Wo àwọn ànfàní àti ewu tó wà nínú mímu Zobo

Oríṣun àwòrán, Getty images
Ohun mimu Zobo ki i ṣe ajeji nilẹ yii, o fẹrẹ ma si apa ibi ti wọn ki i ti i mu lati fi rẹ oungbẹ ati fun iwosan ara.
Gẹgẹ bi awọn oloyinbo ti wi, wọn ni ewe ododo kan ti wọn n pe ni Hibiscus, eyi to ti gbẹ, lo n di Zobo.
Anfaani oriṣiiriṣii lo wa ninu Zobo, koda ajọ FDA to n ri si ounjẹ ati oogun lilo l’Amẹrika sọ pe ko si ewu ti eeyan ba n mu Zobo.
Ṣugbọn wọn ni o ṣee ṣe ko ma ba awọn eeyan kan lara mu.
Àwọn èròjà aṣaralóore wo ló wà nínú Zobo?
Diẹ lara awọn eroja aṣaraloore to wa ninu ohun mimu Zobo ni Protein, Vitamin C, Calcium, Iron, Phosphorous, Niacin, Riboflavin, Fiber, Fat, Thiamine ati Carotene.
Ọpọ eeyan lo nifẹẹ si Zobo mimu nitori awọn anfaani gbogbo to wa lara rẹ yii.
Ànfààní Zobo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
*Amúnijẹun:
Nitori awọn eroja pataki bii Calcium, Iron ati Carotene to wa ninu Zobo, ohun mimu yii maa n jẹ ki ẹnu eeyan ṣi lati jẹun daadaa.
Bakan naa si ni eroja to n gbogun ti kokoro to wa ninu Zobo maa n fun ara lokun.
*Zobo mímu dáa fún ojú:
Bi o ba n fẹ ki oju rẹ mọlẹ kedere, Zobo mimu daa pupọ fun eyi.
Eroja Carotene to wa ninu rẹ yoo parada si Vitamin A, eyi to n ṣiṣẹ fun iriran kedere.
Yatọ si eyi, mimu Zobo le dena airiran daadaa lọwọ alẹ.
*Zobo máa ń mú ìfúnpá tó ga wá sílẹ̀
Iwadii fi han pe mimu Zobo le ran awọn ti ifunpa wọn ba maa n ga lọwọ nipa mimu ifunpa naa wa silẹ.
Ṣugbọn ṣaa, awọn onimọ ijinlẹ sọ pe Zobo ko le rọpo oogun ifunpa lilo.
Wọn ni ẹni ti ifunpa rẹ ba n ga ju yoo nilo lati maa lo oogun rẹ ni.
*Igbọnsẹ ṣíṣe yóò rọrùn fún ẹni tó bá ń mu Zobo:
Eroja kan ti a mọ si fibre wa ninu Zobo, eyi to maa n jẹ ki igbọnsẹ rọrun lati ṣe, to si tun maa n mu ki ounjẹ tete da ninu pẹlu.
* Zobo ń ró àwọn ṣọ́jà ara lágbára:
Fun ẹni to ba n mu Zobo daadaa, eroja Vitamin C to wa ninu rẹ yoo maa ro awọn ṣọja ara (immune sysyem) ẹni bẹẹ lagbara.
*Ó ń dín ìnira nńkan oṣù kù:
Nitori agbara to wa lara Zobo lati ṣatunṣe si awọn ẹya ara obinrin, nnkan mimu yii maa n din inira ti awọn obinrin maa n koju lasiko nnkan oṣu ku.
Bakan naa lo tun n ṣiṣẹ fun bi ẹjẹ ṣe n gba oju ara obinrin kọja, eyi to n ṣiṣẹ fun inira nnkan oṣu lai lo oogun si i.
*Zobo máa ń dín ara sísan kù:
Fun awọn eeyan ti wọn fẹẹ din ara sisan ku, Zobo mimu wulo fun wọn lati ṣe eyi.
Idi ni pe o maa n din bi eroja ṣuga ṣe maa n pọ lara ku.
Ewu tó rọ̀ mọ́ Zobo mímu
*Zobo kò dáa fún aláboyún: Iwadii fi han pe Zobo mimu ko dara fun alaboyun, paapaa aboyun ti oyun rẹ ṣi wa laaarin oṣu mẹta akọkọ.
Idi ni pe mimu Zobo le mu ki eroja obinrin, estrogen, pọ si i ninu oyun, eyi si le fa ki oyun naa walẹ.
*Zobo kò sí fún obìnrin tó ń fún ọmọ lọ́mú: Bi iyalọmọ ba n mu Zobo, o le din bi ounjẹ yoo ṣe wọ ara rẹ ku, eyi to le fa ki ọmu rẹ ma sẹ daadaa fun ọmọ lati mu.
*Zobo kò dáa fún àwọn tí ìfúnpá wọn bá máa ń wálẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà: A wọn eeyan kan wa ti ifunpa wọn ki i ga rara, to jẹ o maa n sabaa lọ silẹ ni.
Iru awọn eeyan bayii ni lati ṣọra fun Zobo mimu.
Bi wọn ba n mu Zobo pẹlu oogun ti wọn lo, ifunpa ti ko to nnkan tẹlẹ le tun lọọ ja wa sisalẹ ju bo ṣe yẹ lọ, eyi si lewu.
Bakan naa, iwadii kan fidi ẹ mulẹ, pe apọju Zobo le ṣe akoba fun ẹdọ eeyan.
Ju gbogbo ẹ lọ, o yẹ ka maa ranti pe apọju gbogbo nnkan ko daa, iwọntun-wọnsi ni nnkan dun mọ.
Bi o ba wa ni ipo iloyun, ti o ba n tọmọ lọwọ tabi ti o n loogun ifunpa, ṣọra ki o too mu Zobo.
Yoo daa ki o gba imọran lati ọdọ dokita rẹ ki o too maa fi Zobo ṣe ara rindin.














