Mọ nípa ààrùn West Nile tí kò gbọ̀ oògùn tí ẹ̀fọn ń gbé kírí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, David Cox
- Role, BBC FUTURE
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Lẹyin ọpọ ọdun gẹgẹ nii ọkan ninu awọn oniwadi nipa HIV ati ipa to ko lorilẹede Amẹrika lati koju itankalẹ aarun Covid 19, aarun mii lo sọ Anthony Fauci dero ile iwosan.
Ni oṣu to kọja, ẹni ọdun mẹtalelọgọrin naa bẹrẹ si ni se afihan awọn aami aiṣan iba, otutu ati rirẹ lẹyin ti o lugbadi aarun West Nile, eyi ti ẹfọn n gbe kiri.
Wọn ṣawari aarun yii ni Uganda ni ọdun 1930. Ṣugbọn Fauci ko ko aarun yii ni Ila-oorun Afirika, dipo ẹfọn kan lo bujẹ ni ẹyinkule rẹ , to si sọ di ero ile iwosan.
Awọn ile-iṣẹ fun Iṣakoso ati Idena Arun (CDC) sọ fun BBC pe ẹgbẹrun meji araalu lo n se airẹ West Nile ni ọdọdun, ti 1,200 eeyan si dero ile iwosan, nibi ti o le ni ọgọrun eeyan ti padanu ẹmi wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
“Ẹnikẹni lo le wa ninu ewu yii,” Kristy Murray sọ, ọjọgbọn lati fasiti Atlanta, ni Georgia, ẹni ti o ti n ṣe iwadii nipa aarun West Nile fun ọpọ ọduni. O sọ pe " Ki ẹfọn kan jẹ eeyan ti to lati ko aarun yii. Ati pe awọn agbalagba lo lugbadi aarun yii ju, bẹẹni awọn ọdọ naa.
Ko si ẹnikan ti o mọ ni pato bi aarun yii se wọ orilẹede Amẹrika lati awọn apakan ni Afirika, Aarin Ila-oorun guusu Yuroopu ati Russia nibiti o ti pin kaakiri fun ọpọ ọdun ṣugbọn iwadii ti fihan pe awọn ẹiyẹ lo kọkọ n gbe aarun kiri. Awọn ẹfọn n ko aarun nigba ti wọn ma jẹ awọn ẹyẹ yii ki wọn to lọ gbe sare awọn eeyan.
Lati igba ti aarun ti bẹrẹ ni ọdun 1999, o le ni ẹgbẹrun ọna aadọta ni Amẹrika, ti eeyan to le ni ẹgbẹrun meji si ti padanu ẹmi wọn lati aarun West Nile.
Bayii, itankalẹ West Niles ti gbode ni ilẹ Amẹrika ati lagbaye, ti iwadii si fihan pe ooru amuju lo fa bi awọn ẹfọn se n bu awọn eeyan jẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ko si oogun to gbọ aarun West Niles"
Murray ni o ti se dandan bayii fun gbogbo agbaye lati mọ pe aarun wa laarin wa, ti ko si si ibi to n lọ nitori o ti le ni ọdun mẹdọgbọn bayii ti aarun naa ti n ba orilẹede Amẹrika ja, ti wọn ko nsi ti ri ojutu si aarun West Niles
Ọjọgbọ Murray ni bi awọn se n gbe pẹlu aisan yii fun ọpọ ọdun tun ma n fa awọn aisan mii bi aarun ọpọlọ.
“Fun awọn to ni aisan mi, o seese ki ida mẹwaa padanu ẹmi wọn, ki ida ọgọrin si ni aisan mii le tun jẹyọ.
“Fun awọn ti ko gba aisan yii ku, o ma n buru si ni, to si ma n fa irẹwẹsi ọkan..
Ọpọ igbesẹ ni awọn onimọ nipa oogun ti gbe sugbọn pupọ ninu awọn oogun ti wọn gbe sita ni ko gbọ aarun naa.
Carolyn Gould, onimọ nipa oogun ni Colorado ṣalaye pe ni aarun gbọdọ tan kalẹ de ibi kan ki wọn to le mọ boya oogun ti wọn gbe sita n sisẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images















