Àwọn èèyàn tí àdó ikú Israel pa ní Lebanon wọ 492, 1,645 sì farapa

Eeru n jade lati ilẹ Lebanon
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

O kere tan, eeyan to le ni ẹẹdẹgbẹta o din mẹjọ (492) ni iye eeyan ti awọn ado iku lati ilẹ Israel ti pa ni orilẹede Lebanon.

Gẹgẹ bi ileese eleto ilera ni Lebanon ti wi, o tun le ni eeyan ẹgbẹjọ ati aabọ (1,645) to farapa ninu ikọlu Israel naa.

Bakan naa, lara awọn eeyan to ku ninu ikọlu naa ni ọmọde marundinlogoji, awọn obinrin mejidinlọgọta.

Ẹgbẹlẹgbẹ awọn idile lo ti n sa kuro nile wọn bi ikọ ologun Israel se doju ija kọ ibudo ikọ agbebọn Hezbollah bii ẹgbẹjọ (1,600).

Afojusun ilẹ Israel to fi se eyi ni lati ba awọn ohun eelo amayedẹrun ti ikọ agbebọn naa ti sagbekalẹ rẹ lati asiko ogun to waye ọdun 2006.

Ikọlu naa ni Israel fi n kọju ija si ikọ agbebọn Hezbollah nigba ti ikọ naa ti fi atẹjade sita pe oun ti yin ado oloro si ẹkun ariwa orilẹede Israel.

O ni oun yin ọpọ ado oloro sawọn ibudo iko ohun elo pamọ si ni Israel lati fesi si ọpọ ado oloro ti Israel naa n yin mọ wọn ni guusu Lebanon.

Amọ atẹjade miran ti ileesẹ alaabo nilẹ Israel fisita ni o kere tan, ado iku marundinlogoji ni Hezbollah ti yin mọ oun lati ilẹ Lebanon.

Ọkunrin kan to le ni aadọta ọdun ni ikọ ologun Israel ni o fara pa lẹkun Galilee.

Amọ o ni ikọ ologun ofurufu ti ja awọn ado iku kan to wa lati Lebanon silẹ.

Ado oloro ni Lebanon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O le ni ọọdunrun ibudo ikọ Hisbollah ti Israel ti kọlu ni oni ọjọ Aje nikan

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wayi o, awọn eeyan to n gbe ni ẹkun guusu ilu Lebanon, to fi mọ minisita kan labẹ ijọba ti salaye pe awọn n gba atẹjisẹ ati ohun akasilẹ lori foonu wọn, eyi to n sekilọ fun wọn lati kuro lawọn agbegbe ti ikọ Hezbolla ti sọsẹ́, ti wọn si n lo ohun ija oloro.

Bakan naa, ileesẹ ologun ilẹ Israel ti fi irufẹ ikilọ yii kan naa ransẹsawọn araalu, to si n sọ fawọn eeyan lati yẹba kuro lawọn ibudo ti wọn n foju sun bii eyi to jẹ ti ikọ Hesbollah.

Tun wẹ, eeyan kan ti ku, ti ẹgbẹlẹgbẹ si farapa ninu akọtun ikọlu to n waye ni afonifoji Bekaa.

Isẹlẹ jiju ado iku yii lo tun bẹrẹ ni akọtun lati ọdọ ilẹ Israel eyi to n ju si Lebanon, ti wọn si se apejuwe rẹ bii eyi to tii buru julọ.

Ileesẹ alaabo nilẹ Israel naa ni o le ni ọọdunrun ibudo ikọ Hisbollah ti Israel ti dojukọ ni oni ọjọ Aje nikan.

Minisita feto aabo nilẹ Israel, Yoav Gallant ni ikọlu to n gbona girigiri naa, yoo tubọ tẹsiwaju titi ti awọn yoo fi mu afojusun awọn sẹ.

Afojusun wọn naa si ni lati da ẹgbẹlẹgbẹ awọn ọmọ Israel ti ko nile lori pada si ẹkun ariwa.

Ibeere to si wa lookan aya ọpọ eeyan ni pe se orilẹede Israel yoo wọ inu ilu Labanon lọ bi?

Ado oloro ni Lebanon

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àwọn alágbára àgbáyé rọ àwọn orílẹ̀ède tó ń kọlu ara wọn láti dáwọ́ ìjà dúró

Gẹgẹ bi ẹka ilera ilẹ Lebanon ṣe ṣalaye, ọmọde marundinlogoji(35) ati awọn obinrin mejidinlọgọta (58), wa ninu awọn oku ti wọn ri.

Bakan naa ni eeyan ti ko din ni 1,645 ni wọn farapa, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ boya araalu lasan ni awọn eeyan naa tabi awọn to n jagun.

Minisita fun eto ilera, Firass Abiad, sọ pe idile to le lẹgbẹrun ni wọn ti tuka bayii, ti wọn ko ri ara wọn mọ latari ikọlu to le wọn nile.

Ninu ọrọ Akọwe apapọ ajọ UN, António Guterres, o kọminu si bi ina ogun yii ṣe n fẹju si i, bẹẹ lo ni oun ko fẹ ki Lebanon tun di Gaza keji.

"Ibẹru gidi ni wahala to n le si i yii n mu wa sọkan eeyan, o si lewu gan-an. O ti fẹrẹ di ogun gidi tan." Josep Borrell to n ri si ọrọ ilẹ okeere fun EU lo sọ eyi, ṣaaju ipade apapọ awọn alagbara agbaye, ni New York.

Ni ti Aarẹ ilẹ Amerika, Joe Biden, o ni orilẹede oun n ṣiṣẹ lọna ti awọn eeyan yoo fi le pada sile wọn pẹlu aabo to peye.

Èèyàn rẹpẹtẹ ti kú, mọ̀lẹ́bí ti pàdánù ara wọn nínú ìjà Israel àti Hezbollah

Ninu ija to n waye laarin Israel ati Hezbollah yii, eyi ti ogun Gaza fa, ọpọ ẹmi lo ti sọnu, awọn idile ti ko si pe mọ pọ pẹlu.

Awijare awọn Hezbollah ni pe awọn n ṣe atilẹyin fun Hamas ni, awọn ko si ni i jawọ nibẹ, afi ti ogun Gaza ba pari.

Ikọ ologun mejeeji yii n ri atilẹyin gba lati ọdọ awọn Iran, awọn israel, UK atawọn orilẹede miran si ti ka wọn si agbesunmọmi.

" Awọn Pentagon ni tiwọn sọ pe awọn yoo tun taari ikọ ologun si agbegbe ti ija ti n waye. Olori wọn, Maj Gen Pat Ryder, lo sọ eyi di mimọ fun awọn akọroyin.

Ni kutu hai ọjọ Iṣẹgun, ikọ IDF ṣalaye pe oun ti kofiri ikọlu awọn Lebanon to to ogun niye, ni awọn agbegbe to kun fun oke nla.

O ni awọn ọmọ ogun ofurufu ri awọn kan ko too balẹ, bẹẹ lawọn miran si jabọ si gbagede okuta.

EC collation centre

Ki lo de ti Israel ati Hezbollah n doju ija kọ ara wọn?

Ija to n waye laarin orilẹede Israel ati Hezbollah ko sẹyin ogun to n waye ni agbegbe Gaza.

Ikọ Hezbollah to tẹdo si ilu Lebanon lo yin ado iku kan si ẹkun ariwa Israel lẹyin ọjọ kan ti ikọ Hamas kọlu Israel, eyi to waye lọjọ Keje osu Kẹwa ọdun 2023.

Ikọ Hezbollah ni oun gbe igbesẹ naa lati se atilẹyin fawọn eeyan agbegbe Gaza lori ogun to n lọ laarin rẹ ati Israel.

Amọ aawọ to n waye laarin Israel ati Hezbollah ti bẹrẹ saaju ogun Gaza, to si ni se pẹlu ede aiyede to n waye laarin Israel ati awọn orilẹede to wa ni agbegbe Middle East.

Ikọ Hezbollah lo n se atilẹyin owo, idanilẹkọ ati ohun ija oloro fun orilẹede Iran, tii se ojulowo ọta ilẹ Israel, to si jẹ ikọ ologun to lagbara julọ ni Lebanon.

Ikọ ologun Hezbollah naa si lo safihan ara rẹ bii ikọ ologun to n tako Israel, to si n beere pe ki wọn pa orilẹede Israel run, gẹgẹ bi Iran naa ti n beere.

Ikọ mejeeji ti doju ija kọ ara wọn lati ọdun 1980 ti ikọ Hezbollah ti bẹrẹ, to fi mọ ogun ọlọjọ mẹrinlelọgbọn to waye lọdun 2006.