Kí ló ṣokùnfà ikú Dele Gold? Ohun tí a mọ̀ rèé

Aworan Dele Gold

Oríṣun àwòrán, Dele Gold/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọpọ eeyan kaakiri Naijiria lo n kọminu lori ohun to le ṣokunfa iku olorin ẹmi Dele Agbeyo ti ọpọ mọ si Dele Gold, lati igba ti iroyin iku rẹ ti jade.

Ti ẹ o ba gbagbe, arun jẹjẹrẹ oju ara ni a gbọ pe o ṣekupa gbajugbaja akọrin ẹmi mii, eyun un ni, Aduke Ajayi ti ọpọ mọ si Aduke to dagbeje faye ni nnkan bi oṣu kan sẹyin.

Ṣugbọn nipa ohun to ṣokunfa iku Dele Gold, ko si ẹni to le sọ pato bayii irufẹ aisan to mu ẹmi olori ẹmi naa lọ.

Ohun ti a gbọ naa ni pe Dele Gold fi aye silẹ lẹyin to ṣe aisan ranpẹ.

Àwọn nǹkan méje tó yẹ kí o mọ̀ nípa Dele Gold, olórin ẹ̀mí tó jáde láyé

Dele Gold

Oríṣun àwòrán, Dele Gold

Ọpọ eeyan kaakiri Naijiria lo ti bẹrẹ si n ṣedaro olorin ẹmi Dele Agbeyo ti ọpọ mọ si Dele Gold, to jade laye.

Akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ orin, Titi Oguntoyinbo, lo fi ikede ipapoda rẹ sita lori ayelujara.

Wayi o, bi awọn kan ṣe mọ Dele Gold si olorin ẹmi lawọn mii mọ ọ si olorin Juju.

Iroyin iku olorin naa lo n mi igboro titi lẹyin oṣu kan ti iroyin iku olorin ẹmi mii, Aduke Ajayi, ti ọpọ mọ si Aduke Gold, jade laye.

Amọ tani Dele Gold gan? Nibo ni wọn bi si, ati pe bawo lo ṣe bẹrẹ iṣe orin kikọ?

Eyi lawọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa oloogbe naa

Ilu Usi, nipinlẹ Ekiti ni wọn bi Dele si, o si dagba niluu Faforiji, to wa nipinlẹ Osun.

Oun ni alaṣẹ ati oludari ileeṣẹ Prodel Music, to jẹ ileeṣẹ to n gbe orin jade, oun tun ni aburo oloju aanu to tun jẹ alaṣẹ ileeṣẹ Cornfield Group of Companies, iyẹn Tope Agbey.

O sọ ninu ifọrọwerọ kan ṣaaju iku rẹ pe oju ala ni oun ti gba ẹbun orin kikọ bo tilẹ jẹ pe oun ko fẹ kọ orun tẹlẹ.

Dele bẹrẹ orin kikọ labẹ itọni agba ọjẹ olorin juju, Ebenezer Obey lọpọ ọdun sẹyin.

Lọdun 2019, oun ati Baba Ebenezer Obey gbe orin kan jade ti wọn pe ni “Hearty Blessings” orin naa si mi gbogbo ilu titi.

Yatọ so orin ọhun, awọn orin mii ti Dele kọ to tun milẹ titi ni “Divine Warning, Every Knee, Infinite God,” ati “A Thousand Tongues.”

Yatọ si baba Ebenezer Obey, awọn olorin mii ti Dele tun ti ṣiṣẹ pẹlu ni Sir Shina Peters, Lanre Teriba (Atorise), ati Abel Dosunmu (Mega 99).

Akọrin ẹ̀mí Dele Gold jáde láyé, Alayo Melody, Kujore àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ míì ń ṣe ìdárò

Aworan Dele Gold

Oríṣun àwòrán, Dele Gold/Instagram

Akọrin ẹmi Dele Agbeyo ti ọpọ mọ si Dele Gold ti jade laye.

Ni Ọjọru l'awọn akẹgbẹ rẹ kede pe Dele Gold to jẹ ọmọbibi Usi Ekiti nipinlẹ Ekiti ku lẹyin aisan ranpẹ.

Awọn akọrin ẹmi ti wọn jẹ akẹgbẹ rẹ bii Titi Oguntoyinbo, Akinlabi Mayor, Alayo Melody Singer ati Wonder Doyin Kujore ti n ṣedaro rẹ loju opo itakun ayelujara wọn.

Oguntoyinbo sọ loju opo Facebook rẹ pe "Oluwa, iṣẹlẹ yii bami lọkan jẹ o, hmmm."

Ni tirẹ, Akinlabi Major sọ pe "mo fẹ ki ẹnikan sọ fun mi pe irọ ni iṣẹlẹ yii.

Sun re o Dele Gold."

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Alayo Melody Singer sọrọ loju opo Instagram rẹ bayii pe "Dele Gold kẹ?

Ahh, eleyii ti n pọju o!

Ki Eledua ba wa dawọ iku aitọjọ bayii duro o.

Dele Agbeyo, maa sinmi laya Olugbala."

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Doyin Kujore naa sọrọ loju opo Facebook rẹ, o ni "ko si nkan kan ninu aye yii, ẹ ṣa jẹ ki a maa gbe ile aye bi eni ti ko ni dọla.

O maa n bami ninu jẹ lati maa sọrọ nipa iku awọn eeyan to ku iku aitọjọ.

Maa sun laya Olugbala, Dele Agbotikuyo, Dele Gold."

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Ọpọ lo maa n ranti orin ti Dele kọ papọ pẹlu agbaọjẹ olorin Juju, Chief Ebenezer Obey lọdun 2019.

Dele Gold jade laye lẹyin oṣu kan ti akọrin ẹmi miran, Aduke Gold ku.