Èèyàn bí i 3,000 farapá lẹ́yìn tí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ‘Pager’ tí Hezbollah ń lò gbiná mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ ní Lebanon

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ijọba orilẹede Britain ti darapọ mọ ajọ United Nations ati ilẹ America, lati fi ikilọ sita lori bi awọn ẹrọ kekeke ti ikọ Hezbollah n lo fun ibaraẹnisọrọ, ṣe n bu gbamu mọ awọn eeyan ni apo jakejado orilẹ-ede Lebanon lọjọ Iṣẹgun.
Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo farapa yanna-yanna ni Lebanon, lẹyin ti ẹrọ kekere ti ikọ ajijagbara Hezbollah n lo fun ibaraẹnisọrọ, bẹrẹ si bu gbamu mọ ni akoko kan naa jaejado orilẹ-ede naa.
Ko sin ni eeyan mẹsa-an to ku, ti bii 3,000 si farapa.
Lootọ ni ko ti fojuhan ni pato lori bi ibugbamu naa ṣe waye, amọ Hezbollah ti di ẹbi rẹ ru ọta wọn, orilẹ-ede Israel.
Isreal ko ti sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ ọhun.
Ninu fidio kan to wa lori ayelujara nipa iṣẹlẹ naa, a ri ti ẹrọ ibaraẹnisọrọ naa ti wọn n pe ni ‘Pager’, bu gbamu ni ile itaja nla kan. Eyi ti ẹnikan ti ṣubu lulẹ lojiji.
Ni nnkan bi aago mẹrin ku iṣẹju mẹẹdogun l’orilẹ-ede naa ni ibugbamu bẹrẹ ni olu ilu Lebanon, Beirut lọjọ Iṣẹgun.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe niṣe ni eefin ina n jade ninu apo aṣọ awọn eeyan, ti ibugbamu to dun bi iro ibọn si n dun.
Ninu fidio miran, a ri ọkunrin kan to duro nile itaja kan, ti ibugbamu ṣẹyọ ninu apo rẹ.
Ko pẹ ti awọn ibugbamu yii waye, ni ọpọ ero n wọ lọ si awọn ileewosan jakejado Lebanon.
Minisita fun eto ilera ni orilẹ-ede naa sọ pe 200 lara wọn lo wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Oju, ẹyinju, ọwọ, ati ibadi, ni pupọ ni awọn eeyan ti farapa, ti ika ọwọ awọn eeyan kan si ti ge sọnu.
Aṣoju ijọba orilẹ-ede Iran si Lebanon, naa farapa ninu ikọlu ọhun.
Ileeṣẹ iroyin Hezbollah sọ pe ọmọ ogun wọn mẹjọ lo ku ninu ikọlu naa, loju ọna wọn si Jerusalẹmu.
Bakan naa ni Syria, nibi ti awọn ọmọ ogun Hezbollah ti ba ileeṣẹ ologun to jẹ ti ijọba jagun. Iroyin sọ pe eeyan mẹrinla farapa latara ibugbamu awọn ẹrọ ibanisọrọ kekeke.
Ileeṣẹ wo lo n ṣe Pager?
Oludasilẹ ileeṣẹ awọn nnkan to n lo ina, Gold Apollo ni Taiwan, sọ pe ileeṣẹ oun ko mọ nkankan nipa bi ẹgbẹẹgbẹrun ẹrọ ibanisọrọ kekeke ṣe gbina ni akoko kan naa ni Lebanon.
Ọgbẹni Hsu Ching-Kuang sọ pe ileeṣẹ oun fọwọ si iwe adehun pẹlu ileeṣẹ kan to ṣe ẹrọ ibanisọrọ naa ni Yuroopu, lati lo orukọ ileeṣẹ oun at ami idanimọ rẹ.
Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii ni awọn ọfiisi ileeṣẹ naa.
Ohun kan ti ko tii ye ẹnikẹni bayii, ni ibi ti ileeṣẹ Yuroopu ọhun ti wọn pe orukọ rẹ́ ni BC, wa ni pato.
Idi ni pe ileeṣẹ Gold Apollo sọ pe oun ko mọ ilu ti ileeṣẹ naa wa rara.
Ọgbẹni Ching-Kuang to ni ileeṣẹ Taiwan naa sọ pe ikọlu to waye ni Lebanon ti ṣe akoba fun ileeṣẹ oun.
Kini idi ti Hezbollah ṣe n lo Pagers dipo foonu?
Ikọ ajijagbara Hezbollah n lo imọ ẹrọ kekere naa fun ibanisọrọ nitori ki Israel ma baa le tọpinpin ibi ti wọn wa.
Ọjọ ti pẹ ti wọn ko ti lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ alagbeka, nitori pe o le gbabọde fun wọn, paapaa lati igba ti Israel ti pa ẹni to ma n ṣe ado oloro fun Hamas, Yahya Ayyash, nigba ti ẹrọ ibanisọrọ alagbeka gbina mọ lọwọ.
Emily Harding, oṣiṣẹ nigba kan fun ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ CIA, sọ pe idojuti nla gba a ni ikọlu to ba eto abo Hezbollah jẹ fun wọn.
Lowurọ Ọjọru, Akọwe ijọba America, Anthony Blinken, yoo gunlẹ si Egypt lati jiroro lori bi ogun yoo sẹ dawọ duro ni Gaza.












