Lẹ́yìn ìkìlọ̀ ìjọba pé òjò ńlá ń bọ̀, àádọ́ta ilé, èrè oko run sínú omíyalé

Oríṣun àwòrán, AFP
Kò dín ní ilé àti oko àádọ́ta tí omíyalé agbára ya ṣọ́ọ̀bù ti ṣe lọ́ṣẹ́ ní ìlú Bindigi, ìjọba ìbílẹ̀ Fune ní ìpínlẹ̀ Yobe.
Bákan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko ni àgbàrá òjò ọ̀hún tún wọ́ lọ.
Ní báyìí, ilé ẹ̀kọ́ àti àwọn ilé ìwòsàn tó wà ní agbègbè náà ni àwọn èèyàn tí omíyalé náà dààmú fi orí pamọ́ sí.
Àwọn èèyàn ìlú Bindigi wà nínú ìrora báyìí látàrí ìpalára tí omíyalé náà ti fà fún wọn.
Olùgbé ìlú náà tó bá BBC sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, Bulama Alhaji Audu ní omíyalé náà pọ̀ ju nǹkan tí àwọn lérò lọ.
Ó ní díẹ̀ ló kù kí agbára òjò náà jẹ gbogbo ìlú run nítorí gbogbo àwọn ilé alámọ̀ ni omíyalé náà dà wó lulẹ̀ àmọ́ tó ní ẹ̀mí kankan kò ba lọ.
Bulama Alhaji Audu ní ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko àwọn ló ti bá omi lọ, tó sì ní àwọn èèyàn ìlú náà kò sùn pẹ̀lú èrò pé omi tún le gbé àwọn lọ lóru.
Ó sọ pé àwọn èèyàn ìlú náà nílò ìrànlọ́wọ́ gidi ní kíákíá.
Ẹ̀wẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Yobe ní àwọn ti ń ṣiṣẹ́ láti pèsè ohun amáyédẹrùn fáwọn èèyàn ìlú náà àtàwọn ibòmíràn tí omíyalé ṣe lọ́ṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà.
Adarí àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Yobe, Dókítà Muhammad Goje ní àwọn ti gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé tó wáyé ní Bindigi àti àwọn agbègbè mìíràn.
Ó sọ pé gómìnà ti fún àwọn láṣẹ láti lọ sí àwọn ìlú tí omíyalé ti ṣọṣẹ́ láti mọ bí nǹkan ṣe ti bàjẹ́ tó níbẹ̀.
Ó ṣàlàyé síwájú si pé Bindigi wà lára àwọn ìlú tí àwọn máa pèsè ohun ìrànwọ́ fún ní ìjọba ìbílẹ̀ Fune nítorí ó wà lára ìlú mẹ́jọ tí àwọn ti rí pé wọ́n nílò rẹ̀.
Goje fi kun pé gbogbo àwọn tó ti ń ṣe àtìpó ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba àti ilé ìwòsàn ni àwọn máa pèsè ohun ìrànwọ́ fún láti dá ààbò bò wọ́n lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àìsàn.
Láti inú oṣù Kẹjọ ọdún ni òjò ńlá ti ń fa ẹ̀kúnwọ́ omi láwọn agbègbè kan ní Nàìjíríà, tó sì ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ di aláìnílé lórí mọ́.
Bákan náà ló tún ba àwọn èrè oko jẹ́.
Ṣáájú ni ìjọba àpapọ̀ ti ṣèkìlọ̀ pé òjò ńlá ọlọ́jọ́ márùn-ún máa rọ̀ tó sì máa fa omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ní àwọn agbègbè 123 ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún.
Lára àwọn ìpínlẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ ní omíyalé náà yóò ti wáyé ni Benue, Kogi, Anambra, Delta, Rivers, Imo àti Bayelsa.















