa.
Nnkan bii ọsẹ meji sẹyin si ni awọn ajinigbe naa pe awọn araalu lori aago, ti wọn si beere fun owo ọọdunrun miliọnu (N300 million) owo itusilẹ, ṣugbọn ipa awọn araalu Isapa ko ka owo naa lẹyin ọpọlọpọ igbiyanju ti wọn ṣe lati ko o jọ nigba naa.
Nigba ti wọn yoo si fi kowo jọ, niṣe ni awọn ajinigbe kọ lati gba a.
Kí ló mú ajinigbe kọ owó ìtúsílẹ̀?
BBC News Yoruba kan si Olori-Ọdẹ ilu Isapa, Arakunrin Adeyeye, lorii foonu lati mọ ibi ti ọrọ de duro bayii.
Adeyeye ṣalaye pe ni nnkan bi ọjọ meloo sẹyin ni awọn ajinigbe naa pe, pe awọn din owo itusilẹ naa ku si miliọnu mẹrin (N4million).
"Awọn ajinigbe naa pe ni bi ọjọ marun-un sẹyin, wọn si ni ki a san N4million. Sugbọn gbedeke ti wọn fun wa ni pe ki a san owo naa ni o pẹ ju, ọjọ Ẹti to kọja yii.
"Igba ti awọn ẹbi ati ilu yoo fi ri owo naa pe, o ti bọ si ọjọ Abamẹta.
"Eyi ni ko jẹ ki wọn gba a lọwọ wa, wọn ni awọn ko le gba miliọnu mẹrin mọ nitori asiko ti awọn fun wa ti kọja.
"Ni bayii, wọn n beere N35million naira, miliọnu marundinlogoji, wọn ni awọn ko le gba N4million mọ nitori asiko oore ọfẹ tawọn fun wa ti kọja."
Olori ọdẹ tẹsiwaju pe eeyan mẹjọ ninu awọn mẹwaa ti wọn ji gbe naa jẹ ọmọ ile kan naa.
O ni ọkunrin Hausa kan to jẹ agbẹ ni wọn gbe iyawo rẹ meji ati awọn ọmọ rẹ mẹfa lọ.
"Wọn ti kọkọ gbe arakunrin naa ti wọn si fi i silẹ lẹyin ti wọn gba N2million. Inu oko rẹ to maa n ṣọ tọsan-toru kawọn maaluu ma baa wọbẹ lo n gbe tẹlẹ, sugbọn o pada ko wa inu igboro Isapa.
"Arakunrin agbẹ yii gan-an ni awọn ajinigbe naa wa wa sinu ilu."Ṣugbọn igba ti wọn de, wọn o ba a nile, wọn si ji iyawo rẹ meji ati awọn ọmọ rẹ mẹfẹẹfa gbe lọ."
Bẹẹ ni Olori ọdẹ Isapa wi.
O ni oun fura pe owo nnkan oko agbẹ naa to ṣẹṣẹ ta ni awọn ajinigbe tori rẹ wa.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alukoro ọlọpaa Kwara, SP Adetoun Ejire-Adeyemi, to ti fi atẹjade lede ṣaaju lori rẹ, sọ pe wọn ko fi abala idunaa-dura ati gbedeke yii to ọlọpaa leti.














