Ọ̀kùnrin ló ní Orò, Orò ìdílé nìkan ni obìnrin le è ṣe, tó bá ṣe Orò tó ń kùn, èwu wà fun - Elebuibon

Oríṣun àwòrán, Oloro
Lẹyin ti iroyin gbode jade pe obinrin kan pe Oro ti oro naa si dahun lawọn eeyan ti bẹrẹ si n woye pe ṣe lootọ ni.
Igbagbọ ọpọ eeyan nilẹ Yoruba ni pe Oro kii ṣe ohun ti obinrin n foju ri tabi kopa ninu rẹ.
Ọpọ ọmọ Yoruba lo gbagbọ pe obinrin to ba foju kan Oro tabi kopa ninu Oro ṣiṣe, yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Amọ ṣe bẹẹ lọrọ ọhun ri?
Idi ree ti BBC Yoruba fi kan si Araba Awo ilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon, ti oun funra rẹ jẹ agba ọjẹ ninu iṣẹṣe, lati tan imọlẹ si ọrọ naa.
Oniruru Oro lo wa
Baba Ifayemi sọ pe obinrin kii lọ sidi Oro, iṣẹ awọn ọkunrin ni, amọ oniruru Oro lo wa.
O ni “nnkan ti a n pe ni Oro, Oro idile wa, gbogbo etutu ti a n sẹ ni iṣẹdalẹ, Oro naa ni.
“Ṣugbọn oro kan wa lọtọ ti obinrin kii ri, ti obinri kii ṣe.
“Amọ awọn nnkan bii etutu ati ikomọ, Oro naa la n pe... o ṣeeṣe ko jẹ Oro idile obinrin yẹn lo ṣe.”
Oro ti obinrin ko gbọdọ lọwọ ninu rẹ
Baba Ifayemi sọ siwaju si pe “to ba jẹ Oro to maa n kun, eyii to maa n jade loru, obirin kii lọwọ nibẹ.
“Ṣugbọn gbogbo aṣa idile yoku bii ki eeyan ka oriki, ka bọ baba, ka bọ iya, ka bọ eegun, ko si ẹni ti ko le ṣe, lọkunrin lobinrin lo n le ṣe .
“Eyii yoo wa ni ilana bi aṣa idile wọn ba ṣe lọ nitori bi a ṣe n ṣe ni idile kan yatọ idile miran, aṣa oro idile le yatọ diẹdiẹ sira wọn.
Elebuibon ni ko si ẹni ti ko le kopa nibi oro idile nitori oro idile yatọ si oro ilu.
Ewu to wa fun obinrin to ba foju ri oro
Araba Awo ilu Osogbo ṣalaye pe to ba jẹ oriṣa gbogbo ilu bii Ọya tabi Sango to jẹ obinrin ni yoo gbe igba rẹ lorukọ gbogbo ilu, obinrin le ṣe e ti nnkankan ko si ni ṣe obinrin naa.
Amọ o fikun pe, obinrin to ba fi oju ri oro ti obinrin kii wo, ewu nla lo wa nibẹ fun irufẹ obinrin bẹẹ.
O ni “Obinrin to ba wo Oro ti wọn kii wo, obinrin bẹẹ le ṣaisan, o si le ku.”
Kàyééfì ńlá! Obìnrin kan pe Orò, tí Orò sì ń dáhùn

Oríṣun àwòrán, Others
Yoruba bọ wọn airin jina lai ri abuke ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.
Nilẹ kaarọ oo jiire, obinrin ko gbọdọ foju ri oro, debi pe yoo pe oro, ti oro yoo si jẹ.
Wọn ni awo Egungun ni obinrin le se, awo Gẹlẹdẹ ni obinrin le wo, bi obinrin ba fi oju kan Oro, Oro yoo gbe.
Amọ niluu Iyoko to wa labẹ ipinlẹ Isakete lorilẹede Benin Republic, obinrin gan an lo n pe oro, ti oro si n da a lohun.
Yoruba maa n sọ pe eti ni obinrin fi n gbọ ohun Oro.
Sugbọn lọjọ kejidinlogun oṣu Kẹjọ to kọja lọ yii, obinrin kan pe Oro niluu Iyoko nibi ayẹyẹ ọdun Oro to maa n waye kaakiri ilẹ Anago lorilẹede Benin Republic.
"Igbagbọ awọn araalu Iyoko ni pe obinrin lo ni Oro, ti wọn si maa n pe Oro"
Ọgbẹni Moufoutaou Aakadiri, to jẹ ọmọ ilẹ Anago ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe igbagbọ awọn araalu Iyoko ni pe obinrin lo ni oro.
Ọgbẹni Aakadiri ni niṣe ni inu awọn obinrin maa n dun ti ọdun Oro ba ti bẹrẹ niluu Iyoko.
"Oriṣiiriṣii ọdun ibilẹ bi ọdun egungun, ọdun Sango, ọdun Oro ati bẹẹ bẹẹ lọ lo maa n waye niluu Iyoko.
Amọ, lasiko ọdun Oro, obinrin lo maa n pe oro niluu Iyoko eyi to jẹ kayeefi nla.
Ti ọjọ ọdun Oro ba ku ọla ni gbogbo araalu yoo peju si ojude ibudo Oro.
Níbẹ ni wọn maa ti n pe Oro, ti Oro yoo si dawọn lohun.
Ti Oro ba ti dahun tan, ni onikaluku yoo maa ṣe adura ti wọn yoo si maa beere ohun ti wọn n fẹ.
"Ọkunrin lo maa n pe Oro ni gbogbo ilẹ Anago, amọ ti Ilu Iyoko yatọ"
Bayii ni oro yoo si maa ke nibẹ ti gbogbo eeyan yoo si maa gbọ.
Niṣe ni idunnu maa n ṣubu layọ fun gbogbo araalu ti wọn ba pe oro ti oro ba si dahun.
Gbogbo awọn alaṣẹ ilu patapata ni wọn yoo bẹrẹ si ni gbadura nibẹ.
Didahun oro ti wọn ba pe e tumọ si pe ọdun ti gba," Ọgbẹn Aakadiri lo sọ bẹẹ.
O fikun alaye rẹ wi pe ti wọn ba pe oro ti ko ba dahun, eyi tumọ si pe ọdun ko gba niyẹn.
Ọgbẹni Aakadiri ni idile kan wa niluu Iyoko to jẹ wi pe awọn obinrin lo maa n pe oro níbẹ.
O ni idile yii ni obinrin to pe oro nibi ọdun oro to bẹrẹ lọjọ kejidinlogun oṣu Kẹjọ to kọja ti wa.
















