Ọlọ́pàá yìnbọn pa dókítà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀sìn Islam

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọlọpaa ila oorun orilẹde Pakistan ti yinbọn pa ọkunrin kan to jẹ dọkita lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o sọrọ odi si ẹsin Islam.
Ọkan lara awọn ọga ọlọpaa agbegbe naa sọ pe ṣe ni ọlọpaa ṣeṣi yibọn pa dọkita Shahnawaz Kanbhar ti wọn ko si mọ pe oun ni.
Ṣaaju ni Shahnawaz ti kọkọ lọ sa pamọ lọjọ Iṣẹgun lẹyin ti awọn kan fẹsun kan an pe o sọrọ odi si anọbi Muhammad to tun n pin ọrọ odi nipa ẹsin Islam loru ayelujara.

Oríṣun àwòrán, Social media
Dokita naa ni ẹni keji ti wọn yoo yinbọn pa laarin ọsẹ kan ṣoṣo lori ẹsun sisọ ọrọ odi nipa ẹsin Islam.
Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, awọn ọlọpaa kan niluu Mirpur Khas n le awọn ọdọkunrin meji kan lori alupupu.
Amọ bi wọn ṣe n le awọn ọdọkunrin naa ni awọn afurasi ọhun ṣina ibọn fun ọlọpaa, ti awọn ọlọpaa si da ina ibọn naa pada fun wọn.
Wọn ni lẹyin ti wọn yinbọn fun ara wọn tan ni wọn to mọ pe awọn ti yinbọn pa dokita ọhun ti wọn fẹsun ọrọ odi si Islam kan ṣaaju.
Iroyin ọlọpaa sọ pe oloogbe naa wa lara awọn ọdọkunrin meji ti wọn n le lori alupupu.
Ọlọpaa mii to ba BBC sọrọ ni ẹnikeji to wa lori alupupu pẹlu dokita ọhun lo yinbọn pa.
Amọ nigba ti BBC kan si mọlẹbi oloogbe ọhun, o ni ṣe ni ọlọpaa mọọmọ pa ọkunrin naa ti wọn si pa irọ mọ pe o kọju ibọn si awọn.
Wayi o, minisita fun ọrọ abẹle fun agbegbe Sindh, Zia-ul-Hasan Linjar ti paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.















