Kìnìún fa ọkùnrin kan ya lọ́gbà ẹranko OOPL Abeokuta, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwadìí

Lion Zoo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Kiniun ti ṣekupa ọkunrin ẹni ọdun marundinlọgbọn kan, Babaji Daule nilu ọgba ẹranko to wa ni Olusegun Obasanjo Presidential Library, OOPL, niluu Abeokuta.

A gbọ pe alẹ ana ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ ọhun waye.

Ninu atẹjade kan ti awọn alaṣẹ ọgba ẹranko naa fi lede ni wọn ti fidi iroyin naa mulẹ.

Atẹjade naa sọ pe, “lalẹ yii, kiniun ṣekupa ọkan lara awọn to n ṣo ẹranko ni ọgba ẹranko OOPL.

“Asọgba ẹranko naa ko awọn alejo lọ sibẹ lẹyin ti iṣẹ ti pari tan lati fi bi wọn ṣe n fun kiniun lounjẹ han wọn.”

Atẹjade naa tẹsiwaju pe oloogbe ọhun ko ti ilẹkun ibi ti ẹranko naa wa latari pe kii ṣe igba akọkọ rẹ ti yoo fun lounjẹ niyẹn, eyii to mu ki kiniun ọhun jade si, to si ṣekupa a.

Wọn ni, ni kete ti awọn akẹgbẹ rẹ ri ohun to ṣẹlẹ ni wọn yinbọn si kiniun ọhun lẹsẹkẹsẹ ko ma baa fa oku naa ya pẹrẹpẹrẹ.

Atẹjade naa ṣalaye pe “a fẹ ki awọn eeyan mọ pe ohun ti oloogbe naa ṣe lodi si bi a ṣe n fun kiniun lounjẹ.”

Wayi o, wọn ni awọn ti fi ọrọ naa to ọlọpaa leti, iwadii si ti bẹrẹ.

Lẹyin naa ni wọn ba awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun lori iṣẹlẹ ọhun.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ kulẹkulẹ bi ọrọ naa ṣe jẹ.

Alukoro ileesẹ naa, SP Omolola Odutola lo sọ bẹẹ ninu atẹjde kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aiku.

Iroyin ni wọn ti gbe okun oloogbe naa to jẹ ọmọ ipinlẹ Bauchi, lọ sile igbokupamọsi to wa nile iwosan gbogbo Ijaye.