Oru mú ọmọdé mẹ́rin pa lẹ́yìn tí wọ́n há sínú fìrííjì tí wọ́n ti ń ṣeré

Firisa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Inu ibanujẹ ni awọn mọlẹbi mẹrin wa, lẹyin ti awọn ọmọ wọn ku sinu firiiji niwaju ile wọn.

Awọn ọlọpaa gbagbọ pe ṣe ni awọn ọmọ naa ha sinu ẹrọ amounjẹ tutu ọhun lasiko ti wọn n ṣere ninu rẹ, ti oru si mu wọn pa.

Wọn ba oku meji ninu awọn ọmọde naa, ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹta si mẹfa ninu firiiji ọhun ti wọn ko lo mọ niluu Mulio, agbegbe Zambesi.

Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Namibia ti bẹrẹ iwadii lori iku awọn ọmọde naa.

Ninu awọn ọmọde mẹrin ti ọrọ naa kan, meji ninu wọn ni wọn ku sinu ẹrọ amounjẹ tutu ọhun, ti awọn meji to ku si jade laye nibi ti wọn ti n gba itọju nile iwosan.

Ọkan lara baba awọn ọmọ naa, Aranges Shoro, sọ fun awọn akọroyin pe “nigba ti mo wọle, mo ri awọn oṣiṣe eto ilera pajawiri ti wọn n ṣetọju ọmọ mi obinrin ati ọmọdebinrin miran.

“Wọn gbe wọn digbadigba lọ sile iwosan nigba ti wọn ko awọn meji to ku sinu ile igbokupamọsi.

Ọga ọlọpaa agbegbe Zambezi, Andreas Shilelo sọ fun ileeṣe iroyin AFP pe “nnkankan wa lara ẹrọ amounjẹ tutu naa ti wọn le fi ṣi lati ita nikan.

“Nnkan bii wakati kan abọ lawọn ọmọ naa lo ninu ẹrọ ọhun ki oru to mu wọn pa.”

Ileeṣẹ iroyin NBC ni awọn meji ti wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan Katima Mulilo ku ki wọn to gbe wọn de ibẹ.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ko si ẹni to le sọ eredi ti wọn ṣe gbe ẹrọ amounjẹ tutu naa siwaju ile ọkan lara awọn mọlẹbi ti ọrọ naa kan.