Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì Ibadan ṣe ìwọ́de nítorí àfikún owó ilé ẹ̀kọ́ wọn

Awọn akẹkọọ fasiti ilẹ Ibadan ṣe iwọde tako afikun owo ile ẹkọ wọn.
Nibi iwọde ti wọn ṣe l'owurọ ọjọ Ẹti ninu ọgba ile ẹkọ giga naa, awọn oluwọde naa gbarata lori afikun ti awọn alokoso ile ẹkọ naa mu ba iye owo ti awọn akẹkọọ n san.
Ọkan lara awọn akẹkọọ to le iwaju iwọde naa, Aduwọ Ayọdele ṣe alaye fun awọn akọroyin wi pe, inira nla gbaa ni igbesẹ naa ti mu ba gbogbo akẹkọọ fasiti ilẹ Ibadan.

O ni owo to pọ ju ti awọn n san tẹlẹ gẹgẹ bii akẹkọọ, ko to ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira, ṣugbọn ni bayii, afikun ti wọn mu ba owo ile ẹkọ naa ti wa laarin ẹgbẹrun lọna igba si ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira.
Ayọdele tẹsiwaju wi pe igbesẹ yii ti mu ki aye su ọpọlọpọ akẹkọọ, ti o si ti sun wọn de ibi ti wọn ti n ṣe awọn nnkan ti ko tọna lati le ri owo ile ẹkọ san.


Laipẹ yii ni awọn akẹkọọ fasiti ilẹ Ibadan kan fọn si ori itakun agbaye lori ikanni ibadọrẹ ‘X’, ni ibi ti wọn ti n tọrọ owo lọwọ awọn ẹlẹyinju aanu to le san owo ile ẹkọ wọn.
Oni yii ni igba ikẹta ọtọọtọ ti awọn akẹkọọ naa yoo ṣe iwọde tako aleekun owo ile ẹkọ wọn.
Igba akọkọ ni laarin ọjọ ikẹrindinlogun si ikẹtadinogun oṣu keje ọdun yii, bakan naa ni wọn tun wọde laarin ọjọ kọkandinlọgbọn si ọjọkọkanlelọgbọn oṣu kẹjọ ọdun yii. Awọn alakoso ile ẹkọ giga naa si paṣẹ wi pe ki gbogbo awọn akẹkọọ kuro ninu ọgba ile ẹkọ naa ki wọn si pada lọ si ile wọn. Oni ogunjọ oṣu kẹsan an ọdun 2024 ni wọn ṣi ọgba ile ẹkọ naa pada.
Lara ohun ti awọn oluwọde naa n pe fun ni pe ki ijọba apapọ fi kun iye owo ti wọn n ya sọtọ fun eto ẹkọ, ki awọn alakoso fasiti ilẹ Ibadan da owo ile ẹkọ pada si iye to wa tẹlẹ, bẹẹ sini ki wọn yi ero wọn pada lori awọn oluwọde mẹta ti wọn n gbero lati le kuro ninu ile ẹkọ naa.
Awọn oluwọde mẹta naa ni:
Aduwo Ayọdele, Nice Linus ati Mide Gbadegẹṣin.
Wamuwamu ni awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Ọlọpaa duro ni ita ọgba ile ẹkọ naa lasiko ti wọde n lọ lọwọ ninu ọgba.
A kan si alukoro fasiti ilẹ Ibadan, Arabinrin Adejọke Akinpẹlu lori iwọde naa, ṣugbọn o ni ko si nnkan kan ti awọn alakoso ile ẹkọ naa fẹ sọ lọwọlọwọ bayii.

Oríṣun àwòrán, Others
Àfikún owó ilé ẹ̀kọ́ sọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ibadan di oníbárà lórí ayélujára
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìjọba àpapọ̀ ti ìlú Ibadan (University of Ibadan, UI) ti ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ọmọ Nàìjíríà láti ran àwọn lọ́wọ́ láti san owó ilé ẹ̀kọ́ wọn.
Èyí kò ṣẹ̀yìn àfìkún tó gorí owó ilé ẹ̀kọ́ náà.
Ṣáájú ni àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ibadan ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa láti ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ nítorí ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe nítorí àfìkún tó bá owó ẹ̀kọ́ wọn.
Gẹ́gẹ́ bí nǹkan táwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún sọ, wọ́n fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìsinmi ọ̀sẹ̀ mẹ́ta kí wọ́n fi wá owó láti fi san owó ẹ̀kọ́ wọn, kí wọ́n sì ṣe ìforúkọsílẹ̀.
Wọ́n ní àwọn ti sún ìdánwò ètò ẹ̀kọ́ sáà kìíní sí ọjọ́ Kẹtàlélógún oṣù Kẹsàn-án.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ UI ni kò rí owó ilé ẹ̀kọ́ wọn san nítorí bí àlékún tó lé ní ìdá ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà ṣe gun owó ilé ẹ̀kọ́ náà.
Àwọn ẹ̀ka tó máa ń san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n náírà (N30,000) ni àfìkún ti bá owó wọn di ẹgbẹ̀rún òjìlérúgba dín mẹ́wàá náírà (N230,000) tí àwọn tó ń san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta náírà (N60,000) tẹ́lẹ̀ ni owó ti di ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìrínwó lé méjìlá náírà (N412,000) báyìí.
Èyí mú kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ìwọ́de láti fi ẹ̀hónú hàn pé àlékún pọ̀ púpọ̀ àti pé agbára àwọn kò ká láti san owó ọ̀hún.
Láti ìgbà tí àwọn aláṣẹ ti ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ń wá ọ̀nà kan tàbí òmíràn, tó fi mọ́ orí ayélujára láti fi san owó ẹ̀kọ́ wọn tó fi mọ́.
Bí owó ilé ẹ̀kọ́ sì ti ṣe gbówó lórí, ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ gba ẹ̀yàwò akẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọba àpapọ̀ gbá kalẹ̀ ni kò ì tíì rí ìbuwọ́lù àjọ náà.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ni wọ́n ti ń tọ̀rọ̀ owó lórí ayélujára fúnra wọn, táwọn ẹgbẹ́ ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ mìíràn sì ń gba owó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn.
Lára àwọn ẹgbẹ́ tó ń bèèrè fún owó fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn ni ẹgbẹ́ àwọn Mùsùlùmí. Nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sórí ìkànnì X wọn rọ àwọn èèyàn láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́.
Àtẹ̀jáde náà sọ pé látàrí àlékún àti ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà tó mẹ́hẹ ti ṣokùnfà kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan má rì í owó ilé ẹ̀kọ́ wọn tó sì lè ṣokùnfà kí wan pa ẹ̀kọ́ wọn tì.
“A rọ àwọn èèyàn láti ṣe ìrànwọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣeéṣe kí wọ́n pàdánù ètò ẹ̀kọ́ wọn nítorí àìrí owó san.”
Bákan náà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ètò àyíká ìyẹn Environmental Design ti darapọ̀ mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń tọ̀rọ̀ owó lórí ayélujára.
Wọ́n ní àwọn ń bèèrè fún ìrànlọ́wa fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ láti san owó ilé ẹ̀kọ́ wọn.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lẹ́ka ìmọ̀ ẹ̀rọ Petroleum náà kò gbẹ́yìn tí àwọn náà sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́ wọn lórí ayélujára láti bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Ẹ̀wẹ̀, àjọ tó ń rí sí ẹ̀yàwò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní Nàìjíríà (NELFUND) ti bẹ̀rẹ̀ pínpín ọ̀kànlénígba mílíọ̀nù náírà (N201,000,000) fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ 1,370 tó forúkọ sílẹ̀ fún ẹ̀yàwò láti inú oṣù Karùn-ún.
Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ti forúkọ sílẹ̀ ni wọn kò tíì rí ìbúwọlù àjọ náà títí ti àsìkò yìí.
Ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní UI sọ pé àwọn ti kàn sí NELFUND láti ri pé wan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àwọn ní ẹ̀yàwò náà kó tó di ogúnjọ́ oṣù Kẹsàn-án àmọ́ àwọn kò rí èsì kankan.
Èyí ló mú kí ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní tọrọ owọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún kí wọ́n má ba à pàdánù ẹ̀kọ́ wọn.















