Ẹ má sunkún fún Dele Gold nítorí ó gbé ìgbéayé rẹ̀ fún Ọlọrun – Pásítọ̀

Oluṣọ aguntan, S. Balogun ti rọ awọn mọlębi oloogbe Dele Agbeyo, ẹni tí ọpọlọpọ mọ si Dele Gold pe ki wọn ma sunkun fun eeyan wọn mọ nitori o gbe igbeaye rẹ fun Ọlọrun to si ti ṣẹgun ogun aye.

Balogun lo sọ eyi nigba to n waasu níbi eto isinku Dele Gold ni agbegbe Abule Egba, nipinlẹ Eko
O ni Dele Gold lo dukia rẹ ati gbogbo ohun tí Ọlọrun fun un lati fi sin Ọlọrun ati ìjọ Ọlọrun.
O ni “Dele ran mi si ẹyin, ẹ ma sunkun fun mọ, o yẹ kí inu yin ma a dun ni nitori o ri aanu gba.

“O dara lati lọ sibi eto isinku ju ki a lọ si ayẹyuẹ igbeyawo lọ.
“Dele ran mi sí yín pe ki ẹ yi iwa ibajẹ yin pada, ki ẹ si tẹle ofin ati ilana Ọlọrun.

“Bakan naa ni Dele n lo asiko yii lati sọ fun awọn eeyan pe kí wọn tun aye wọn to, ki wọn sì dirọ mọ opo Ọlọrun. Ki a ni ajọsepọ nla pẹlu Ọlọrun."
Alufaa naa tẹsiwaju pe ki awọn eeyan to wa nibi eto isinku ọhun lati maa muara silẹ fun ọjọ ìkẹyìn.


Báyìí ni ètò ìsìnkú gbajúgbajà àkọrin ẹ̀mí, Dele Gold, ṣe n lọ

Eto isinku gbajugbaja akọrin ẹmi, Dele agbeyo, ti ọpọ eeyan mọ si Dele Gold, ti n waye.
Ile to wa ni agbegbe Abule-Egba, nipin Eko, ni isinku naa ti n waye.
Ọjọru, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024, ni Dele Gold jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọta.
Iku rẹ waye lẹyin ọsẹ diẹ ti Aduke Ajayi ti ọpọ mọ si Aduke Gold dagbeje faye.
Ọjọru to pe ọsẹ kan geerege to ku ni wọn ṣe eto orin idagbere ati titan abẹla fun un nipinlẹ Eko.
A ko le fidi nnkan to pa Ọgbẹni Dele agbeyo mulẹ, ṣugbọn iroyin sọ pe o ku lẹyin aisan.

Oríṣun àwòrán, Dele Gold/Instagram
Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Dele Gold

Oríṣun àwòrán, Dele Gold/Instagram
Ilu Usi, nipinlẹ Ekiti ni wọn bi Dele si, o si dagba niluu Faforiji, to wa nipinlẹ Osun.
Oun ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Prodel Music, to jẹ ileeṣẹ to n gbe orin jade, oun tun ni aburo oloju aanu to tun jẹ alaṣẹ ileeṣẹ Cornfield Group of Companies, iyẹn Tope Agbey.
O sọ ninu ifọrọwerọ kan ṣaaju iku rẹ pe oju ala ni oun ti gba ẹbun orin kikọ bo tilẹ jẹ pe oun ko fẹ kọ orun tẹlẹ.
Dele bẹrẹ orin kikọ labẹ itọni agba ọjẹ olorin juju, Ebenezer Obey lọpọ ọdun sẹyin.
Lọdun 2019, oun ati Baba Ebenezer Obey gbe orin kan jade ti wọn pe ni “Hearty Blessings” orin naa si mi gbogbo ilu titi.
Yatọ so orin ọhun, awọn orin mii ti Dele kọ to tun milẹ titi ni “Divine Warning, Every Knee, Infinite God,” ati “A Thousand Tongues.”
Yatọ si baba Ebenezer Obey, awọn olorin mii ti Dele tun ti ṣiṣẹ pẹlu ni Sir Shina Peters, Lanre Teriba (Atorise), ati Abel Dosunmu (Mega 99).













