Ìjì líle Hurricane Helene gbẹ̀mí èèyàn 43 nílẹ̀ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ko din ni eeyan mẹtalelogoji to ti jade layẹ bayii nilẹ Amẹrika ti ẹgbẹlẹgbẹ awọn mii si di alairilegbe lẹyin ti iji lile Hurricane Helene kọlu guusu ila oorun ilẹ naa.
Awọn alaṣẹ ti bẹrẹ si n doola awọn to ha sagbegbe ti iṣẹlẹ naa kọlu pẹlu ọkọ oju omi, ọkọ ofurufu atawọn ọkọ mii bo tilẹ jẹ pe o ṣoro lati doola ọpọ eeyan.
Nnkan bii aadọta eeyan lo ha si ori orule nile iwosan kan bayii ni Tennessee.
Iroyin ni iji lile ọhun ni eyii to buru julọ iru rẹ ti yoo kọlu agbegbe Big Bend ni Florida lati ọpọ ọdun sẹyin.
Awọn onimọ nipa eto iṣuna sọ pe atunṣẹ ohun ti iji na bajẹ yoo to ọpọ biliọnu dọla.
Ọpọ oju popo ati ile gbigbe ni omi bo mọlẹ lọjọ Ẹti, koda mọlẹbi kan sọ pe ṣe ni awọn luwẹ jade ninu ile awọn.
Alẹ Ọjọbọ ni iji lilẹ Helene ọhun bẹrẹ to si ja fun nnkan bii wakati mẹfa gbako.
Iji lile yii ni ikẹrinla iru rẹ ti yoo lagbara julọ nilẹ Amẹrika lati igba ti iji ti n ja nibẹ.
Awọn onimọ sọ pe ọdun 1996 ati 2017 ni wọn ti ri irufẹ iji lile bẹẹ kẹyin.
Lara awọn ilu ti iji naa kan ni Florida, Georgia, Tennessee atawọn Carolina mejeji.
O kere tan, eeyan mẹjọ lo ku ni Florida lọjọ ẹti, lara wọn ni awọn to dagbere faye ni Pinellas County.
Gomina Florida, Ron DeSantis sọ fun awọn akọroyin pe ẹnikan ku lẹyin ti patako ajuwo dawo le ọkọ rẹ lori, nigba ti ẹlomiran ku lẹyin ti igi wo lu ile rẹ.















