Ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ikú Mojisola Awesu tí wọ́n bá lórí àkìtàn Ilorin, adájọ́ pàṣẹ àhámọ́ fún afurasí mẹ́rin

Mojisola Awusu

Oríṣun àwòrán, bbc/Mojisola Awusu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ile ẹjọ Majisreeti to kalẹ si ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara ti bẹrẹ igbẹjọ lori iku ọmọ ọdun mọkanlelogun kan, Awesu Mojisola to jẹ akẹkọọ Kwara State College of Health Technology, Offa.

Gẹgẹ bi iwe alaaye ọlọpaa ṣe gbe e kalẹ, awọn olujẹjọ lori iṣẹlẹ naa ni Adebayo Joshua Happiness ẹni ọdun mọkanlelogun, Kolawole Timilehin ọmọ ọdun mẹrinlelogun, Adebayo Adeniyi to jẹ ẹni ọdun mọkanlelaadọta ati Adeniyi Bukola tii ṣe ẹni ọdun mọkandinlaadọta.

Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni igbimọpọ, ipaniyan, ole jija, iperaẹni loun ti wọn ko jẹ, bibo ẹri ẹsun mọlẹ to fi mọ iluni ni jibiti ori ayelujara.

Iwaju adajọ agba, Wahab Saka ni wọn ti kawọ pọn rọjọ lori ẹsun naa ti ọlọpaa fi kan wọn.

Bawo ni igbẹjọ ṣe lọ?

Lẹyin ti wọn awọn ẹsun naa niwaju ile ẹjọ tan ni ikọ agbẹjọro awọn olujẹjọ ti ọgbẹni Iwalaye jẹ ọga fun pe fun beeli.

O ṣalaye pe awọn onibara oun yoo ma wa ile ẹjọ ni gbogbo ọjọ igbẹjọ.

Ṣugbọn agbefọba ASP Isaac Yakub tako o, o sọ pe ẹsun naa niiṣe pẹlu ipaniyan ti wọn ko si le dede gba beeli tabi oniduro fun.

Adajọ agba Wahab Saka gba si i lẹnu, o si pasẹ ahamọ fun wọn ni ọgba ẹwọn ile atunse Oke-Kura ni Ilọrin.

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kejila, osu kẹsan-an, ọdun 2024.

Ọwọ́ ọlọ́pàá Kwara tẹ afurasí mẹ́fà lórí ikú Mojisola Awesu tí wọ́n bá òkú rẹ̀ lórí àkìtàn

Mojisola Awesu

Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara ti ṣafihan awọn afurasi mẹfa lori iku ọmọ ọdun mọkanlelogun kan, Awesu Mojisola, to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ Kwara State College of Health Technology, Offa.

Awọn afurasi yi ni, Adebayo Joshua Happiness, Adebayo Adeniyi, Adeoye Adeola, Bulus Peter atawọn obinrin meji, Adeniyi Bukola ati Lawal Aminat.

Gẹgẹ bii Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ naa ti wi, oloogbe ọhun ni wọn pa ni ile itura kan ni ilu Ilorin, to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe iṣẹlẹ naa waye ni ọjọ kẹsan-an, osu Kẹjọ, ọdun 2024 nigba ti Awesu Mojisola gba ipe lati ọdọ Kolawole Timilehin, ti oun naa jẹ akẹkọọ binrin ile ẹkọ kan naa.

Ki ni iwadii ọlọpaa sọ?

Mojisola Awesu
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọlọpaa ni “Timilehin jiṣẹ Adebayo Joshua Happiness, ẹni to jẹ akẹkọọ fasiti Summit ni ilu Offa, pe ki o tẹle oun lọ si ode ariya ni ile itura Whitefield ni ilu Ilorin, ko si ṣe bi ọrẹ binrin rẹ lati gba owo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun marundinlogun naira.”

CP Olaiya sọ pe, “nigba ti Mojisola de ibẹ lo fi atẹjisẹ ransẹ si ọrẹ rẹ pe ibi ti Happiness mu oun wa ko tẹ oun lọrun nitori ko si ayẹyẹ kankan ṣugbọn oun ati Happiness nikan ni wọn wa ninu yara ti Happiness si n fa igbo.

“O ni lẹyin igba naa ni ago rẹ ko lọ mọ ti wọn ko si mọ ibi to wa

“Lẹyin ti wọn fi ọrọ naa to ọlọpaa leti ni a bẹrẹ iwadii to munadoko, a si nawọ gan Adebayo Joshua Happiness.

“Iwadii fihan pe Adebayo Joshua Happiness tan Awesu Mojisola lọ Ilorin ni, o si gba yara ni nnkan bii ago mẹfa laisi ero a ti ṣe ariya kankan.

“Iwadii tun fidi rẹ mulẹ pe Adebayo Joshua Happiness tun gba yara fun obinrin mii nile itura kan naa lati fi ṣe boju-boju fun iṣẹ ọwọ rẹ.

“Ni afẹmọju ọjọ kẹwa, osu Kẹjọ, ọdun 2024, Adebayo Joshua Happiness ṣeku pa Awesu Mojisola, o fi iyoku ara rẹ kalẹ sile itura naa, o si salọ pẹlu ẹrọ ibanisọrọ iPhone ati owo ẹgbẹrun marundinlogun naira to jẹ ti oloogbe ọhun.

Ọlọpaa tẹsiwaju pe “lẹyin naa lo pada si ilu Offa, o si fi ẹrọ iPhone to ji pamọ si akata rẹ"

“Lẹyin ti ọwọ tẹ Happiness tan ni awọn obi rẹ n gbiyanju lati bo awọn ohun to le jẹ bi ẹri lori iṣẹlẹ naa mọlẹ.”

"Awọn oṣiṣẹ ile itura lo ju oku Misola sori akitan"

Mojisola Awesu

Oríṣun àwòrán, Mojisola Awesu

Àkọlé àwòrán, Mojisola Awesu ṣaaju iku rẹ

CP Olaiya ni dipo ki awọn oṣisẹ ile itura naa ti wọn wa ni ibisẹ lọjọ ọhun fi ọrọ naa to ọlọpaa leti, niṣe ni wọn lọ gbe oku oloogbe ọhun sọ sori akitan nigba ti wọn rii.

O fi kun un pe awọn obi atawọn oṣisẹ ile itura naa ni ọlọpaa ti mu nitori wọn bo ẹri lori iṣẹlẹ laabi naa mọlẹ.

"Emi kọ lo pa Mojisola"

Nigba ti BBC fọrọ wa Adebayo Joshua Happiness lẹnu wo nibi afihan naa, o ni ọrẹbinrin oun ni Kolawole Timilẹhin jẹ ti awọn si ma n ni nnkan papọ sugbọn tori pe ko le ba oun wa si Ilorin lọjọ naa lo ṣe ṣeto ọrẹ rẹ, iyẹn Awesu Mojisola fun oun.

Adebayo Joshua Happiness sọ pe, oun to sẹlẹ ni pe, Awesu Mojisola ko gba ki oun ba oun ni ajọsepọ nile ni Ilorin ni oun ṣe lọ gba yara mii pẹlu obinrin miran lati tẹ ara oun lọrun.

O salaye pẹlu omi loju pe oun ko mọ nnkankan nipa iku oloogbe naa.

Nitirẹ, Adebayo Adeniyi to jẹ baba Adebayo Joshua Happiness, sọ fun BBC Yoruba pe, "mi o mọ nkan mii ti mo le sọ ju pe ọmọ mi tọwọ mi bọ wahala, nitori Offa ni awa wa, ṣugbọn Ilorin lo ti gbe ọmọ lọ sile itura ti ọmọ si ti ku, ninu eyi to n sọ pe oun kọ ni oun pa a titi di asiko yii.

“Ninu ile, ọmọ mi n ṣisẹ Ọlọhun, to ba si ṣe aṣemaṣe, gẹgẹ bii obi a maa n bawi.

“Offa lawa wa, Ilorin loun wa, kosi nnkan to fi kan wa lẹyin pe mo lọ ko ẹru rẹ ni ile iwe.”

Ẹwẹ, BBC Yoruba tun ba agbẹjọro Adebayo Joshua Happiness ati awọn obi rẹ sọrọ, o bẹbẹ kafi orukọ bo oun lasiri.

Agbẹjọro naa sọ pe, gbogbo ohun to sẹlẹ bayi ko ti kọja iwadii awọn ọlọpaa, o ni koda oun ko tii ni anfani lati ba awọn onibara oun sọrọ ayafi lati okere.

O ni awọn ọlọpaa n fi ọwọ lile mu-un nitori bi iṣẹlẹ naa se jẹ atawọn to ti tara bọ ọ.