Ìgbà mẹ́jọ ọ̀tọ̀tọ̀ tí ìjọba fi owó gọbọi lé jálá epo bẹntiró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni bayii ti ijoba Naijiria ti gbe owo epo bẹntiro si ₦897, o n tumọ si pe owo epo ti lọ soke ni ida 460% lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2023 ti Aarẹ Bola Tinubu ti gori aleefa.
Afikun yii ni igba ọgbọn ti ijọba Naijiria yoo fikun owo epo lati ọdun mọkanlelaadọta sẹyin ti ọgagun Yakubu Gowon kọkọ fi owo kun owo epo lọdun 1973 lati 6 kobo si 8.45 kobo.
Alekun owo lita epo bẹntirolu ti ọtẹ yii si lo n waye laarin wakati mẹfa ti ileesẹ elepo eroja epo rọbi ti Dangote kede pe oun ti bẹrẹ ipese epo bẹntirolu.
Iwọnyii ni igba mẹjọ ti ijọba fi owo to ga gọbọi le owo epo bẹntiro ni Naijiria
- Shonekan (1993): 70k si N5 (614.29%)
- Abacha (1994): N3.25k si N15 (361.54%)
- Tinubu (2023) : N195 si N557 (282.74%)
- Tinubu (2024): N617 si N897 (145.38%)
- Abubakar I (1998): N11 si N25 (127.27%)
- Buhari (2020): N87 si N195 (124%)
- Jonathan (2012): N65 si N141 (116.92%)
- Tinubu (2023) : N557 si N617 (110.77%)
Wo apapọ iye igba ti ijọba fi owo kun owo epo ni Naiijiria
- Gowon (1973): 6k si 8.45k (40.83%)
- Murtala (1976): 8.45k si 9k (6.5%)
- Obasanjo (1978): 9k si 15.3k (70%)
- Shagari (1982): 15.3k si 20k (30.72%)
- Babangida I (1986): 20k si 39.5k (97.5%)
- Babangida II (1988): 39.5k si 42k (6.33%)
- Babangida III (1989): 42k si 60k (42.86%)
- Babangida IV (1991): 60k si 70k (16.67%)
- Shonekan (1993): 70k si N5 (614.29%)
- Abacha I (1993): N5 si N3.25k (epo walẹ ni ida 35%)
- Abacha II (1994): N3.25k si N15 (361.54%)
- Abacha III (1994): N15 si N11 (epo walẹ ni ida 26.67%)
- Abubakar I (1998): N11 si N25 (127.27%)
- Abubakar II (1999): N25 si N20 (epo walẹ ni ida 25%)
- Obasanjo I (2000): N20 si N30 (50%)
- Obasanjo II (2000): N30 si N22 (epo walẹ ni ida 26.67%)
- Obasanjo III (2002): N22 si N26 (18.18%)
- Obasanjo IV (2003): N26 si N42 (61.54%)
- Obasanjo V (2004): N42 tsi N50 (19.05%)
- Obasanjo VI (2004): N50 si N65 (30%)
- Obasanjo VII (2007): N65 si N75 (15.39%)
- Yar’ Adua (2007): N75 si N65 (epo walẹ ni ida 15.39%)
- Jonathan I (2012): N65 si N141 (116.92%)
- Jonathan II (2012): N141 si N97 (epo walẹ ni ida 31.21%)
- Jonathan III (2015): N97 si N87 (epo walẹ ni ida 10.31%)
- Buhari (2016): N87 si N145 (66.67%)
- Buhari’s term (2020): N87 si N195 (124%)
- Tinubu (2023) : N195 si N557 (282.74%)
- Tinubu (2023) : N557 si N617 (110.77%)
- Tinubu (2024): N617 si N897 (145.38%)
Ni ọpọ igba ni alekun owo epo yii maa n fa awuyewuye laarin ijọba, araalu, ẹgbẹ osisẹ, ẹlẹgbẹjẹgbẹ atawọn ẹgbẹ agbasaga ni ẹya ati ẹkun kọọkan.
Bi ọpọ ọmọ Naijiria se wa n fi apa janu lori alekun owo epo naa, ireti wa pe ijọba yoo wa ọna lati bu ororo itura si ibi ti bata ti n ta awọn araalu lẹsẹ lori igbesẹ naa.
Ireti si wa pe isẹlẹ naa ko ni fa rogbodiyan ati iwọde gẹgẹ bo se waye lasiko isejọba Goodluck Jonathan lọdun 2012.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fọnmú lórí àlékún owó epo, ó kéde kókó ìgbésẹ̀ méje tó ní kí Tinubu gbọdọ̀ gbé kíakía

Oríṣun àwòrán, Daily Post Nigeria
Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naiiria, NLC, ti fesi lori alekun owo jala epo bẹntiro ti ajọ NNPCL kede ni ana ọjọ Isẹgun eyi to n fa awuyewuye yika Naijiria.
NLC sọ pe afikun tuntun ti ijọba ṣe si owo epo yii yoo tunbọ mu aye nira fun araalu ni.
O wa ke si ijọba apapọ pe ko da owo jala epo bẹntiro pada si iye to wa tẹlẹ.
Ana ode yii ni NNPC gbe owo jala epo bẹntiro soke lati ₦568 si ₦855 ati ₦897 bo tilẹ jẹ pe nnkan ti le koko tẹlẹ faraalu.
"Tinubu, da owo jala epo bẹntiro pada si iye to wa tẹlẹ, ko si tu awọn oluwọde to wa nigbekun silẹ"
Nigba to n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ afikun owo epo tuntun naa, Aarẹ NLC, Joe Ajaero sọ igbesẹ marun to fẹ ki ijọba Tinubu gbe ni kiakia.
- Ajaero ni ijọba apapọ ti dalẹ awọn oṣiṣẹ lori adehun owo osu to kere julọ tii se aadọrin naira
- Ajaero ni ijọba gbọdọ da owo epo bẹntiro pada si iye to wa tẹlẹ kaakiri Naijiria tori alekun owo epo ko jẹ itẹwọgba awọn osisẹ lasiko yii.
- Bakan naa, ijọba Tinubu gbọdọ tu awọn to fi si ahamọ nitori pe wọn ṣe iwọde ilu le silẹ ni kiakia.
- A tun fẹ ki ijọba fopin si bo ṣe n fi ṣikun ofin mu araalu lori awọn ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ
- Ijọba tun gbọdọ wọgile afikun 250% owo ina mọnamọna, ko si dẹkun ati maa gba iṣẹ ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ ṣe.
- Ko tan sibẹ, NLC tun beere pe ki ijọba Naijiria “fopin si awọn igbesẹ to n fa ebi ọpagba laarin ilu ati eyii to n mu ki eto abo dẹnukọlẹ siwaju si.
- NLC sọ pe ijọba Naijiria ni lati fopin iwa iṣẹrubani ati irọ pipa to n hu.
"Ọdalẹ ni ijọba Tinubu, a fun ni ni fila, gba odidi ori lọwọ ẹni ni"
Gẹgẹ bi nnkan ti Aarẹ NLC naa sọ, ijọba to wa lode ko tii bẹrẹ si n san afikun owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ amọ o ti bẹrẹ si n gba owo naa pada pẹlu afikun owo epo bẹntiro.
Ajaero sọ pe ijọba ọdalẹ ni ijọba Tinubu bẹẹ ni ko si ootọ kankan lẹnu rẹ.
O ni Aarẹ fun ẹgbẹ oṣiṣẹ lanfani lati yan laarin ki wọn maa gba ₦250,000 owo oṣu to kere julọ ki wọn si maa ra jala epo kan ni ₦1,500 tabi ki awọn gba ₦70,000 owo oṣu to kere julọ ki ijọba ma si ṣafikun owo epo, amọ nitori inira ti yoo mu ba araalu, awọn yan lati gba ₦70,000.
Ajaero ni laarin nnkan bii oṣu kan pere ti ko tii bẹrẹ iṣe lori owo oṣu tuntun naa, o ti fikun owo epo.
Lẹyin naa lo juwe ijọba Aarẹ Bola Tinubu bii ọdalẹ, to si fikun pe ọpalamba iya ni yoo jẹ araalu ti ijọba ko ba yi igbesẹ afikun owo epo tuntun ọhun pada ni kiakia.
NNPC kéde àfikún owó lítà epo bẹntiró

Ileesẹ to n ri si katakara epo rọbi labẹ ajọ to n se akoso epo rọbi nilẹ wa, NNPC, ti kede pe alekun ti ba owo lita epo bẹntiro kan.
Atẹjade kan ti ajọ NNPC fisita ni owurọ ọjọ Isẹgun, ọjọ Kẹta osu Kẹsan ọdun 2024, ti fidi rẹ mulẹ pe owo lita epo bẹntirolu kan ti di N897.
A ranti pe ajọ NNPC lo n ta lita epo bẹntol lawọn ile epo rẹ gbogbo yika orilẹede yii ni N580.
Saaju ni ọwọn gogo epo bẹntirol ti wa yika Naijiria, ti ọpọ alagbata epo si n ta lita epo kan kọja ẹgbẹrun kan Naira.
BBC Yoruba rin yika awọn ileepo to wa yika ilẹ yii, ti a si ri awọn ileepo NNPC ti wọn ti yi owo lita epo bẹntirol kan si N897 fun liter kan
NNPC kede alekun owo lita epo bẹntiro lẹyin wakati mẹfa ti ileesẹ elepo rọbi Dangote bẹrẹ ipese epo bẹntiro
O si seese ki alekun ba iye ti awọn alagbata epo kọkan yoo maa ta lita epo bẹntirolu bayii kja iye owo ti ajọ NNPC kede rẹ.
Ni Ibadan, Osogbo ati Eko, abẹwo BBC Yoruba fihan pe ọpọ awn alagbata epo lo ti yi owo lita epo bẹntirolu si N950 lọ si N1000.
Gẹgẹ bi alasẹ ileesẹ elepo rbi naa, Aliko Dangote ti sọ lasiko to n se afihan epo bẹntiro ti ileesẹ rẹ n se jade, o ni ileesẹ oun ti setan lati pese miliọnu mẹẹdọgbọn epo bẹntirol sita ninu osu yii
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe alekun yoo ba ipese epo bẹntirol naa si ọgbọn miliọnu lita ninu osu kẹwa to n bọ.

NNPC ni oun ko ni owo lati ko epo bẹntiro wọle mọ lati oke okun
Ajọ elepo rọbi nilẹ wa, NNPC lo ti kede saaju pe ọda owo n da oun, ti oun ko si lagbara mọ lati maa ko epo rọbi wọle si Naijiria mọ fun tita.
Ọjọ Aje ana ni adari ajọ NNPC, Mele Kyari, kede bẹẹ ninu alaye to se lori idi ti ọwọngogo epo bẹntirolu se n waye.
“Ajọ NNPC n koju ọda owo lasiko yii, oun nikan si lo n da gbọ bukata gbigbe epo bẹntiro wọ orilẹede yii.
Bakan naa, NNPC lo n ru ẹru owo iranwọ lori epo bẹntiro eyi to le ni aimọye trilinu naira.
A jẹ awọn alagbata epo ni owo to to $6.8bn eyi to n se okunfa aifararọ to n waye ni ẹka epo rọbi.
Obitibiti gbese ti a jẹ sọrun yii lo si ti gbe ẹru nla ka ori ajọ naa nidi kiko epo bẹntriolu wọ Naijiria wa lati oke okun.”
Awọn alagbata epo bẹntiro, lasiko ti wọn n sọ ero wọn lori ọwọn gogo epo to gbode si ti salaye pe ọwọn epo naa yoo maa tẹsiwaju.
















