Jíjẹ Ìmáàmù Ààfin Ogbomoso kò mú ìjà dání, ẹ̀tọ́ tí ìdílé Ayilara ń bèèrè fún ni - Sheikh Habeeb Ayilara

Àkọlé fídíò, Imaamu Agba Ogbomoso
Jíjẹ Ìmáàmù Ààfin Ogbomoso kò mú ìjà dání, ẹ̀tọ́ tí ìdílé Ayilara ń bèèrè fún ni - Sheikh Habeeb Ayilara

Imaamu aafin Soun Ogbomoso tuntun, Sheikh Habeeb Adekunle Ayilara ti sọ pe ọrọ jijẹ imaamu ni aafin ko mu awuyewuye kankan dani.

O ni Kabiyesi Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandi Afolabi Olaoye sọ foun pe oun yoo maa ṣoju ori ade naa lawọn ipẹjọ kọọkan.

Sheikh Ayilara ni eyi tumọ si pe oun yoo maa ṣoju kabiyesi fun ẹsin musulumi ati fun ilu Ogbomoso.

Imaamu Ayilara ni ẹtọ idile Ayilara ti wọn ti n beere fun ni Soun Ọba Ghandi Afolabi Olaoye ṣe fun wọn.

‘’Ẹbi Ayilara lo maa n fẹnuko lori ẹni ti yoo ba jẹ imaamu niluu Ogbomoso silẹ.

Ọpọ eeyan mii lo wa nilẹ tawọn naa le jẹ imaamu ninu ẹbi Ayilara ki ẹbi to yan mi ti kabiyesi si fontẹ lu u.

Aṣoju ni mo jẹ fun idile Ayilara ati aafin Ogbomoso, ati pe n ko ni fi ẹsin musulumi ati ilu ti mo n ṣoju ba ẹsin kristẹni ati awọn oniṣẹṣe jẹ.

Emi naa wa n gbadura wi pe n ko ni doju ti ilu Ogbomoso ati ipinlẹ Oyo lapapọ.

''Imaamu aafin ni a yan, a o yan imaamu agba Ogbomoso''

Ẹwẹ, Aarẹ Ago ilẹ Ogbomoso, Oloye Samuel Otolorin sọ fun BBC Yoruba wi pe ‘’imaamu aafin ni a yan, a o yan imaamu agba Ogbomoso.

Ohun to jẹ ki a gbe igbesẹ yii ni pe imaamu to maa n ṣe adura tẹlẹ ni aafin, Sheikh Teliat Ayilara, ti pe Soun ilu Ogbomoso, Ọba Ghandhi Afolabi Olaoye lẹjọ.

Nigba ti ọrọ imaamu agba ilu Ogbomoso bẹrẹ, Soun Ọba Ghandi Afolabi ko ti de ipo nigba naa.

Emi ni mo n de ile lasiko naa, tori nigba ti wọn fi yan Sheikh Ayilara sipo imaamu agba Ogbomoso, Soun to waja to yan an sipo wa ni ẹni ọdun marundinlọgọrun nigba naa.

Ko pe oṣu kan ti baba yan an sipo tan ni wọn waja lọdun naa.

Iyẹn ni ko jẹ ki wọn le wa idi rẹ daada.

Lẹyin ti Kabiyesi Ọba Olaoye gori itẹ tan ni idile Ayilara ti wọn maa n jẹ imaamu Ogbomoso sọ fun Kabiyesi wi pe ki i ṣe ọmọ ile awọn.

Lẹyin naa ni kabiyesi sọ fun un wi pe ko lẹ yanju ọrọ naa pẹlu idile Ayilara ki o to maa ba iṣẹ rẹ lọ.

Iyẹn lo jẹ ko gbe baba atawọn oloye lọ ile ẹjọ.

Eyi gan an lo jẹ ki kabiyesi sọ fun un wi pe ko maa wa ṣe adura to maa n ṣe lọjọ Ẹti ni aafin mọ tori o ti gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ.’’

Aarẹ Ago ilu Ogbomoso ni kabiyesi atawọn oloye mọ ofin, idi niyii ti Soun fi yan imaamu fun aafin nikan.