Kò sí ìfaǹfà láàárín Tinubu àti Shettima - Iléeṣẹ́ ààrẹ

Oríṣun àwòrán, PRESIDENCY
Iléeṣẹ́ ààrẹ ti ní kò sí ìfaǹfà tàbí gbọ́misi omi ò to láàrin ààrẹ Bola Ahmed Tinubu àti igbékejì rẹ̀, Kashim Shettima bí àwọn kan ṣe ń gbe kiri.
Wọ́n ní àjọṣepọ̀ tó wà láàárín àwọn adarí méjéèjì náà dúró ire, tó sì dán mọ́rán láì sí wàhálà kankan láàárín wọn.
Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí igbákejì ààrẹ, Stanley Nkwocha ló fi ọ̀rọ̀ náà léde nínú àtẹ̀jáde kan tó fi ń kí Shettima kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún méjìdínlọ́gọ́ta.
Nkwocha ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni àhesọ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń gbé kiri àti pé kò bá nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní ilé ìjọba lọ rárá.
Ó tẹmpẹlẹmọ pé Shettima ṣe pàtàkì sí ìjọba Tinubu àti pé ó máa ń ṣe àtìlẹyìn tó péye fún-un.

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/FACEBOOK
Agbẹnusọ Shettima nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé àwọn àtìlẹyìn àti ìfarajìn tó ń ṣe fún Tinubu, tó sì ní ìṣọ̀kan tó ń wà láàárín wà lára nǹkan tó ń mú ìtẹ̀síwájú bá ìṣèjọba tó wà lọde.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìlera Shettima, ó ní digbí lára ọ̀gá òun wà, pé irọ́ ni àwọn èèyàn ń gbé kiri.
Láti bíi ọjọ́ mélòó kan ni àwọn èèyàn ti ń gbé ìròyìn kiri pé ààrin Tinubu àti igbákejì kò dán mọ́rán kódà kí ìṣèjọba wọn tó pé ọdún kan lórí ipò.
Ó ti fẹ́ di àṣà ní Nàìjíríà, kí ìfaǹfà máa wáyé láàárín ààrẹ àti igbákejì rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá dórí ipò tán.
Èyí tó fojú hàn jùlọ lẹ́yìn tí Nàìjíríà padà sí ètò ìṣèjọba àwaarawa ni ti ìgbà ààrẹ Olusegun Obasanjo àti igbákejì rẹ̀, Atiku Abubakar lásìkò tí wọ́n ṣèjọba láàárín ọdún 1999 sí 2007.















