Kí ló fà á tí ìkookò ṣe ń jí àwọn ọmọdé, ṣekúpa wọ́n ní India?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Soutik Biswas
- Role, India correspondent
- Author, Saiyed Moziz Imam
- Role, BBC Hindi, Bahraich
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Sandhya, ọmọ ọdun mẹrin n sun ni ita ni agbegbe Uttar Pradesh ni India ni alẹ ọjọ kẹtadinlogun Oṣu Kẹjọ nigba ti wọn mu ina mọnamọna lọ ti gbogbo abule sì wa ninu okunkun.
"Awọn ikoko sekolu laarin iṣẹju meji ti wọn mu ina mọnamọna lọ. Ni akoko ti a mọ ohun ti n ṣẹlẹ, wọn ti gbe e lọ," iya rẹ, Sunita, ranti.
Wọn ri oku Sandhya nilẹ ninu oko ireke kan ni ọjọ keji ni bi kìilomita si ile rẹ
Ṣaaju ninu oṣu yẹn, ni abule kan ta wa ni tosi ilu naa, ọmọ ọdun mẹjọ Utkarsh n sun labẹ nẹẹti ẹ̀fọn nigba ti iya rẹ ri bi ikooko kan se n wọ inu ahere wọn.
"Ẹranko naa ṣafẹri lati ojiji. Mo kigbe, 'Fi ọmọ mi silẹ nikan!' Awọn aladugbo mi sare jade, Ikooko naa si salọ, ”o sọ.
Lati aarin Oṣu Kẹrin, awọn ikọlu Ikooko ti di bẹruboju ni ayika awọn abule 30 ni agbegbe Bahraich, nitosi aala Nepal.
Awon omode mesan an ati agbalagba kan ni awọn ikooko ti gbe lọ ti won si pa.
Ọmọ ọdun kan nilo kere ju ninu wọn, eyi to dagba ju jẹ obinrin ẹni ọdun marunlelogoji. O kere ju eeyan 34 miiran ti farapa.

Oríṣun àwòrán, ANI
Ibẹru ati ijaya ti de ba awọn eeyan abule naa. Pẹlu ọpọlọpọ ile ni abule naa ko se ki n si ni titiipa, awọn ọmọde wa ninu ile, ti awọn ọkunrin n ṣọ awọn opopona ti o ṣokunkun ni alẹ.
Awọn alaṣẹ ti gbe awọn kamẹra ranṣẹ, ṣeto awọn ẹgẹ ati lo awọn ina lati dẹruba awọn ikooko naa.
Titi di isisiyi, awọn ikooko mẹta ni wọn ti mu ti wọn si ti gbe lọ si awọn ọgba ẹranko.
Ikọlu ikooko si eeyan ṣọwọn gan-an.
Iwadii kan nipasẹ Ile-ẹkọ Norwegian fun Iwadi Iseda ti Ilu Norway royin awọn ikọlu Ikooko ni awọn orilẹ-ede 21 - pẹlu India - laarin ọdun 2002 ati 2020.
Isele 26 ninu wọn ni buru gan an. O fẹrẹ to awọn eeyan 380 to fara kasa ikọlu naa.”.
Kilode ti awọn ikooko se n kọlu eeyan ni Bahraich?
Ti o wa laarin odo kan ati awọn igbo, awọn apakan ti Bahraich ti jẹ ibugbe Ikooko fun igba pipẹ.
Ti o wa ni ibi iṣan omi ti odo Ghaghara, agbegbe, ile si awọn eeyan miliọnu 3.5, jẹ itara si iṣan omiyale.
Ojo nla to n rọ ati ẹkun omi lakooko kan ti se akoba nla. Odo Ghaghara yawọ awọn igbo, eyi to le awọn ikooko jade lati wa ounjẹ ati omi
“Iyipada oju-ọjọ jẹ ilana to n tẹsiwaju.
Ṣugbọn omiyale le ja si awọn idalọwọduro ibugbe fun awọn ikooko, ti o fi ipa mu wọn sinu ibugbe eeyan lati wa ounjẹ,”
Amita Kanaujia ti Institute of Sciences Wildlife ni University Lucknow sọ.
Ki ni idi ti awọn ọmọde jẹ ohun ti awọn ikooko n wa fun ounjẹ?


Lakoko iwadii sinu ipaniyan nipa awọn ọmọde ni ikọlu Ikooko ti mu lọ ọrun ni abule Uttar Pradesh ni ọdun 1996, awọn amoye ẹranko rii pe abojuto kekere wa lo fun awọn ọmọde nitori ọpọlọpọ awọn olufaragba wa lati awọn idile talaka ti o ni obi kanṣoṣo, ti iya maa n dari.
Ni awọn abule India wọnyi, awọn ẹran-ọsin nigbagbogbo ni aabo to dara julọ ju awọn ọmọde lọ.
Nigbati Ikooko ti ebi npa, ko ba ri nnkan ọsin jẹ, awọn ọmọde lo ṣeese ko ma kọlu.
“Ko si ibomiran ni agbaye ti a ti rii awọn ikọlu Ikooko lori awọn ọmọde,” Yadvendradev Jhala, onimọ-jinlẹ ara ilu India ati onimọ-itọju, sọ fun BBC.
Awọn ikọlu Ikooko lọwọlọwọ ni Uttar Pradesh ni o ṣee ṣe ko jẹ ti yoo waye.
Ni ọdun 1981-82, ikọlu Ikooko ni Bihar gba ẹmi awọn ọmọde 13 o kere ju. Laarin 1993 ati 1995, awọn ọmọde 80 miiran ni a kolu.
Iṣẹlẹ ti o le julọ waye fun o le ni oṣu mẹjọ ni ọdun 1996, nigbati o kere ju awọn ọmọde 76 lati awọn abule 50 ni Uttar Pradesh ti kọlu, ti o fa iku 38.
Awọn ipaniyan duro lẹyin ti awọn alaṣẹ ti pa awọn ikooko 11.
















