Ṣé lóòtọ́ọ́ ní ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ń palẹ̀mọ́ láti ṣe ìwọ́de tako ìjọba Tinubu?

Oríṣun àwòrán, NANs
Ni irọlẹ Ọjọru ni awuyewuye kan gbode pe apapọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ yika orilẹede Naijiria (NANs) ti n palẹ ogun mọ lati doju kọ isejọba aarẹ Bola Tinubu.
Iroyin naa to gba ọpọ oju opo ayelujara kan lo sọ pe NANs fẹ se iwọde lati fi ẹhonu wọn han lori ele to gun jala epo bẹntiro kan si N897.
Iroyin naa ni ẹgbẹ awọn akẹkọọ naa lo kọju oro si igbesẹ ijọba naa, to si ni oun yoo ba ijọba Tinubu na tan bii owo, titi ti yoo fi ja owo epo naa walẹ.
Amọ iwadi BBC Yoruba ti fihan pe irọ to jinna si ootọ ni ahesọ ọrọ naa.
Bakan naa, apapọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria ti ke wa si gbogbo araalu pe ko si nnkan to jọ mọ pe awọn n gbero lati se ifehonuhan kaakiri orilẹede Naijiria.
"Agbofinro, ẹ bẹrẹ iwadii lati mọ orísun iroyin ofege yii tori o yẹ ki ofin fiya jẹ awọn eeyan to gbe iroyin naa sita"
Atẹjade kan ti ẹgbẹ akẹkọọ naa fi lede fun awọn akọroyin, eyi ti Aarẹ ẹgbẹ naa, Akinteye Afeez Babatunde buwọlu lo sisọ loju ọrọ yii.
Babatunde ṣalaye pe ẹgbẹ NANS ko lọwọ ninu ifehonuhan tabi buwọlu ìwọde kankan eyi ti ko ba ofin ati ilana ẹgbẹ naa mu.
Gẹgẹ bii ẹgbẹ awọn akẹkọọ, Babatunde ni ẹgbẹ naa mọ nipa inira ti awọn araalu n la kọja lọwọ yii sugbọn oniranṣẹ alaafia ni ẹgbẹ NANS jẹ.
"Igbesẹ ti wọn ma gbe eyi ti yoo da rogbodiyan silẹ, a ko ni ba wọn da si.
"A rọ awọn araalu, awọn akọroyin pe ki wọn yẹra fun irufẹ iroyin naa nitori awọn eeyan to wa nidi iroyin ofege yii fẹ ba orukọ ẹgbẹ wa jẹ ní fun anfani tí wọn.
Bakan naa ni Aarẹ ẹgbẹ naa tun kesi awọn agbofinro lorilẹede Naijiria pe ki wọn bẹrẹ iwadii lati ṣawari orísun ibi ti iroyin ofege naa ti jade nitori o ṣe koko ki ofin fiya jẹ irufẹ awọn eeyan bẹ.
"Lilo orúkọ ẹgbẹ NANS lati fi gbe iroyin yii sita lewu pupọ to si n ba orukọ ọpọ akẹkọọ to n wa ilọsiwaju orilẹede Naijiria jẹ.
"A n rọ gbogbo awọn agbofinro pe ki wọn gbe igbesẹ lati sawari awọn eeyan naa."
Babatunde ni oun ti NANS gbajumọ ni igbeaye gbadun awọn akẹkọọ lorilẹede Naijiria.
"A o tẹsiwaju lati ma pe fun ẹtọ awọn akẹkọọ ni ilana to ba ofin ni ọna alaafia.
"O se koko ki gbogbo araalu mọ pe alaafia, idagbasoke ati isọkan ni ẹgbẹ NANS duro fun."















