Wo àwọn èèyàn tó ṣeé ṣe kó rọ́pò Ajuri Ngelale gẹ́gẹ́ bíi agbẹnusọ Ààrẹ Tinubu

Aworan Sunday Dare, Ajuri Ngelale ati Bayo Onanuga

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ajuri Ngelale/Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bi ileeṣẹ Aarẹ se ti tẹwọgba iwe ifiṣẹsilẹ Ajuri Ngelale gẹgẹ bii agbẹnusọ aarẹ, mọ nipa awọn eeyan to ṣeese pe ki wọn rọpo rẹ.

Ni ana ni ọjọ kẹjọ oṣu kẹsan an ọdun 2024, ni Ngelale kede pe oun ti kan si adari awọn osiṣẹ nile iṣẹ aarẹ, Femi Gbajabiamila wi pe oun fẹ lọ isinmi lẹnu iṣẹ.

BBC se akojọpọ awọn eeyan to see se ko rọpo Ngelale.

Bayo Onanuga

Aworan Bayo Onanuga

Oríṣun àwòrán, Others

Bayo Onanuga lo jẹ oludamọran fun Aarẹ Bola Tinubu lori iroyin ati sise eto lọwọ bayii

Lasiko eto idibo, oun ni agbẹnusọ fun ipolongo ibo fun Tinubu/Shettima.

Agba akọroyin ni Onanuga jẹ lorilẹede Naijiria, o wa lara awọn to da ileeṣẹ iroyin The News Magazine silẹ, to si tun jẹ ọga agba tẹlẹri fun ileeṣẹ iroyin PM News .

Bakan naa ni, Onanuga, ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin jẹ olumojuto iroyin tẹlẹri ni ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria.

Ọpọ awọn to ma gbe sita lo ti wa loju opo ọpọ iwe iroyin lorilẹede Naijiria.

Sunday Dare

Aworan Sunday Dare

Oríṣun àwòrán, Facebook/.Sunday Dare

Sunday Dare jẹ minisita tẹlẹ fun ere idaraya ati awọn ọdọ labẹ iṣejọba Aarẹ tẹlẹ, Muhammadu Buhari.

Ko to gba iṣẹ minisita, o jẹ Kọmisana ni ẹka ijọba to n risi ibaraẹnisọrọ , NCC.

Agba akọroyin ni Sunday Dare, to siṣẹ pẹlu ọpọ ileeṣẹ iroyin to jẹ ti momaworan tabi redio, iwe iroyin ati bẹbẹ lọ fun o le ọdun mẹdọgbọn.

Sunday Dare ti ṣiṣe gẹgẹ oludamọran fun Aarẹ Tinubu lasiko to jẹ Gomina ipinlẹ Eko.

Ọpọ eeyan ni Dare ni o ṣee se ko bọ si ipo Ajuri nitori iwa irẹlẹ rẹ.

Daniel Bwala

Aworan Dokita Daniel Bwala

Oríṣun àwòrán, X/@BwalaDaniel

Daniel Bwala jẹ agbẹjọro ati agbẹnusọ tẹlẹ fun oludije fun ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar.

Saaju ninu ọdun yii ni Bwala gbe igbesẹ to ya ọpọ lẹnu nigba to kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lati sisẹ pọ pẹlu Aarẹ Bola Tinubu.

Bo ti lẹ jẹ pe Bwala se atilẹyin fun Aarẹ Tinubu lasiko eto idibo abẹle APC sugbọn o yọ atilẹyin rẹ nitori ọrọ to so mọ ẹlẹsin musulumi gẹgẹ bii aarẹ ati igbakeji aarẹ.

Ninu oṣu kinni ọdun 2024, Aarẹ Tinubu gbe Bwala ni alejo ni ile ijọba ninu Abuja, nibi to si ti kesi gbogbo araalu lati se atilẹyin fun ijọba to wa lode .

Bwala lo jẹ ẹlẹsin Kristi to wa lati ipinlẹ Kaduna.

Tinubu sọ̀rọ̀ lórí agbẹnusọ rẹ̀ Ajuri Ngelale tó fipò rẹ̀ sílẹ̀

Aworan Aarẹ Bola Tinubu ati Ajuri Ngelale

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale/X

Aarẹ Bola Tinubu ti gba igbesẹ oludamọran rẹ lori eto iroyin ati ilukoro, Ajuri Ngelale, lati gba isinmi alailọjọ lẹnu iṣẹ rẹ wọle.

Laarọ ọjọ Abamẹta ni Ngelale kede pe oun ti kan si adari awọn osiṣẹ nile iṣẹ aarẹ, Femi Gbajabiamila wi pe oun fẹ lọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Ohun ti Ngelale sọ ni pe ẹbi oun lo ni ipenija nipa eto ilera eyi to si nilo amojuto oun ni kiakia.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, ni irọlẹ ọjọ Abamẹta to lọ yii naa ni ileeṣẹ aarẹ fi idi rẹ mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede loju opo X rẹ pe Tinubu ti gba igbesẹ Ngalale lati ṣe gaaya fun iṣẹ gẹgẹ bi agbẹnusọ rẹ.

Ileeṣẹ aarẹ ninu atẹjade ọhun sọ pe ‘’Aarẹ Tinubu ti tẹwọ gba iwe ti Ngelale fi ranṣẹ lori igbesẹ rẹ lati gba isinmi alailọjọ gẹgẹ bi oludamọran aarẹ lori eto iroyin ati ilukoro.

Igbesẹ Ngelale ye aarẹ yeke yeke, bakan naa ni aarẹ kaanu Ngelale lori ipenija eto ilera to n koju ẹbi rẹ eyi to jẹ ko fi isẹ silẹ.’’

Ileeṣẹ aarẹ tun sọ ninu atẹjade naa wi pe Tinubu mọ riri iṣẹ takuntakun ti Ngelale ṣe lasiko to wa pẹlu aarẹ papaa julọ igbiyanju rẹ lori eto ayipada oju ọjọ atawọn nnkan mii to ti ṣe.

Bakan naa ni ileeṣẹ aarẹ tun sọ ninu atẹjade naa wi pe ki awọn eeyan ma yọ Ngelale lẹnu lasiko yii gẹgẹ bi o ṣe sọ ninu atẹjade to fi sita.

Tinubu ko ṣai gbadura fun Ngelale pe Eleduwa yoo fun ẹbi rẹ ni alaafia ati okun to peye.

Bi ẹ o ba gbagbe, Ngelale fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade to fi sita pe oun gbe igbesẹ yii lẹyin ijiroro pẹlu ẹbi oun.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Olùdámọ̀ràn ààrẹ Ajuri Ngelale ṣàlàyé ìdí tó fi gba ìsinmi aláìlọ́jọ́ tí yóò padà sẹ́nu iṣẹ́

Aworan Bola Tinubu ati Agbẹnusọ Ààrẹ Ajuri Ngelale

Oríṣun àwòrán, X/Ajuri Ngelale

Oludamọran aarẹ Bola Tinubu lori eto iroyin ati ilukoro, Ajuri Ngelale, ti kede wi pe oun ti gba ìsinmi alailọjọ lẹnu iṣẹ.

Ngelale sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Abamẹta wi pe oun gbe igbese yii lẹyin toun ti kọkọ ba ẹbi oun jiroro.

Oludamọran aarẹ ni igbesẹ yii da lori ọrọ to ni ṣe pẹlu eto ilera ẹbi oun eyi to n buru sii.

Ngelale ni oun ti fi igbesẹ oun yii to adari awọn oṣiṣẹ nile iṣẹ aarẹ, Femi Gbajabiamila leti.

Ngelale sọ pe oun ti fipo oun silẹ bakan naa gẹgẹ bi aṣoju aarẹ lori ayipada oju ọjọ ati gẹgẹ bi alaga lori eto gbingbin koriko ati igi.

"Ni ọjọ Ẹti ni mo kọwe si adari awọn oṣiṣẹ nile iṣẹ aarẹ pe mo ti bẹrẹ ìsinmi alailọjọ lẹnu iṣẹ lati le wa ojutuu si ipenija eto ilera to n koju ẹbi mi lọwọ yii.

Emi fun ra mi mọ pe igbesẹ yii ko ni le jẹ ki n tẹsiwaju ninu awọn ipo ti mo di mu, amọ, mo gbe igbesẹ naa nitori ẹbi mi ni.

Mo si ni ireti pe mo maa pada sẹnu iṣẹ mi nigba ti akoko ba to, ati nigba ti iwosan ba de ba ẹbi mi.

Mo n fi tọwọ tọwọ rọ awọn eeyan wi pe ki wọn ṣe gaaya fun emi ati ẹbi mi lasiko yii," Ngelale lo sọ bẹẹ.

Isinmi alailọjọ tumọ si pe Ngelale yoo fi iṣẹ rẹ sílẹ gẹgẹ bi agbẹnusọ aarẹ Tinubu fun igba diẹ

Aworan atẹjade Ajuri Ngelale

Oríṣun àwòrán, Facebook/ Ajuri Ngelale