Ohun tí Tinubu sọ rèé lórí àfikún owó epo bẹntiróòlù tí NNPC ṣe

Oríṣun àwòrán, Ajuri Ngelale
Aarẹ Bola Tinubu ti sọrọ fun igba akọkọ lẹyin ti ajọ NNPC fikun owo bẹntiro ni Naijiria.
Nigba to n ba awọn ọmọ Naijiria to n gbe lorilẹede China sọrọ, Tinubu sọ pe afikun owo epo naa atawọn igbesẹ mii ti ijọba oun n gbe waye fun idagbasoke Naijiria.
O ni “lọwọ yii, Naijiria n la awọn atunṣe kan kọja, bẹẹ ni a n gbe awọn igbesẹ akin kan. Fun apẹrẹ, ẹ o ti maa gbọ lati ile lẹnu ọjọ mẹta yii nipa afikun owo epo.
“Bawo ni a ṣe fẹ de ebute ogo ti a ba kọ lati gbe awọn igbesẹ to le koko ti yoo la ọna fun wa?
“Niwọn igba ti awọn eeyan wa ba n fẹ nnkan ọfẹ, bẹẹ ni nnkan yoo maa wọn siwaju si, bẹẹ naa ni irinajo ati de ibi ti a n lọ yoo pẹ si.”
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun to kọja ni NNPC gbe owo epo lati N568 si N855 ni gbogbo awọn ile epo kaakiri Naijiria, eyii to mu ki awọn ile epo aladani gbe owo tiwọn si laarin N1,000 si N1,200.
Lẹyin ikede naa ni ọpọ araalu binu, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu ijọba Tinubu bo tilẹ jẹ pe ko si ni Naijiria lasiko ikede afikun owo epo naa.
Eyii ko ṣeyin bi ikede ọhun ṣe waye lasiko ti ara n ni ọpọ araalu, ti gbogbo nnkan si gbowo lori, ti wọn ko si tun ri epo ọhun ra pẹlu.
Amọ Tinubu ti sọ niluu Beijing pe igbesẹ akin ni afikun owo epo naa jẹ, o si ṣe pataki lati gbe irufẹ igbesẹ bẹẹ ti Naijiria ba fe de ebute ogo lọwọ iwaju.
O ni “ṣugbọn ki ni a fẹ ṣe? Ṣe a le ṣe ọna to dara bii iru eyii to wa nibi yii? Ina mọnamọna to duro dede, omi to mọ geere atawọn ile ẹkọ to dara.”
Tinubu pari ọrọ rẹ pe afojusun oun ni lati mu irufẹ idagbasike to wa ni China waye ni Naijiria.















