Ìjàmbá iná míì tún wáyé nílé ẹ̀kọ́, akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta farapa

Aworan ile ẹko Isiolo Girls Highs School

Oríṣun àwòrán, Isiolo Girls Highs School

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Akẹkọọ mẹta ni wọn ti farapa lẹyin ti ina ṣẹyọ ni ile ẹkọ awọn obinrin to wa ni aarin gbogbo Isiolo orilẹede Kenya.

Iṣẹlẹ yii lo waye lẹyin ti o le ni akẹkọọ mọkanlelogun padanu ẹmi wọn nibi ijamba ina to waye ni ile ẹkọ kan ni Nyeri ni dede ago mọkanla alẹ lọjọbọ ọsẹ to kọja.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ina naa ba ọpọ dukia jẹ ko to di pe wọn pa ina ọhun.

Ohun to ṣokunfa ijamba ina ni ko ti di mimọ sugbọn ọpọ ijamba ina lo ti waye ni awọn ile ẹkọ lorilẹede Kenya, to si ti n ke pe akiyesi awọn ijọba lori abo awọn akẹkọọ.

Awọn ikọ pupọ Red Cross ni awọn ọmọde mẹta to farapa yii ni wọn ti wa ni ile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju.

Awọn ọlọpaa ati awọn ẹsọ alabo mii ni wọn tu sita lati ma wa awọn akẹkọọ, ti wọn si tun gbiyanju lati doola awọn dukia.

Ìjọba fẹ́ ṣe àyẹ̀wò DNA fún ìdánimọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kú nínú ìjàm̀bá iná tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀

Awọn obi to n wa ọmọ wọn

Oríṣun àwòrán, EPA

Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè Kenya ti ní àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àyẹ̀wò DNA fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí sínú ìjàm̀bá iná tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ kan lórílẹ̀ èdè náà.

Ìgbésẹ̀ náà ni wọ́n ní yóò jẹ́ kí àwọn mọ òkú ẹni tó jẹ́ gan.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlélógún, tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́sàn-án, ni wọ́n jóná kọjá mímọ̀.

Nnkan bíi aago mọ̀kánlà alẹ́ ọjọ́bọ̀ ni ìjàm̀bá iná náà wáyé níbi ilé ìgbé àwọn ọkùnrin tí iye wọn tó 156 ní ilé ẹ̀kọ́ Hillside Endarasha Academy. Àwọn panápaná kò tètè ríbi débi ìṣẹ̀lẹ̀ iná náà àmọ́ àwọn èèyàn tó ń gbé ní agbègbè náà sáré ṣe ìrànwọ́ tí wọ́n lè ṣe.

Àwọn aláṣẹ ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tàdínlógún ni àwọn kò lè sọ ibi tí wọ́n wà báyìí - táwọn òbí àti ẹbí sì ń bèèrè fún àwọn ọmọ wọn.

Ìjọba ti ké pe àwọn tó ṣe ìrànwọ́ láti dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kí wọ́n dá wọn padà sí ilé ẹ̀kọ́ kí wọ́n lè mọ àwọn tó kù tí wọ́n ń wá.

Àjọ Red Cross ti nawọ́ ìrànwọ́ láti wá àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Ohun tó ṣokùnfà iná náà ni ẹnikẹ́ni kò ì tíì mọ̀ títí di àsìkò yìí.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ olùpẹjọ́ ìjọba ní kí àwọn tó ń ṣe ìwádìí ṣàwárí ohun tó fa ìjàm̀bá iná náà.

Adarí olùpẹjọ́ fún ìjọba, Renson Ingonga ní ìjàm̀bá iná náà mú kí àwọn ènìyàn rántí àwọn tó ti wáyé sẹ́yìn.

Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ìjàm̀bá náà ló wáyé látàrí pé wọn kò tẹ̀lé òfin àti ìlànà fún pípèsè ààbò bó ṣe tọ́.

Agbẹnusọ ìjọba, Isaac Mwaura sọ pé ìjàm̀bá náà kọjá ohun tí èèyàn le rò rárá.

Ó ní ohun ìbànújẹ́ ńlá ni pé orílẹ̀ èdè náà ń pàdánù àwọn ọmọdé tó jẹ́ ògo àti ọjọ́ iwájú orílẹ̀ èdè náà.

Mwaura rọ àwọn akọ̀ròyìn láti dènà kíkéde iye kan bíi àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí àyẹ̀wò DNA máa gba ọjọ́ díẹ̀.

Igbákejì ààrẹ Kenya, Rigathi Gachagua lásìkò tó ṣe àbẹ̀wò sílé ẹ̀kọ́ náà

Oríṣun àwòrán, EPA

Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn olùwádìí àtàwọn onímọ̀ ìlera ìjọba ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa fún àyẹ̀wò.

Ààrẹ William Ruto ti kéde ọjọ́ mẹ́ta láti fi dárò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ́ nìyí tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá iná ń wáyé ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ ní Kenya léyìí tó ń mú àwọn èèyàn kọminú lórí bí àwọn ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe ń tẹ̀lé ètò ààbò tí ìjọba fi lélẹ̀.

Ní ọdún 2022, ẹ̀ka ilé ìgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ní ẹkùn ìwọ oòrùn Kenya jóná, tí wọ́n sì fòfin gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan pé àwọn ló mọ̀ọ́mọ̀ sọ iná sínú ilé náà.

Ní ọdún 2017 ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́wàá pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá iná ní ilé ẹ̀kọ́ Moi Girls High School ní olú ìlú orílẹ̀ èdè náà, Nairobi.

Ìjábọ̀ kan lọ́dún mẹ́rin sẹ́yìn ṣèkìlọ̀ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama ní Kenya ni kò mọ nǹkan tó tọ́ láti ṣe bí ìjàm̀bá iná bá bẹ́ sílẹ̀.

Bákan náà ni ìjábọ̀ kan ní ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ni kò ní ohun èlò láti kojú ìjàm̀bá iná tó bá ṣẹlẹ̀ àti pé ọ̀pọ̀ wọn ni kò tẹ̀lé ìlànà ààbò tó tọ́.

Ọmọdé tó lé ní mẹ́tàdínlógún kú nínú ìjàmbá iná tó wáyé nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀

Ileẹkọ ti ijamba ina ti waye

Oríṣun àwòrán, Facebook

kere tan, ọmọde mẹtadinlogun lo ti dagbere faye nile ẹk kan to wa ni ẹkun arin gbugbun orilẹede Kenya lọjọbọ.

Ohun to se okunfa iku awọn ọmọde yii ni ijamba ina kan to waye ninu ọgba ileẹkọ alakọbẹrẹ Hillside Endarash ni ẹkun Nyeri.

O si seese ko jẹ pe iye awọn ọmọde ti yoo ba isẹlẹ naa lọ tun pọ si nitori o le ni dọsini kan akẹkọọ to jona kọja sisọ, ti wọn ti gbe lọ sile iwosan.

Agbẹnusọ fun ileesẹ Ọlọpa, Resila Onyango sọ fawọn akọroyin pe awọn si n se iwadii lọwọ lori ohun to fa ijamba ina naa.

Ọkọ Panapana

Isẹlẹ ina yii jẹ eyi to ba ni lẹru, ti ko wu oju ri, to si ba ni lọkan jẹ - Aarẹ William Ruto tilẹ Kenya

Aarẹ William Ruto tilẹ Kenya ti wa se apejuwe isẹlẹ naa bii “eyi to ba ni lẹru, ti ko wu oju ri, to si ba ni lọkan jẹ”.

“Gbogbo awọn eeyan to ba wa nidi isẹlẹ yii ni yoo fi imu ko ata ofin.”

Nibayii, ileesẹ ọlọpaa ni ikọ awọn oluwadii ni wọn ti ko lọ sile ẹkọ naa.

Bakan naa, ajọ Red Cross nilẹ Kenya ti salaye pe oun n pese atilẹyin fawọn akẹkọọ, Olukọ ati awọn ẹbi ti ijamba ina naa ba.

Isẹlẹ ijamba ina saba maa n waye lorilẹede Kenya.