Ara ń ni ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà torí ọ̀wọ́n epo, ibí yìí sì ni mo ná owó sí jùlọ fétò ìdàgbàsókè - Bill Gates gbarata

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bill Gates, ọkan lara Oludasilẹ Bill and Melinda Gates Foundation ti kede pe orilẹede Naijiria ni ajọ naa na owo ju fun ni ilẹ Afrika.
Gates, ẹni to jẹ ọkan lara eeyan to lowo julọ lagbaye, sọ eyi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja.
Gẹgẹ bii Gates ṣe ṣalaye, ajọ oun n se iranlọwọ lagbaye lati tako awọn aisan bii igbona, iba ati aarun rọpa rọsẹ.
"A na ọpọ owo ni Asia sugbọn orilẹede tí a na ọpọ owo si julọ ni ilẹ Afrika, paapaa orilẹede Naijiria.
"Eyi waye nitori ọpọ ero wa nibẹ ati pe orilẹede naa nilo iranlọwọ.
"Eyi tumọ si pe mo ti na ọpọ bilọnu ni Naijiria.
"Inu mi dun pe ọpọ ohun aburu ti wa silẹ sugbọn a sì le se ju bẹẹ lọ."
"Maa si na ọpọ owo seto ọgbin eyi ti yoo tako ọwọn gogo ounjẹ"
Gates tẹsiwaju pe ajọ rẹ tun gbero lati na ọpọ owo ni ọjọ iwaju lati se iranlọwọ fun eto ìlera.
"Iṣẹ wa lo da lori eto ìlera abẹle nitori o ṣe koko."
O tun fikun pepe yatọ si eto ilera, ajọ naa tun na ọpọ owo si ẹtọ ọgbin lati fi se alekun ohun ọgbin tí yoo se anfani fun eto ọrọ aje lorilẹede Naijiria.
O ni erongba on lati na ọpọ owo sinu eto ogbin eyi ti yoo tako ọwọn gogo ounjẹ.
Ajọ Bill and Melinda Gates Foundation ni wọn da silẹ lọdun 2000 lati fi pese iranlọwọ fun awọn orilẹede Afrika.
"Owo ori ti araalu n san kere jọjọ, ko si ilọsiwaju fun eto ọrọ aje Naijiria"
Bill Gates tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe lati ibi ọdun mẹẹdogun si asiko yii, ilọsiwaju kankan ko de ba eto ọrọ aje orilẹede Naijiria.
Gates gba ìjọba apapọ ni imọran pe ko tubọ na owo si eto ilera lati ra ọrọ aje pada.
O ṣalaye pe o ṣe koko ki ijọbai wa ojutu si bi yoo se se igbelarugẹ awọn araalu bi o ṣe n igbiyanju lati gbe ogun ti kudiẹkudiẹ eto ọrọ aje.
Gates ni ọpọ ìṣòro lo n ba Naijiria ja sugbọn ijọba gbọdọ gbajumọ ìlera awọn araalu.
"Eto ọrọ aje ko lọ siwaju. Ni Ibẹrẹ ọdun yii gbese pọ ju ida aadọta lati ọdun 2001.
"O tun walẹ ju bo se wa ni ọdun mẹdogun sẹyin.
"Mo mọ nípa bi eto oṣelu ṣe ri orilẹede Naijiria.
Ara n ni awọn ọmọ Naijiria, ọwọngogo gbode, ti awon araalu si n fi ẹhonu han sita.
"Owo ori sísan ni Naijiria kere jọjọ sugbọn awọn araalu ma san owo ori ti wọn ba ri pe ijọba n na owo naa fun igbe aye to rọnu.
"Mo mọ pe gbogbo ọrọ, lai si owo, ofo ni, nítori ẹ ní mo fi gba ìjọba ni imọran lati na owo si bi to yẹ "















