Wo oyè pàtàkì méje nílẹ̀ Yorùbá tó wà fáwọn obìnrin alágbára

Obinrin to wà nínú awo eleegun
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ní àwùjọ kọọkan, ipò pàtàkì ni àwọn obìnrin di mú bóyá nínú ilé, ní ọjà, láwùjọ òsèlú àti nínú ẹgbẹ́ àwo.

A sì le ṣe àpèjúwe àwọn obìnrin bíi kò sí mi, àjọ kò kún, ní awujọ nítorí àwọn ojúṣe pàtàkì tí wọn ń ṣe láwùjọ wá.

Pàtàki ojúṣe àwọn obìnrin yìí sì ti bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà ìwáṣẹ̀, nígbà tí Yorùbá ti ń ṣe àkóso ara wọn, ṣáájú kí àwọn òyìnbó amúnisìn tó dé.

Kódà, àwọn aṣáájú ìlú tàbí àwùjọ bíi ọba, baálẹ̀ àti baálé gan-an kò jẹ́ kọ iyán àwọn obìnrin yìí, kò ma fi ewé bò ó

Lára àwọn oyè pàtàkì tí àwọn obìnrin dì mú náà ni Ìyálóde, Ìyá Àgan, Ìyálọ́jà, Ìyálájé, Ìyá Àbíyè, Ìyá Èwe àti Erelu.

Ní àwọn àgbègbè miràn nílẹ̀ Yorùbá, wọn máa yí orúkọ ìyá yìí padà sí Yèyé èyí tó ní ìtumọ̀ kan náà, àwọn obìnrin tó jẹ́ àgbàlagbà sì ni wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀.

BBC Yorùbá wá ṣe àkójọpọ̀ àwọn oyè pàtàkì méje nílẹ̀ Yoruba tó wà fún àwọn obìnrin nìkan.

Ìyálóde

Oyè Ìyálóde wà fún àgbà obìnrin ni ìlù tàbí àwùjọ kan, a sì lè pé ẹni tó bá jẹ́ òye iyalode ni ọba àwọn obìnrin tó wà ní àárín ìlú náà.

Ìyálóde máa ń wà nínú ìgbìmọ̀ àwọn olóyè ńlá tó ń darí ìlú èyí tí ọba tàbí baalẹ ko sodi.

Bákan náà, Ìyálóde lo jẹ asiwaju fún àwọn obìnrin tó wà nínú ìlú tàbí abúlé, ti wọn si maa n wa rìrì fún.

Ojúṣe Ìyálóde ni lati maa gbe àwọn ọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ mọ àwọn obìnrin lọ síwájú ìgbìmọ̀ àwọn olóyè àgbà àti oriade ìlú náà, láti jíròrò le lori.

Oyè Ìyálóde kìí ṣe oyè lásán ní àárín ìlú, tí wọn leè gbé fún obìnrin lásán.

Akinkanju obìnrin tó ń ṣíṣẹ́ takuntakun ni obìnrin tó máa ń jẹ Ìyálóde nitori oyè yìí ló ga julọ tí obinrin leè jẹ.

Níbi tí òye iyalode ṣe pàtàkì tó, Iyalode ni àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tiẹ̀ bíi Ọtun Iyalode, Òsì Iyalode, Ẹ̀kẹrin àti Ẹ̀karùn-ún Iyalode.

Lára àwọn gbajúmọ̀ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá tó jẹ́ oyè Ìyálóde ni Ìyálóde Efunroye Tinubu, Efunsetan Aniwura, iyalode ilẹ̀ Ibadan, Ìyálóde Alaba Lawson.

Ìyálọ̀jà

Oyè aṣáájú àwọn obìnrin miran tó tún ṣe pàtàkì nílẹ̀ Yorùbá ni Iyaloja.

Oyè náà sì lo wa fún àgbàlagbà obìnrin tó jẹ́ oníṣòwò tàbí ìnájà tó ń ṣe kárakára ninu ọjà.

Ojúṣe Iyalọja ni lati maa se akoso ọjà laarin awọn obinrin, kò parí ìjà laarin wọn, kí wọn rí sì agbega ìlú àti ṣíṣe odiwọn owó ọjà kọọkan.

Lára àwọn gbajúmọ̀ Iyalọja nílẹ̀ Yorùbá ni Abibat Mogaji, Folashade Tinubu Ojo.

Erelú

Erelú

Oyè Erelú jẹ òye àwọn obìnrin tó máa ń bá ìgbìmọ̀ ìlú jíròrò nípa ààtò ìlú.

Bákan náà, wọn máa ń fi òye Erelú ìlú dá àwọn ìyá tó bí ọba lọla.

Oyè yìí sí wa fún àwọn àgbà obìnrin tó wà láti ìdílé ọba tàbí tó ní owó àti ọlá ni awujọ.

Àwọn àgbààgbà obìnrin nínú ẹgbẹ́ awo bíi Ogboni, ní wón tún máa fi ń jẹ òye Erelú.

Erelú àkọ́kọ́ nílẹ̀ Yorùbá ni Erelú Kuti, tíí ṣe Omooba Addo nilu Eko ni ọdún 1630,oun si ni ìyá ìyá Ọba Akintoye tilu Eko.

Àwọn obìnrin míràn tó tún jẹ́ oyè Erelu ni Erelu Talabi, Erelu Abiola Dosumu àti àwọn miran.

Ìyálàjè

Oyè ìyálájé fi ara jọ oyè Ìyálọ́jà ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ kékeré lo wa laarin wọn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Iyalọja wá fún ọjà, àwọn ontaja sì lọ máa ń jẹ Iyalọja ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àgbègbè kan ló máa ń fà Iyalaje kalẹ.

Lootọ ni ojúṣe wọn ní àwùjọ jọ ara wọn, torí isẹ wọn ní láti ṣe akoso àwọn obìnrin.

Bákan náà ni iyalaje je koriya fáwọn obìnrin, to sì máa ń kọ àwọn obìnrin jọ láti jẹ ki wọn jẹ anfani lọpọlọpọ lọdọ ìjọba tàbí oriade.

Ọba lọ máa ń fi iyalaje jẹ gẹ́gẹ́ bíi oyè àwọn obìnrin miran, tí Iyalaje náà sì jẹ àgbà òye fún àwọn obìnrin tó ní ọlá, owó àti òkìkí ni awujọ.

Lára àwọn gbajúmọ̀ obinrin tó jẹ́ oyè Iyalaje ni Ọmọ ọbabìnrin Toyin Kolade

Ìyá Àgan

Oyè ìyá Àgan wà fún àgbàlagbà obìnrin nínú ìdílé Eleegun.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin lo maa n gbé egungun, àmọ́ àwọn amugbalẹgbẹ wọn máa ń jẹ àgbà obìnrin tí wọn máa ń pe ni ìyá Àgan.

Ìyá Àgan sì ni olórí obìnrin fún àwo Egungun, ó sì jẹ ohun kan ṣoṣo tó sọ àwọn òrìṣà àti àwọn alalẹ papọ.

Ní àkókò tí a wà yìí, oyè Ìyá Àgan kò wọ́pọ̀ mọ bí kò ṣe laarin awọn obinrin tó wà nínú ẹgbẹ́ awo bíi Ògbóni.

ìyá Àbíyè

Oyè ìyá Abiye wá fún àgbà obìnrin tó máa ń gbẹbi fún àwọn obìnrin tó lóyún, tí wọn sì ń rọbi láti bímọ lọ́jọ́ ikunlẹ.

Ní ayé àtijọ́, ko sì ilẹ̀ ìwòsàn tí àwọn obìnrin máa ń bímọ sì, inú ilé àgbà obìnrin kan ni aarin ìlú ni wọn máa ń lọ láti bímọ.

Iya Abiye yìí sí máa ń lọ imọ Yoruba bíi ewé àti egbò láti gbẹbi fún àwọn Oloyun.

Oyè ìyá Abiye yìí sí ṣe kókó ni aarin ìlú láyé àtijọ́ nítorí ikú àti ìyè àwọn Oloyun laarin ìlú wa lọ́wọ́ rẹ

ìyá Èwe

Àgbàlagbà obìnrin tó fẹ́ràn ọmọdé àti ọ̀dọ́, tó máa ń kọ wọn mọ́ra, ní wón ń pè ní Ìyá Èwe.

Iya Èwe lọ máa ń gba àwọn ọdọ ni ìmọ̀ràn nípa ìrírí ayé àti bí wọn ṣe le e rìn lai fi ẹsẹ gbún òkúta nílé ayé.

Iya Èwe tún máa ń tọ àwọn ọdọ yìí sọ́nà lórí igbesẹ wọn lojoojumọ, kí wọn máa bá sì ẹsẹ gbe.

Ojúṣe abiyamọ àti òbí tòótọ́ ni Iya èwe ń kọ laarin ìlú, tí àwọn ọdọ ìlú kii si fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣeré.

Àmọ́ lóde òní, wọn tí gbé òye Iya Èwe wọ ilé ìjọsìn nítorí àwọn obinrin lorisirisi tí ń jẹ òye ìyá èwe ni ṣọọsi.

Òun sì lọ máa ń fi ona ìjọsìn hàn àwọn ọdọ nínú ìjọ kan, tó sì tún máa ń gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn nípa igbe ayé wọn.