Kà nípa bí àwọn ìgbésẹ̀ ìṣèjọba Tinubu ṣe ń pa àwọn iléeṣẹ́ àdáni lára ní Naijiria

Aworan awọn ọkunrin kan ninu ileeṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty image

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ẹgbẹ awọn onileeṣẹ adani ti wọn n pese nnkan eelo ni Naijiria, Manufacturers Association of Nigeria, (MAN), ti ṣalaye inira to n koju wọn latari awọn ilana iṣejọba ti Aarẹ Bola Tinubu gunle, eyi ti aarẹ sọ pe ki nnkan le baa daa ni.

Bẹrẹ lati ori owo naira to ti ja walẹ, titi de ori ina mọnamọna ti owo rẹ ti kọja agbara ni awọn MAN mẹnuba.

Ida ọgbọn (30%), pere ni iṣẹ ti awọn ileeṣe to n pese nnkan eelo wọnyi n ṣe lojumọ bayii gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Ẹgbẹ yii sọ pe pẹlu bi awọn ṣe n sọ idaamu awọn fun ijọba to, wọn ni ijọba ko dahun.

Kí ló fa ìnira báyìí fún àwọn oníleeṣẹ́?

Ali Sufyanu Madugu, ọkan lara awọn alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ MAN, ṣalaye fun BBC pe,

"Nnkan akọkọ to da wahala silẹ fun awọn ileeṣẹ to fi di pe iṣẹ ida ọgbọn pere ni wọn n ṣe bayii, ni ti naira ti ko niye lori mọ.

“Ikeji ni ti owo ilẹ okeere bii dọla ti ko si. Dọla ni a fi n ra awọn irinṣẹ ati nnkan eelo ti a nilo lati ṣiṣẹ."

"Lọdun to kọja, dọla ko kọja irinwo naira (400) ti ofin ni ki wọn maa ta a.

Ṣugbọn ni bayii, dọla ti lọ soke, o ti di ẹgbẹrun kan ati ẹgbẹta naira (1,600).

Iyẹn fi n ye wa pe onileeṣẹ to ba fẹẹ ṣiṣẹ to pe lasiko yii gbọdọ ṣetan lati ṣafikun owo ti yoo na ni ilopo mẹrin."

‘’Ina mọnamọna ni iṣoro miran ti a ni, awọn ileeṣẹ kan ko le ṣiṣẹ mọ nitori afikun to ba owo ina.’’

Nitori ọrọ ina yii ni awọn ileeṣẹ ilẹ okeere mi-in ṣe ta ileeṣẹ wọn to wa ni Naijiria, ti wọn si gba ibo mi-in lọ

" A n ra dọla ti banki n ta lati banki, ti a ba waa fẹẹ lọọ fi dọla naa ra irinṣẹ ti a nilo, ọsẹ mẹfa si mẹjọ, ko ni i tẹ wa lọwọ."

"Nipa ti ina mọnamọna, ijọba ko ri nnkan kan ṣe si i. Ti wọn ba ti fowo kun owo ina, o maa pa wa lara, nitori ina la n lo.

Awa naa maa ni lati fowo kun ohun ti a n ṣe sita, awọn araalu ti ko ni pupọ lọwọ naa lo si n ba wa ra awọn ọja yii, awọn naa yoo fori ko o. "

Bi wahala yii yoo ba dopin, Madugu sọ pe ijọba gbọdọ dahun si ohun ti awọn onileeṣẹ n wi, ki araalu naa le fi ẹdọ lori oronro.

Àyọkúrò owó ìrànwọ́ epo ló fa ìnira lóòótọ́, ṣùgbọ́n...

Igbagbọ ọpọ eeyan, titi kan awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ọrọ aje ni pe owo iranwọ ori epo ti ijọba Aarẹ Tinubu yọ loṣu kẹfa ọdun to 2023 lo fa inira fun araalu.

Ayọkuro sọbsidi naa lo mu owo ori ọja wọn gogo, to si n ba ọrọ aje finra titi di asiko yii.

Ṣugbọn bi eyi ṣe jẹ otitọ to, awọn onimọ nipa ọrọ aje sọ pe ọna abayọ kan to wa fun iṣoro yii ni lati ro awọn ileeṣẹ lagbara.

Eyi yoo pese iṣẹ fun ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ti iṣẹ ati oṣi n ba finra.

Yoo si tun mu ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eeyan kuro ninu inira to n ba wọn finra bi wọn ṣe sọ.