Tinubu tún ti ṣàlàyé ànfàní tó wà fún aráàlú nínú àyọkúrò ‘subsidy’ orí epo bẹntiróòlù

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe ijọba oun fopin si owo iranwọ ori epo lọdun 2023 lati ṣi aye silẹ fun owo ti ijọba yoo fi ṣe awọn iṣẹ akanṣe fun idagbasoke ilu.

Aarẹ lo sọ ọrọ naa lọjọ Iṣẹgun nibi ipade awọn oṣiṣẹ ile ifowopamọ kan, CIBN, to waye niluu Abuja.

Tinubu sọ pe, “lootọ ni yoo nira ni ibẹrẹ, amọ a yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro lati le ṣi ọna silẹ lati lo owo naa fun idagbasoke ilu.”

Igbakeji Tinubu, Kashim Shettima lo ṣoju fun nibi ipade ọhun.

Nigba to n sọrọ nipa awọn iṣoro ti araalu yoo dojukọ lasiko yii, o mẹnuba ọwọngogo ounjẹ, airiṣẹ ṣe atawọn nnkan mii latari igbesẹ ijọba naa.

Amọ o ni awọn iṣoro ọhun yoo pese anfani fun idagbasoke lọjọ iwaju ni.

O ni “ohun ti a n jiroro le lori lonii yoo fun wa lanfani lati wo ibi ti a de gẹgẹ bii orilẹede, ki a mọ ipinlẹṣẹ iṣoro wa ki a si wa ọna abayọ si awọn iṣoro naa.

“A ti gbe igbesẹ akinkanju lati mu idagbasoke ba awọn olokoowo kekeke, afojusun wa ni lati mu ki araalu ni igbagbọ ninu eto ọrọ aje wa.”

Aarẹ tun sọ siwaju si pe ijọba oun ti ṣetan lati kọ awọn ohun amayedẹrun faraalu.

O ni “a ti ṣetan lati ṣe igbeleke awọn ohun amayedẹrun aarin ilu fun idagbasoke ọrọ aje.

“A n na ọpọ owo lori awọn nnkan bii opopona to dara, ọna oju irin, awọn ohun amuṣagbara ati ibaṣepọ laarin ijọba atawọn ileeṣẹ aladani lati le di iye owo ọkọ ku laarin ilu.

Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2023 ni Tinubu fopin si afikun owo ori epo bẹntiro, loni, N1,000 ni jala epo bẹntiro kan ni Naijria.