Wọ́n ti sin òkú Rukayat Gawat, akọrin Islam tó jáde láyé

Rukayat Gawat

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wọn ti sin oku gbajugbaja akọrin ẹsin Isilaamu, Rukayat Gawat Oyefeso.

Ilu Ayepe-Ijebu, tii ṣe ilu ọkọ rẹ, Shakiru Oyefeso, ni wọn sin oloogbe Rukayat si ni ọsan ọjọ Iṣẹgun.

Nibi eto isinku naa to waye ni ilana ẹsin Isilaamu, ni awọn ẹbi, ara, ọrẹ ati awọn abanikẹdun mii peju si.

Owurọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024, ni oloogbe dagbere faye.

Botilẹ jẹ wi pe a ko le fidi ohun to pa a mulẹ, awọn akẹẹgbẹ rẹ to ba BBC sọrọ salaye pe aisan ranpẹ lo pa a.

"Wọn lo rẹ Rukayat ni, a dijọ wa ni ode ariya Temi ni Success laipẹ yii ni - Barry tide

Nigba to n tara poro nipa iku aitọjọ to pa Rukayat, Barrytide sọ pe:

‘’Haa, Aduke ti lọ o, o ti lọ o. Mi o riru eleyi ri o.

Eleyii ju ẹmi mi lọ o, iwaju ẹ la wa bayii o, ta n pe e, ti ko dahun o.

Aduke ti lọ o, eleyii pọ, haa."

‘’Wọn lo rẹ ẹ ni o. Lọjọ party Temi-ni- Suceess, a jọ wa nibẹ ni, ọjọ yẹn ni mo ri Aduke gbẹyin, ṣugbọn a maa n sọrọ daadaa.

‘’Eeyan daadaa ni, oni la maa sin, ko sẹni kan to gẹẹti ara ẹ ninu gbogbo wa bayii o.’’

Ta a ni Rukayat Gawat?

Abdulrasak Gawat

Oríṣun àwòrán, Other

Àkọlé àwòrán, Ọdun mejila sẹyin ni Alhaji Abdulrasak Gawat, baba to bi Rukayat Gawat Oyefeso, atọkun eto ‘Ẹ ji saari’ lorii tẹlifiṣan deedee di awati
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹ́yìn ọdún méjìlá tí Bàbá rẹ̀ dàwátì, Rukayat Gawat, gbajúmọ̀ olórin Islam, jáde láyé

Ọmọ Oloogbe Abdulrasak Gawat, atọkun eto ‘Ẹ ji saari’ lorii tẹlifiṣan nigba kan ni Ruqayat Gawat.

Lasiko aawẹ Ramadan ni Rasak Gawat maa n ṣe eto rẹ, nigba ti awọn musulumi ba n ji saari lọwọ.

Awọn ẹbun rabandẹ bii ilẹ, aṣọ olowo nla, apo irẹsi ati bẹẹ bẹẹ lọ ti Baba Ruka maa n pin lori eto naa lo sọ ọ di ko ṣee ma wo fun awọn eniyan, titi kan awọn ti ki i ṣe musulumi.

Ṣadeede ni Abdulrasak di awati, ninu oṣu keje ọdun 2012.

Mọto rẹ ni wọn deede ba lori afara ẹlẹkẹẹta (3rd Mainland bridge nipinlẹ Eko), lati ọdun naa ni wọn ko si ti ri Gawat mọ.

Wọn ko ri oku rẹ, bẹẹ ni ẹnikẹni ko foju kan an mọ titi doni.

Iṣẹlẹ iku baba rẹ lo sọ Rukayat Gawat aya Oyefeso di olorin Islam, nigba to gbe awo akọkọ rẹ to pe ni ‘’ Aye le’’ jade.

Ninu awo naa lo ti sunkun kikoro lati daro baba rẹ.

Ọpọlọpọ olorin Islam ni Ruka ti ba kọ orin papọ yatọ si awọn orin tiẹ to da kọ.

Awọn bii Saoti Arewa, Ere Asalatu, Amina ọmọ t’ayebi ati bẹẹ bẹẹ lọ.