Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

O darinako, o doju ala, o tun di bẹni ba n jọni

Hmmmm! Ilẹ n jeeyan o

Abi, Oku gbajumọ olorin ẹmi nni, Dele Gold ti wọ kaa ilẹ sun

Ni ile rẹ to wa ni Abule Egba ni eto isinku naa ti waye lọjọbọ

Ẹbi, ara, ọrẹ atawọn ololufẹ Dele Gold lo peju pesẹ sibi eti isinku naa

Lọjọru ọsẹ to kọja ni Dele Gold jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọta lẹyin aisan

Ẹ lọ fọkan balẹ, a ti n gbe igbesẹ to yẹ lori ilẹ mimi to n waye niluu Abuja

Minisita fọrọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ, Uche Nnaji lo sọ aridaju bẹẹ

Lẹyin ti iṣẹlẹ ilẹ mimi da ibẹrubojo sọkan awọn olugbe Maitama, Katampe ati Mpape

O ni awọn ti n gbe igbesẹ lati ri pe ko waye mọ

Inu fu, aya fu gbọkan awọn eeyan lorilẹ ede Lebanon

Latari ibugbamu mii to tun waye lẹyin ọjọ kan ti ibugbamu awọn ẹrọ ibanisọrọ pager ṣekupa eeyan mẹsan-an

Niṣe lawọn ẹrọ ibanisọrọ mii tun bu gbamu lasiko ti wọn n ṣẹyẹ ikẹyin fawọn to padanu ẹmi nibi ibugbamu akọkọ

Eeyan mẹrinla lo tun dagbere faye, tawọn to le ni irinwo si farapa

Ko see ma gbọọ