Sheik L'Agbaji sọ̀rọ̀ lórí fídíò òun àti Wòólì Genesis tó fa awuyewuye lórí ayélujára
Laipẹ yii ni ẹnu kun gbajugba Alfa ẹsin Islam kan, Al Sheik Hamad Labeeb L’Agbaji, ti ọpọ mọ si Sheik Labuaji.
Eyi ko ṣẹyin fidio kan to jade sori ayelujara, to ṣafihan bi olori ẹlẹsin Islam ọhun ṣe wa lori itage kan naa pẹlu gbajugbaja alufa ijọ Genesis, Wooli Oladele Ogundipe Genesis.
Ninu fidio naa lati ri Sheik Labuaji ati Wooli Gensis ti wọn jọ n jo loju agbo tẹrin-tọyaya.
Bakan naa la ri to da bi ẹni pe Wooli Genesis fi nnkankan si apo Alfa naa.
Ọpọ awọn to n sọrọ nipa fidio naa lori ayelujara lo gbagbọ pe ko lẹtọọ fun Sheik naa lati wa ni ipejọpọ kan naa pẹlu ẹlẹsin mii.

Oríṣun àwòrán, BBC/Others
Amọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC Yoruba lori ọrọ naa, Sheik L’Agbaji sọ pe ọkan ṣoṣo ni Ọlọrun ọba, nitori naa ẹnikẹni o le reti pe ki oun ati Genesis pade ara, ki awọn si maa ya aṣọ mọ ara wọn lara.
O ni lara ibi ti agbọye ẹsin ti bẹrẹ ni ki eeyan fi “dẹrẹ ẹgbẹ fun gbogbo ẹda ti Ọlọrun ba da.
“Ẹni ti ko ba ni oye iru nnkan bẹẹ, yoo maa ṣe bii aja digbolugi pe oun ko fẹ ri ẹlẹsin kan.
Nipa ti fidio to fa awuyewuye ọhun, Sheik Labuaji ṣalaye pe kii ṣe ṣọọṣi Oluṣọagutan Genesis ni oun lọ.
O ni ode ariya kan to waye lasiko awẹ ni awọn ti pade.
‘Nigba ti a de ibẹ, Genesis lo n sọrọ lọwọ. Nigba to si kan mi, o wa a pọn mi le.
‘Ṣe ẹni to pọn mi le, a wa a da ki n kan an l’abuku bi?
Sheik L’Agbaji sọ pe wọn o kọ oun lẹkọọ lati ma a ta ọfa gbolohun si ẹni to pọn oun le bẹẹ.
Tako nnkan ti awọn eeyan n sọ pe awọn ojiṣẹ Ọlọrun mejeeji jọ waasu papọ, tabi pe Alfa naa jọsin pẹlu awọn ẹlẹsin Kristiẹni, Sheik Labaji ṣalaye pe ọrọ ko ri bẹẹ.
O ni oun kan ti oun sọ ni pe “awọn ẹni Ọlọrun lo ma n ṣe bi Wooli Oladele Genesis ṣe ṣe.
‘Awọn ọrọ to sọ n da wa pada si ipilẹ, paapaa nipa asiko to gbe ninu igbe aye oṣi ati aini.’
O ni lara awọn nnkan ti awọn eeyan tun ṣi oun gbọ le lori ni pe oun sọ pe Ọlọrun da awọn Kristiẹni mọ ninu Kuraani.
“Nnkan ti mo fẹ sọ ni pe Ọlọrun darukọ awọn Krsitiẹni ninu Kuraani.
‘Eyi to tumọ si pe a le jọ ṣe oriṣiriṣi nnkan papọ, yatọ si didarapọ mọ ẹsin wọn.’
O ni oun le lọ si ṣọọṣi lati waasu, nitori naa ẹnikẹni ko le sọ pe ki oun doju ija kọ Genesis.
Aigbọra ẹni ye nipa ọrọ ẹsin ko jẹ tuntun ni orilẹ-ede Naijiria. Eyi si ti fa rogbodiyan ni aimọye igba, to si ṣaba maa n mu ẹmi ati dukia lọ.



