Àwọn òbí akẹ́kọ̀ọ́ Kwara Poly táwọn afurasí ọlọ́pàá 'yìnbon pa' ń bèèrè ìdájọ́ òdodo, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Aworan Abdulqoyum Bamidele

Oríṣun àwòrán, Abdulkadir Abolarin Ibrahim/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ogbeni Abdulyekeen Muslim Ayinla ati iyawo rẹ Ramat Abdulyekeen ti wọn jẹ obi Abdulqoyum Bamidele, akẹkọọ ile ẹkọ gbogbonise Kwara Poly niluu Ilorin, ipinlẹ Kwara ti wọn ni afurasi ọlọpaa yinbon pa ti pe fun idajọ ododo lori iku ọmọ wọn.

Baba rẹ akẹkọọ to doloogbe yii, Ogbeni Abdulyekeen to kọkọ bawa sọrọ sọ wi pe ni ọjọ kẹrin osu yii ni oun gba ipe pajawiri wi pe ọmọ oun ni ijamba ọkọ, sugbon bi oun se de ile iwosan ni oun ri ọgbẹ ọwọ rẹ, oun si ri pe ibo ni wọn yin fun un.

"Abdulqoyum ni akọbi ọmọ mi, osu to n bọ lo ma pe ọmọ ọdun mọkanlelogun sugbọn wọn ko jẹ ko di igba naa."

Baba oloogbe naa sọ pe agbasẹse ina mọna-mọna loun, oun si mu ọmọ oun lọ ile ẹkọ lati ni imọ nipa isẹ naa sugbọn o ṣe pe aye da oun loro, wọn fina ọmọ jo oun.

Alaye ree lori bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye

Gẹgẹ bi awọn akẹkọọ to jẹ akẹgbẹ oloogbe naa ṣe sọ, "ni Ọjọru ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an yii ni awọn ọlọpaa kan to duro pẹlu ọkọ wọn lagbegbe Sango, niluu Ilorin da ọkọ ti akẹkọọ to ti di oloogbe bayii, Abdulqoyum, wa ninu rẹ duro.

"Wọn ni ko ṣọkalẹ ninu ọkọ to wa, wọn si mu oun ati awọn akẹgbẹ rẹ mii wọn inu ọkọ ti wọn.

Wọn gba foonu atawọn nnkan mii lọwọ wọn, lẹyin naa ni wọn n beere owo lọwọ wọn sugbọn Abdulqoyum sọ pe oun o lowo.

"O ṣa bọọlẹ ninu ọkọ awọn ọlọpaa ni wọn ba n le e lọ, bayii ni awọn ọlọpaa ṣe yin ibọn si i to si gba ibẹ ku.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ tiẹ, baba ọmọ ṣalaye pe awọn ọrẹ oloogbe naa sọ pe ohun ti yoo fi ṣe ayẹyẹ asekagba ikẹkọọgboye ND 2 rẹ ni o lọ ra, ki awọn ọlọpaa to da wọn duro lopopona Panat, laarin Sango si ShopRite, niluu Ilọrin ti wọn fi beere owo lọwọ wọn to si ni oun o lowo lọwọ.

"Wọn ni ibi ti o ti n saa lọ ni wọn ti yinbọn fun un lapa, ti wọn si fi awọn yoku rẹ silẹ, wọn si sa lọ.

Mo gbera lọ si agbegbe naa, awọn eeyan si ni lootọ lawọn gbọ iro ibọn.''

Baba Abdulqoyum ni o ṣee ṣe ki ọmọ oun ye, ṣugbọn ko tete ri oluranlọwọ, tori wọn lo to bi wakati meji ki alaanu kan to n kọja lọ to gbe e lọ ile iwosan.

''Igba to laju to le sọrọ lo fun wọn ni nọmba ibanisọrọ aburo mi.

"Ohun to fun mi ni aridaju pe awọn ọlọpaa lo pa a ni pe, ọmọ ti wọn jọ mu wọn papọ lo duro to si tun jẹri lagọ ọlọpaa pe ọlọpaa lo pa a.

"Koda awọn ẹbi ọlọpaa to sisẹ laabi yi ti wa laarọ oni lati wa bẹ mi, wọn o le wọ ile mi ki wahala ma baa sẹlẹ sugbọn ile Mogaji ni wọn pe mi si.

Sugbọn mo jẹ ko ye wọn pe ọrọ naa kii se temi sugbọn ti jọba ni nitori o kọja agbara mi.

Baba oloogbge naa ni oun ko le pari ile ti toun n gbe nitori awọn ọmọ oun, ki wọn ba le ni ẹkọ to ye kooro.

Amọ, o ni wọn pa ọmọ naa mo oun lọwọ, ṣugbọn oun ti fi gbogbo rẹ le Ọlọrun lọwọ.

''Idajọ ita gbangba ni mo fẹ lori iku ọmọ mi''

Aworan Baba oloogbe ati oloogbe

Ninu ọrọ tirẹ, mama oloogbe naa, Ramat Abdulyekeen sọ pe idajọ ita gbangba ni oun fẹ latọdọ ijọba ki wọn si ma ṣe ọrọ naa ni bonkẹlẹ.

"Ṣowo ile ẹkọ ni ka sọ ni, ọmọ ti mo n wo ti wọn si fi lami loju, idajọ ododo ni mo fẹ o, iya yi ko gbọdọ jẹ mi gbe,'' Ramat lo sọ bẹẹ.

Ohun ti Mogaji Alagbọn sọ

BBC News Yoruba tun kan si ile Mogaji Alagbọn, Alhaji Abubakir Garba, ẹni to fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn ẹbi ọlọpaa to yinbọn naa wa tọrọ aforiji lọwọ baba oloogbe ni aafin oun.

"Ni aarọ ọjọ Aje ni mo ri awọn kan ti wọn to bi mẹfa, wọn ni awọn ni ẹbi ọlọpaa to yinbọn fun Abdulqoyum, wọn ni awọn wa bawa kẹdun, gẹgẹ bii musulumi.

Ko si ohun ti a le se, sugbọn a rọ ijọba ki wọn ṣe idajọ ododo lori iṣẹlẹ naa," Mogaji lo sọ bẹẹ.

Kinni ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?

Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, IGP Kayode Adeolu Egbetokun, ti paṣẹ pe ki iwadii kikun waye lori ohun to ṣokunfa iku Qoyum Ishola Abdulyekeen.

Ọga ọlọpaa sọrọ yii ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi fi sita lana ọjọ Aje.

Ni bayii, awọn ọlọpaa tọrọ naa kan, Insipẹkitọ Abiodun Kayode, Insipẹkitọ James Emmanuel, and Sajẹnti Oni Philip, ti wa ni ahamọ ọlọpaa nigba ti iwadii n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọga ọlọpaa Egbetokun kẹdun pẹlu ẹbi, ọrẹ atawọn akẹgbẹ rẹ nile ẹkọ giga Kwara Poly lori iku Ishola.

O fi dawọn loju wi pe idajọ ododo yoo waye lori iṣẹlẹ naa.

Ṣaaju ni agbenusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, DSP Ejire Adeyemi Adetoun, naa ti sọ pe iwadii to peye si n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

DSP Adeyemi ni lotitọ gẹgẹ bi awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ti wi, ọwọ ọlọpaa wa ninu ọrọ naa nitori awọn lo da wọn duro, sugbọn ohun to sẹlẹ lẹhin ti wọn dawọn duro ni awọn ko tii le sọ.

O salaye pe "awọn o so ju mi koro lo sọ ọ pe oloopa lo da wọn duro, kii se pe awọn ọlọpaa naa jẹwọ pe awọn ṣe bẹẹ gẹgẹ.

"Sugbọn ju gbogbo rẹ lọ, a ti mu awọn ọlọpaa naa, wọn si ti wa latimọle nigbati iwadi n lọ lọwọ," DSP Adeyemi ṣalaye.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post