PDP tako èsì ìbò gómìnà Edo, ó ní olùdíje òun, Asue Ighodalo, ló wọlé ìbò

Oríṣun àwòrán, Okpebholo Monday
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti tako esi ibo gomina ipinlẹ Edo ti ajọ eleto idibo INEC kede lalẹ ana ọjọ Aiku wi pe Okpebholo Monday oludije fẹgbẹ oṣelu APC lo wọle ibo naa.
PDP sọ ninu atẹjade to fi lede loju opo X rẹ pe oludije ẹgbẹ naa, Asue Ighodalo, lo wọle.
Ajọ INEC kede pe Ọgbẹni Monday la oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Ighodalo mọlẹ pẹlu 291,667 si 247,274 ti Ighodalo ni lati wọle ibo ọhun.
PDP sọ ninu atẹjade to fi lede naa pe oun ko faramọ esi ibo naa tori o yatọ gede gede si bawọn eeyan ipinlẹ Edo ṣe dibo.
Ninu ọrọ rẹ, Gomina Ahmadu Fintiri to jẹ alaga igbimọ ipolongo ibo fun PDP lori eto idibo gomina ipinlẹ Edo sọ pe ajọ INEC ti tapa sofin to n ri si ọrọ eto idibo ni Naijiria pẹlu bi o ṣe kede oludije APC gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo to waye lopin ọsẹ.
Ẹgbẹ oṣelu PDP sọ ninu atẹjade ọhun ti akọwe iroyin ẹgbẹ naa, Họnọrebu Debo Ologunagba, fi sita pe esi ibo tawọn aṣoju ẹgbẹ PDP ni gbogbo ibudo idibo kaakiri ipinlẹ Edo kojọ fihan wi pe Ighodalo lo wọle ibo naa.
‘’Gbogbo gira gira, iwa ipa ati eebu ti ẹgbẹ oṣelu APC n bu Gomina Fintiri ko sẹyin ọgbọn alumọkọrọi lati ja ibo tawọn eeyan ipinlẹ Edo di fun Ighodalo eyi to fi wọle ibo gomina Edo gba.
Gẹgẹ bi Gomina Fintiri ṣe sọ, awọn esi ibo lati gbogbo ibudo idibo fihan wi pe Ighodalo lo n lewaju ki APC to ja eto naa gba pẹlu ajọmọ ajọ INEC atawọn ẹṣọ alaabo.
Gbogbo wọn ni jọ yi ibo ti wọn si paarọ ibo ti oludije PDP ri si ti Ọgbẹni Monday ti INEC kede pe oun lo wọle.’’
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
''Esi ibo ti INEC kede kii ṣe bawọn eeyan Edo ṣe dibo rara''
Ẹgbẹ oṣelu PDP fikun ọrọ rẹ ninu atẹjade naa wi pe oun ti kilọ ṣaaju fawọn ọmọ Naijiria tẹlẹ pe oun ko ni gba fun APC lori eeru ti o ba fẹ ṣe ninu eto idibo.
Esi ibo ti INEC kede kii ṣe bawọn eeyan Edo ṣe dibo rara.
PDP tun sọ pe ki ajọ INEC ranti rogbodiyan to ṣẹlẹ eyi to mu ẹmi awọn oṣiṣẹ INEC kan lọ lẹyin ti ọga eleto idibo INEC tẹlẹri nipinlẹ Adamawa, Mallam Hudu Ari, gbiyanju lati yi esi ibo gomina to waye nipinlẹ naa pada.
Aṣoju PDP ni ibudo ti wọn ti n ko ibo jọ niluu Benin, Iyoha Osaigbovo, naa sọ pe ibo ti INEC ka fun ẹgbẹ oṣelu APC kii ṣe bawọn eeyan Edo ṣe dibo.
Osaigbovo ni ‘’a o gba esi ibo yii wọle, tori o fihan gbangba wi pe INEC bu ibo fun oludije APC ki o le wọle.
Esi ibo ti INEC kede ti kii ṣe ifẹ awọn araalu le pada wa ṣakoba fawọn to ṣe ikede naa.
APC sọrọ lori eto idibo gomina Edo
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Edo, Jarret Tenebe, ti tako gbogbo PDP lori gbogbo ẹsun to ka si APC ati INEC lọrun lori eto ibo gomina to waye lopin ọsẹ l’Edo.
Ọgbẹni Tenebe sọ pe esi idibo ti ajọ INEC kede tẹ oun lọrun toru oludije APC lo wọle ibo naa ni tootọọ gẹgẹ bi INEC ṣe kede rẹ.
Alaga APC nipinlẹ Edo sọ pe apa ariwa Edo ti APC ti jawe olubori jẹ ọkan lara awọn ẹkun ti ẹgbẹ oṣelu naa ti fidi mulẹ daadaa papaa julọ lẹyin ti igbakeji gomina to gba ipo rẹ pada, Philip Shaibu, pada sinu ẹgbẹ naa.
Nigba ti o n sọrọ lori ohun ti Osaigbovo sọ pe ẹrọ BVAS daṣẹ silẹ tabi wi pe wọn kọwọ bọ ọ, Ọgbẹni Tenebe ni PDP ko gbọdọ darukọ APC lori ọrọ naa raa.
O sọ pe ni ṣe lo yẹ ki PDP maa sọ nipa akojọpọ ati ikede esi ibo lasan.















