Èèyàn 37 ló pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé ní Maiduguri- NEMA

Aworan iṣẹlẹ omiyale nipinlẹ Maiduguri
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA ti kede sita pe o le ni eeyan mẹtadinlogoji to ti padanu ẹmi wọn lasiko ẹkun omi to waye ni daamu kan to fa omiyale nipinlẹ Borno.

Lasiko to n ba BBC sọrọ, Hajiya Zubaida Umar ni o seese ki afikun de ba iye awọn eeyan naa sugbọn awọn osisẹ ajọ naa n gbiyanju lati yọ awọn eeyan to ha lasiko omiyale naa.

Hajiya Zubaida tun ṣalape pe o le ni eeyan 400,000 to padanu ile wọn lasiko ajalu naa.

Ẹkun omi daamu Alau lo ṣokunfa iṣẹlẹ omiyale naa.

“Wahala wa nitori omi ti gba ilu Maiduguri, ẹ ko le ri eeyan kankan nitori wọn ti sa kuro ni ile wọn.”

O ni omi ti gba ida ogoji gbogbo agbegbe ilu Maiduguri

Hajiya Zubaida ni titi wọ aṣiko yii, ọpọ awọn eeyan lo si wa labẹ omi, ti wọn ko ri anfani lati doola wọn.

“Nibayii, awọn oṣiṣẹ ajọ ni awọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye n rọ awọn eeyan lati jade sita, ti qwọn si n doola wọn kuro ni bi ti wọn ha si

Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Umar Zulum ni o le ni eeyan milọnu kan ti iṣẹlẹ ṣe akoba fun.

A ti pese ile wosan to n lọ kiri awọn agbegbe yii

Aworan awọn oṣiṣẹ NEMA

Oríṣun àwòrán, Zubaida Umar/X

NEMA ni awọn ti da ibudo mẹjọ silẹ fun awọn eeyan ti wọn padanu ile wọn kaakiri ipinlẹ naa,

Ounjẹ, ọkọ oju omi ni wọn ti ṣeto silẹ fun awọn araalu.

Ni afikun, NEMA ni awọn ti pese ọkọm ti yoo magbve omi kiri fun awọn araalu, eyi ti ko ni jẹ ki wọn lugbadi aarun.

Hajiya Zubaida ni ajọ NEMA ti pese oogun lilo fun awọn araalu ti wọn si n gbe iwosan kiri.

Omiyale ba ọpọ ile pataki jẹ

Aworan awọn agbegbe ti omiyale ti waye

Oríṣun àwòrán, Alhaji Adamu

Hajiya Zubiada ni iṣẹlẹ Omiyale naa ba ọpọ dukia jẹ bi ilen iwosan ipinlẹ Maiduguri, ọgba ẹranko ati ọgba ẹwọn.

Bakan naa lo dupẹ lọwọ ijọpa apapọ, ẹka eto ilera, ijọba ipinlẹ Borno ati ajọ eleto ilera agbaye fun pipese iranlọwọ fun awọn araalu.

Gomina Zulum ni otitọ ni pe ijọba apapọ ti fi bilọnu mẹta ranṣẹ si ipinlẹ naa, eyi to ni wọn yoo fi pese iranlọwọ fun awọn araalu.

O fikun pe ijọba yoo gbe igbimọ kalẹ lati bẹrẹ iwadii lori bi awọn araalu ko se ni lugbadi aarun nitori iṣẹlẹ naa.

Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó wó dáàmù lulẹ́ ní Maiduguri sọ aráàlú di aláìnílélórí, lé àwọn ẹranko inú ọgbà síta

Aworan iṣẹlẹ Omiyale

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọ awọn eeyan to n gbe ni ipinlẹ Maidguri ni wọn ni lati saa kuro ni ile wọn, ti wọn si ni lati wa ile mi sun si lẹyin ti omigun daamu ti Alau ya nitori ojo to rọ ni agbegbe naa.

Omi daamu naa lo wa ni kilomita ogun siluu Maiduguri, to jẹ olu ilu ipinlẹ Borno, ni o sadede ya lulẹ lẹyin ti ojo nla kan rọ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe omiyale naa waye, to si gba gbogbo ilu, oju opopona, ile ẹkọ ati ile iwosan.

Awọn agbegbe bii Adamkolo, Fori, Galtimari, Gwange ati Bulabitin ni iṣẹlẹ omiyale naa se akoba fun.

Bakan naa ni iṣẹlẹ omiyale naa tun ṣe akoba fun awọn ẹranko, paapa awọn ẹranko inu igbo, ti wọn si n rin kiri ilu, eyi to n fa ẹru fun ọpọ araalu.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Kọmisọna fun iroyin, Usman Tar ti kesi awọn araalu lọjọ Isẹgun, to si rọ wọn pe ki wọn da bo bo ara wọn, ki wọn si kuro ni agbegbe ti omiyale ti waye.

“Pẹlu bi omiyale naa se waye lọdun yii, a n rọ awọn araalu to n gbe ni agbegbe yii pe ki wọn gbe igbesẹ ni kiakia lati da bobo dukia ati ẹmi wọnl.”

Lati bi ọgbọn ọdun, iṣẹlẹ yii ni eyi to lagbara ju to waye ni omi daamu Alau, ti ijọba si ni lati ti ile ẹkọ pa.

Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum ti buwọlu aṣẹ pe ki gbogbo ile ẹkọ wa ni titi pa, ati ile ẹkọ ijọba ati aladani fun ọsẹ meji nitori iṣẹlẹ naa omiyale.

Ninu atẹjade kan ti ẹka eto ẹkọ nipinlẹ naa gbe sita ni oun pato to sokunfa iṣẹlẹ naa ni ijamba to waye si omi daamu Alau.

Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti ransẹ ibanikẹdun si awọn olugbe ipinlẹ naa.

Aarẹ fi da awọn eeyan ipinlẹ naa ati gomina ipinlẹ naa, Zulum pe ijọba apapọ setan lati fọwọsowọpọ pẹlu wọn lati wa ojutu si iṣẹlẹ omiyale naa

O wa pada lasẹ fun ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, NEMA pe ki wọn pese ohun iranwọ fun awọn eeyan to lugbadi iṣẹlẹ naa.

“Aarẹ Tinubu ba ijọba ati awọn eeyan ipinlẹ Borno kẹdun paapa awọn mọlẹbi to padanu ọpọ nnkan nitori iṣẹlẹ omiyale” Bayo Onanuga ṣalaye

“Bi awọn omimọ se wadi ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa, Aarẹ palasẹ pe ki wọn gbe awọn eeyan kuro ni agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.”

Oludari ẹka Nema, Zubaida Umar ni iṣẹ ti bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ lati gbe awọn eeyan kuro ni agbegbe naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Awọn ẹranko to ṣa kuro ni ibudo ẹranko Zoo

Aworan iṣẹlẹ omiyale

Oríṣun àwòrán, NEMA/X

Awọn oṣiṣẹ ibudo ẹranko nipinlẹ naa ni awọn ẹranko kan ti saa kuro ni ahamọ ti wọn lẹyin ti iṣẹlẹ omiyale naa waye.

Fọnran awọn ẹranko naa ni agbegbe awọn eeyan lo ti lu sita lori ayelujara.

Ali Donbest to n se amojuto ibudo ẹranko, sọ fun BBC pe oun ko mọ iye awọn ẹranko to wa nita bayii sugbọn igbiyanju n lọ lọwọ lati ṣawari awọn ẹranko naa.

Bakan naa lo ni oun ko le sọ boya ahamọ awọn kininu ati ikoko si wa ni titi pa.

Olugbe Maiduguri, Ishaq Sani sọ fun BBC pe oun to n ba oun lẹru bayii ni ki oun ṣalabapade awọn ẹranko yii

Sani, ẹni to ti fi ile rẹ silẹ nitori iṣẹlẹ omiyale naa, to si n lọ gbe pẹlu ọrẹ rẹ

Iroyin to wa lọwọ bayii ni pe ko ti si ikọlu ẹranko kankan.