Ẹ̀yin obìnrin tọ́kọ yín ń yan àlè, ẹ má kọkọ sílẹ̀ o, ìdí rèé tí ẹ fi gbọdọ̀ forí ti ìgbéyàwó yín - Toyin Tomato

Toyin Adegbola
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agba oṣere tiata Yoruba, Toyin Adegbola, ti ọpọ mọ si Toyin Tomato ti rọ awọn obinrin ti wọn n koju oriṣiiriṣii ipenija ninu igbeyawo wọn wi pe ki wọn ma kuro nile ọkọ.

Toyin Tomato sọrọ yii ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ.

Agba oṣere naa sọ pe ọkunrin ati obinrin ko bara wọn dọgba ninu igbeyawo gẹgẹ bi ero ti oun.

Bakan naa ni Toyin Tomato tun rọ awọn obinrin ti ọkọ wọn n yan ale wi pe ki wọn ma ti tori rẹ kọ ọkọ wọn silẹ.

Imọran to fun wọn ni pe ki wọn tọju ara wọn lọna ti wọn yoo fi le dena kiko arun nipasẹ ibalopọ.

''Ẹ duro sile ọkọ yin, ki ẹ si maa bẹ ọkọ yin wi pe ko maa daabo bo ara rẹ’’

‘’Ko si bi ọkọ rẹ ṣe le buru tabi bajẹ tọ, ma lọ ti tori iyẹn kuro nile ọkọ tabi ki o le ọkọ naa jade.

Ti o ba ṣe bẹẹ, iwọ naa ni wa a pada bẹbẹ to ba ya nigba tawọn ọmọ yin ba ni nkan ti wọn fẹ ṣe.

Ẹyin gẹgẹ bi obinrin ti jiya nile ọkọ, ti ẹ ba wa kuro nile ọkọ, ko si ọkunrin ti koo tii laya nile to maa fẹ yin.

Ẹ duro sile ọkọ yin, ki ẹ si maa bẹ ọkọ yin wi pe ko maa daabo bo ara rẹ,’’ Toyin Tomato lo sọ bẹẹ.

Toyin Tomato sọ pe oun ni ọrẹ kan to maa n ra paali rọba idaabo bo meji fun ọkọ rẹ nigba kugba to ba ti n bọ wa si Naijiria.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Otitọ to wa nibẹ ni pe ẹtọ ọkunrin ati obinrin ju ara wọn lọ - Toyin Tomato

‘’Nigba ti ọkọ ọrẹ mi yii ba si ti de si Naijiria ni o maa n pe mi lati sọ fun mi nipa ohun ti ọrẹ mi ṣe.

Ọkunrin naa a tun sọ fun mi pe ni ṣe loun maa n da rọba idaabo bo ti iyawo oun ba ra foun nu ti oun si maa n ra eyi toun ba fẹ lo fun ra oun.

Ṣe ko ni ba obinrin mii sun ni? Amọ, ṣe obinrin le maa bọ wa si Naijiria ki ọkọ rẹ ra rọba idaabo bo fun un?

Otitọ to wa nibẹ ni pe ẹtọ ọkunrin ati obinrin ninu igbeyawo ju ara wọn lọ, mo ti maa n sọ ọrọ yii tipẹ, mo si maa tẹsiwaju lati maa sọ bẹẹ.

Mo n bẹ awọn ọkunrin lati mu awa obinrin gẹgẹ bi agbelebu ati akọbi ọmọ wọn.

Awa obinrin naa ti fẹ yin, a si ti mu yin gẹgẹ bi akọbi ọmọ wa tori ko si bi ọkunrin ṣe le gbọn to, wọn tun maa pada huwa agọ,’’ Toyin Tomato ṣalaye.

Toyin Tomato tun sọ pe ohun tawọn obinrin ba fẹ kawọn ọkunrin mọ ni wọn maa mọ.

Koda, o tunni ohun tawọn ba fẹ ki ọkunrin ri laarin awọn obinrin atawọn ọmọ ni wọn maa mọ.