Anthony Joshua sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Daniel Dubois fi ẹ̀ṣẹ́ àlùwó dá a dùbúlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe abẹṣe-ku-bi-ojo ọmọ Naijiria ati Gẹẹsi, Anthony Joshua, padanu ninu idije International Boxing Federation (IBF), to waye laarin oun ati Daniel Dubois, sibẹ, Joshua loun ko ni i tori ẹ fẹyinti.
Tẹ o ba gbagbe, Daniel Dubois gba ami-ẹyẹ ‘IBF heavy weight Champion’ nigba to fi ẹṣẹ gbe Anthony Joshua ṣubu ni ipele karun-un ija naa.
Idije nla naa waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024.
Nigba to n sọrọ lori iṣubu rẹ yii, AJ, bawọn eeyan ṣe tun mọ Anthony Joshua si, sọ pe:
" Bẹẹ ni, mo ṣi fẹẹ tẹsiwaju lati maa ja.
"A gbiyanju lati yege, idakeji rẹ si ṣẹlẹ. Ṣe ka waa maa sa lọ ni abi ka duro ka le ja nigba mi-in? Akọni ni mi."
Ipinnu AJ ni lati darapọ mọ awọn akọni iṣaaju ninu ẹsẹ kikan, awọn bii Muhammad Ali, Lennox Lewis, Evander Holyfield ati Vitali Klitschko, koun naa si di abẹṣe-ku-bi-ojo to gba ami ẹyẹ yii lẹẹmẹta.
Bi àpá ṣe wa nisalẹ oju rẹ mejeeji ati ọrun rẹ to latari ija oun ati Dubois, Anthony Joshua tun sọ ọrọ akin pe, "Maa figba gbogbo dá ara rẹ loju, ma ja ja irawọ ara rẹ walẹ’’
" A fẹẹ fi itan balẹ fun ẹṣe kikan nilẹẹ Gẹesi, mo si ro pe a n ṣe e."
O kere tan, yoo to ẹgbẹrun lọna ẹedẹgbẹta eeyan (500,000 fans) ti wọn ti wo ija AJ ni gbọngan ẹṣẹ mẹfa nilẹẹ Britain.
Orilẹede naa ko kọ iyan rẹ kere labala idagbasoke to ti mu ba ẹṣẹ jija nilẹe Gẹesi.
Ija to waye laaarin Anthony Joshua ati Daniel Dubois yii ni akọkọ ninu ija agbaye rẹ lẹyin to padanu si ọwọ Oleksandr Usyk, ninu ija WBA (Super), IBF ati WBO loṣu kẹjọ ọdun 2022.

Ó yà mí lẹ́nu pé Joshua fìdírẹmi nínú ìjà yìí-Usyk
Ninu ero tirẹ, Oleksandr Usyk, ọmọ orilẹede Ukraine to fi ẹyin Anthony Joshua balẹ leralera ni 2021 ati 2022, sọ pe o ya oun lẹnu pe AJ fidirẹmi ninu ija agbaye yii.
‘’Fun emi o, o ya mi lẹnu gan-an. Ero ọkan mi ni pe Joshua yoo bori ija naa’’
Bayii ni Oleksandr to gba ami-ẹyẹ WBA, WBC ati WBO sọ fun ẹka iroyin Sky Sports.
Usyk to gba isinmi ranpẹ bo ṣe n gbaradi lati koju Tyson Fury lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila ọdun yii, ko ti i fidi rẹmi ri inu ija mejilelogun to ti ja.
O darapọ mọ abala awọn agba ọjẹ to wa bayii, o si n rọwọ mu lọ lai si iṣoro.














