Burkina Faso, Mali àti Niger, pawọ́pọ̀ ṣe ìwé ìrìnnà 'passport' jáde

Aworan awọn ologun AES Sahel

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Orilẹede mẹta to yapa kuro lara ajọ Iwọ oorun Afrika, ECOWAS, Burkina Faso, Mali ati Niger, ti kede pe awọn ti ṣe iwe irinna to jẹ tiwọn (Passport) jade.

Iwe irinna tuntun fun awọn orilẹede mẹta naa ni wọn ni yoo jade lai si ami kankan to ni i ṣe pẹlu ECOWAS tabi CEDEAO ninu rara.

Igbesẹ awọn orilẹede ta a tun mo si AES Sahel, n waye nigba ti ajọ ECOWAS ṣi n wa ọna ti wọn yoo fi da wọn pada sinu ajọ naa.

Ǹjẹ́ yóò rọrùn láti fi ìwé ìrìnnà Sahel wọ ilẹ̀ ECOWAS?

Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu BBC, Ọmọwe Moussa Abdullahi to jẹ onimọ nipa oṣelu lagbaye, sọ pe ko ṣoro rara fun awọn orilẹede mẹta yii lati rin irinajo laarin ara wọn.

Ọmọwe Moussa sọ pe ṣugbọn o ṣee ṣe ki iṣoro diẹ fẹẹ wa nibẹrẹ lati wọ awọn ilẹ ECOWAS.

"Mi o ro pe o yẹ ki iṣoro kankan wa, niṣe lo yẹ kawọn orilẹede tọrọ yii kan yanju wahala aarin wọn, ki iwe irinna ti wọn fẹẹ ṣe yii ma baa pa ẹnikan kan wọn lara.

‘’Ti wọn ba gbọ ara wọn ye, awọn eeyan AES Sahel ati ECOWAS yoo maa wọle-jade sinu ara wọn lai si wahala kankan niluu mejeeji.

" Bi awọn orilẹede ECOWAS ba le fi iwe irinna tiwọn wọ Sahel lai ni iwe ti a mọ si Fisa, awọn naa le wọ ilẹ ECOWAS pẹlu iwe irinna wọn." Bẹẹ ni Ọmọwe Musa ṣalaye.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Ninu oṣu Kinni, ọdun 2024, ni Niger, Mali ati Burkina Faso yapa kuro lara ECOWAS.

O pẹ ti awọn orilẹede mẹta yii ti maa n ya ara wọn sọtọ, ti wọn ki i fẹẹ ba awọn orilẹede Africa mii ṣe titi kan Naijiria.

Lẹyin eyi ni wọn kede pe awọn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ ECOWAS mọ, bi wọn ṣe fofin de wọn latari iditẹgbajọba to waye nibẹ.

Awijare awọn Sahel ni pe ECOWAS gbọdọ tẹti si awọn ibeere tawọn n beere, ki wọn si mu wọn ṣẹ, bi wọn ba fẹ kawọn pada sinu ẹgbẹ Iwọ-Oorun Africa naa.

ECOWAS fi awọn ofin kan de wọn, nitori bi wọn ṣe ditẹ mọ ijọba awaarawa lawọn orilẹede yii, ti ologun si n dari bayii.

Ṣugbọn o, awọn alẹnulọrọ kan ti n sọ pe ki ECOWAS gbesẹ kuro lori ofin to fi de awọn Sahel naa.