Àwọn adigunjalè tó fọ́ bánkì l’Offa tí iléẹjọ́ dájọ́ ikú fún yóò pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn - Agbẹjọ́rò

Aworan awọn adigunjale

Oríṣun àwòrán, Kwara State Government/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Lẹyin ti ileẹjọ giga niluu Ilorin nipinlẹ Kwara dajọ iku fawọn adigunjale l'Ọjọru lori iṣẹlẹ idigunjale ni banki niluu Offa ninu eyi ti eeyan to le lọgbọn ti ku, agbẹjọro awọn ọdaran naa ti sọ pe awọn adigunlale yoo pe pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ.

Lẹyin idajọ naa ti o to wakati mẹta ti adajọ Haleema Salman fi ka a ni agbẹjọro awọn adigunle maraarun ọhun, Abdullahi Jimba, fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akoroyin.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ l"Ọjọbọ, adajọ Salman wi pe ko si ẹri to le fidi rẹ mulẹ wi pe awọn adigunjale naa ni iwe ẹri lati gbe ibọn labẹ ofin.

Gbogbo awọn ọdaran naa nile ẹjọ ni wọn jẹbi ẹsun gbigbe ibọn lai ni iwe ẹri lati ṣe bẹẹ.

Bakan naa ni ile ẹjọ tun sọ pe wọn jẹbi ẹsun igbimọpọ lati digunjale ni banki.

Bi idajọ iku fawọn adigunjale marun un naa ṣe lọ ree

Adajọ Salman fidi rẹ mulẹ wi pe ikọ agbẹjọro olupẹjọ ti fidi ẹsun idigunjale ati ipaniyan mulẹ kọja ohun to le ru ẹnikẹni loju.

Ile ẹjọ sọ pe olupẹjọ ti mu awọn ẹleri mọkanla pẹlu nkan ẹri to to mọkandinlọgọrun wa ileẹjọ lati fidi ẹsun naa mulẹ.

Adajọ Salman, ni lọjọ buruku eṣu gbomi mu yii, gbogbo ilu Offa lo wa ninu ọfọ lori bi awọn adigunjale naa se yabo awọn banki marun-un ni ilu naa, ti wọn si gbe owo to to ẹgbẹẹgbẹ milionu lọ lẹyin ti wọn ṣeku pa awọn ọlọpaa ati awọn araalu mii.

O ni bi iṣẹlẹ naa se ṣẹlẹ pe fun akiyesi gbogbo agbaye.

Fun ẹsun nini ohun ija ni ikawọ, adajọ pasẹ ẹwọn ọdun mẹta fun wọn nipa ilana ofin Naijiria.

Aworan awọn adigunjale

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Fun idigunjale ati ipaniyan, o pa a lasẹ pe ki wọn yẹgi fun wọn titi ẹmi yoo fi bọ lọrun wọn.

Adajọ Salman wa parọwa fawọn ọdọ lati maa rọra ṣe nitori ibasepọ awọn ọdaran naa pẹlu ijọba ode igbana naa lo jẹ ki wọn ṣe asise, ti wọn si ti gbagbe pe, ohun kan ko lọ titi lai.

Ijọba Kwara sọrọ lori idajọ iku fawọn adigunjale to fọ banki l'Offa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣapejuwe idajọ idajọ iku ti adajọ Salman gbe kalẹ fawọn ọdaran marun un naa gẹgẹ bi ohun to dara to bori ohun buburu.

Kọmiṣọna fun eto iroyin, Họnọrebu Bola Olukoju lo fọrọ yii lede loju opo X ijọba ipinlẹ Kwara.

Ijọba ipinlẹ Kwara dupẹ lọwọ ẹka ijọba to jẹ igbimọ olupẹjọ fun iṣẹ takun takun ti wọn ṣe lori igbẹjọ naa lati ibẹrẹ titi ti o fi pari.

Bakan naa, ni ijọba tun kẹdun pẹlu ilu Offa ti iṣẹlẹ naa ti waye atawọn ẹbi ti eeyan wọn ba iṣẹlẹ laabi naa lọ lọdun 2018.

Inu ijọba dun wi pe idajọ ti adajọ Salman gbe kalẹ lori iṣẹlẹ idigunjale naa to waye lọjọ kẹrinlọgbọn oṣu Kẹsan an niluu Off ti jẹ ki ọkan awọn alaṣẹ ijọba ipinlẹ Kwara balẹ lori ọrọ naa.

O kere tan eeyan mẹtalelọgbọn ninu eyi ti alaboyun ati ọlọpaa mẹsan an wa ninu wọn lo ku ninu iṣẹlẹ naa.

Ijọba Kwara ni iṣẹlẹ buruku ti ipinlẹ naa ko le gbagbe laelae ni iṣẹlẹ ọhun.

Inu ijọba Kwara tun dun wi pe idajọ ododo ti waye eyi ti yoo si jẹ idunnu fawọn ẹbi awọn eeyan to fara kaasa iṣẹlẹ ọhun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ijọba tun lu ile ẹjọ giga to ṣagbatẹru igbẹjọ naa lọgọ ẹnu fun idunsinsin ati iṣẹ takun takun ti o ṣe lati ibẹrẹ titi de opin igbẹjọ naa.

Kọmiṣọna fun eto iroyin tun gbe oṣuba rabandẹ fun agbjọro ijọbo, Ọgbẹni Rotimi Jacob, SAN, fun iṣẹ ọpọlọpọ ati ifọkansi rẹ lori igbẹjọ naa.

O ni idajọ ileẹjọ fihan pe ko si aye fun ẹnikẹni lati huwa tani yoo mu mi nipinlẹ Kwara.

Kọmiṣọna sọ ninu atẹjade naa wi pe ko ẹmi eeyan kan to ṣe pataki ju ti ẹlomiran lọ.