Ọmọ ìyá méjì tó díbọ́n bíi obìnrin, tó dúnkookò láti fi ìhòòhò ọmọ Amẹ́ríkà kan han lórí ayélujára, rí ẹ̀wọ̀n ọdùn17 he

Oríṣun àwòrán, EFCC/FACEBOOK
Ọmọ orilẹede Naijiria meji ti wọn jẹ ọmọ iya kana, Samuel ati Samson Ogoshi, ni wọn lu ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan ni jibiti pe, ko fi aworan ihooho ransẹ .
Adajọ ileẹjọ agbegbe lorilẹede Amẹrika Robert J. Jonker lo gbe idajọ naa kalẹ lẹyin ti ẹri fi idi rẹ mulẹ pe awọn ọdọmọkunrin meji naa jẹbi ẹsun naa.
Ileẹjọ ran awọn mejeeji lọ si ẹwọn ọdun mẹtadinlogun ati abọ ni ọgba ẹwọn ijọba.
Awọn ọmọ iya mejeeji naa lo tan ọdọmọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Jordan DeMay, pe ko fi aworan ihooho rẹ ransẹ, ti wọn si n dibọn gẹgẹ bii obinrin.
Wọn lu ọmọ naa ni jibiti, to si ṣekupa ara rẹ laarin wakati mẹfa ti wọn bẹrẹ si ma sọrọ lori ayelujara.
"Igbẹjọ akọkọ ree ti yoo gbe ọlọpaa Amẹrika wa sewadi awọn ọdaran ni Eko, ti wọn si gbe wọn lọ foju ba ile ẹjọ ni Amẹrika"
Jordan DeMey lo wa lati ile ẹkọ kan ni Michigan.
O gba ẹmi ara rẹ ni ọdun 2022 nigba ti awọn ọmọ iya meji Ogoshi bẹrẹ si ni ma dunkoko mọ.
Iya Jordan DeMay, Jenn Buta, di fọto ọmọ rẹ dani ni ile ẹjọ, to si n to omije loju.
O ni oun tẹwọgba idajọ naa sugbọn o ni ko da nnkan to ti bajẹ pada.
Samson ati Samuel Ogoshi pẹlu ọrẹ wọn mii, Ezekiel Robert ni wọn ka ẹsun mẹrin si lẹsẹ eyi to jẹ mọ lulu eeyan ni jibiti aworan ihooho ara.
Agbẹjọro Mark Totten lo bẹrẹ ẹjọ lori ọmọ orilẹede Naijiria mẹta ti wọn fi ẹsun kan pe wọn ti lu ọpọ ọdọmọkunrin ni jibiti bẹẹ ni agbegbe naa ati kaakiri orilẹede Amẹrika.
Ọkan lara awọn ọdọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Samuel Ogoshi, ni wọn fi ẹsun nla kan nitori ohun to ṣe lo sokunfa iku Jordan DeMay.
Ni ọjọ kẹdọgbọn, oṣu kẹta ọdun 2022 ni wọn ri oku ọmọ ọdun mẹtadinlogun naa lẹyin to yinbọn fun ara rẹ.
Ni oṣu kẹrin ọdun 2024, awọn ọmọ iya mejeeji naa jẹwọ pe awọn jẹbi fun ile ẹjọ ati pe awọn n hu iwa aidaa yii kaakiri orilẹede Amẹrika.
Awọn mejeeji tọrọ aforijin lọwọ awọn mọlẹbi oloogbe.
Samson Ogoshi sọ fun awọn mọlẹbi pe oun tọrọ aforijin “A gbe igbesẹ buburu lati wa owo, o wu mi pe ki n ni anfani lati yi isẹlẹ naa pada,”
Igbẹjọ akọkọ iru rẹ ree ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo ṣawari awọn ọdaran wa si ilu Eko, ti wọn si gbe wọn lọ lati foju ba ile ẹjọ.
Bawo ni wọn se ṣokunfa iku Jordan DeMay?

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn ọmọ iya mejeeji naa, Samuel Ogoshi, ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Samuel Ogoshi, ẹni ọdun mọkanlelogun, ni wọn fi ibeere ibanidọrẹ ransẹ si Jordan DeMay lori Instagram, ti wọn si n dibọn bi obinrin.
Bi wọn se gba aworan ihooho lọwọ oloogbe naa, ni wọn bẹrẹ si ma dunkoko mọ Jordan pe ko san ọpọ miliọnu dọla.
Wọn ni ti ko ba ṣe bẹẹ, awọn yoo fi aworan naa sita fun awọn ọrẹ rẹ.
Jordan fi gbogbo owo rẹ ransẹ, to si ki awọn ọmọ iya meji naa nilọ pe oun yoo ṣekupa ara oun ti wọn ba fi aworan naa sita.
Awọn ọmọ iya meji fesi pada pe “O dara bẹẹ, tete se ni kiakia tabi maa jẹ ki o ṣe .
John DeMay sọ fun ile ẹjọ Marguette ni Michigansay pe, o da bi ala ni, nigba ti oun ri oku ọmọ oun ninu yara rẹ.
O ni awọn mọlẹbi oun ni lati kuro ni ile naa lati le fi gbagbe ohun to sẹlẹ.
Irufẹ iṣẹlẹlilu jibiti lori ayelujara to ti waye ri, ti ọmọ Naijiria lọwọ ninu rẹ

Oríṣun àwòrán, NSW Police
Awọn agbofinro ati oniwadii ti tọka si orilẹede Naijiria gẹgẹ ibudo awọn ọdaran yii.
Ninu oṣu kẹrin, wọn mu ọmọ orilẹede meji lẹyin akẹkọọ lati Australia ṣekupa ara rẹ.
Awọn mejeeji tun jẹjọ nipinlẹ Eko lẹyin ti ọmọ ọdun mẹdogun kan ṣekupa ara rẹ ni US ati ọmọ ọdun mẹrinla mii ni Canada.
Awọn ọlọpaa orilẹede Naijiria siṣẹ papọ pẹlu awọn ọlọpaaScotland lati ṣe iwadii iku ọmọ ọdun mẹrindinlogun Murray Dowey, to ṣekupa ara rẹ ninu oṣu kejila ọdun 2023.
Amoye nipa eto abo ayelujara, Adedeji Oyenuga lati fasiti ipinlẹ Eko ni oun lero pe bi wọn ran awọn orilẹede Naijiria yii lọ sẹwọn yoo ṣe ẹru ba ọpọ ọdaran yoo pe le ki wọn fopin si.
Awọn nnkan to yẹ ki o ṣe to ba wa ninu ipo yii pẹlu awọn ọdaran onijibiti
Amọran yii wa lati ẹnu Jenn Buta ati ọpọ awọn agbofinro nipa awọn ọdaran to n fi aworan ihooho lu awọn eeyan ni jibiti.
- Ranti pe o ko da wa, eyi ki si n se ẹjọ rẹ
- Fi ẹjọ akanti wọn sun lori opo ayelujara
- Yọ wọn kuro loju opo rẹ lati ma lee ni anfani lati ba ẹ sọrọ
- Ri pe o mọ orukọ oju opo wọn, eyi yoo se iranlọwọ fun awọn agbofinro
- Kan si agbalagba to fi inu tan tabi awọn agbofinro ko to di pe o fi owo ranṣẹ tabi aworan mii.
Awọn nnkan to le se, ko maa ba lugbadi iṣẹlẹ jibiti ori ayelujara
- Ma buwọlu eeyan ti o ko mọ lati di ọrẹ rẹ lori ayelujara
- Sọra fun ọrẹ ori ayelujara
- Ma fi fọnran aworan ihooho rẹ sori foonu rẹ
- Ma gbe ipe fidio lati ọdọ eeyan ti o ko mọ lori opo ayelujara.
- Ma pin aworan tabi fido ihooho rẹ ka loru opo ayelujara















