Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin he lẹ́yìn tó gbé igbó pamọ́ sínú ọkọ̀ ìyàwó rẹ̀

Aworan igbo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkunrin kan lorilẹede Singapore ti dero ẹwọn ọdun mẹrin lẹyin to gbiyanju lati ṣakoba fun iyawo rẹ ti wọn o jọ gbe papọ mọ nipa gbigbe igbo pamọ sinu ọkọ obinrin naa.

Tan Xianglong ẹni ọdun mẹtadinlogoji ni o gbe igbo idaji kilo sori ijokoo to wa lẹyin ọkọ iyawo lati daran si i lọrun ki ijọba si le da ẹjọ iku fun obinrin naa fun gbigbe egbo igi oloro.

Orilẹede Singapore ni awọn ofin to lagbara eyi to tako oogun oloro gbigbe, tita, tabi lilo rẹ.

Iroyin fidi rẹ mulẹ pe Tan dẹru ba obinrin naa ati pe o tun fẹ ko ṣe nnkan to lodi sofin orilẹede Singapore.

Ile ẹjọ ni o ye Tan wi pe awọn ọlọpaa yoo mu obinrin naa, wọn yoo si fẹun nla kan an ti ohun toun gbimọ lati ṣe fun un ba kẹsẹjari.

L’Ọjọbọ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii ni ile ẹjọ dajọ ẹwọn ọdun mẹta ati oṣu mẹwaa fun Tan lori ẹsun wi pe igbo wa lọwọ rẹ lọna aitọ.

Ile ẹjọ tun ṣagbeyẹwo ẹsun mii wo pe o n gbin igbo eleyii to lodi sofin.

Ọdun 2021 ni Tan ṣe igbeyawo pẹlu aya rẹ, ti wọn si fi ara wọn silẹ lẹyin ọdun kan.

Tọkọ taya gbọdọ gbe papọ fun ọdun mẹta ki wọn to le kọ ara wọn silẹ ni Singapore

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tan ati iyawo rẹ ko le kọ ara wọn silẹ labẹ ofin tori pe awọn lọkọ laya ti wọn ba ti wa papọ fun ọdun mẹta o kere tan ni ofin Singapore faye gba lati kọ ara wọn silẹ.

Tan ro pe ofin naa le yipada foun ti iyawo oun ba jẹbi ẹsun iwa ọdaran.

Ninu ọrọ atẹjiṣẹ to kọ si ọrẹbinrin rẹ lori Telegram ni Tan ti sọ pe oun ti ri ọna ti iyawo rẹ ti wọn ko jọ wa papọ mọ ti le di ọdaran.

Lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa ni Tan ra igbo ti o si gbin in sinu ọkọ iyawo rẹ lọjọ keji.

Amọ, Tan ko mọ pe kamẹra wa ninu ọkọ iyawo rẹ to ka gbogbo nkan ti Tan ṣe silẹ.

Iyawo rẹ lawọn ọlọpaa kọkọ mu lẹyin ti wọn ri igbo ninu ọkọ rẹ, amọ wọn mu Tan fun ra rẹ lẹyin ti wọn ko ri nnkan kan to lodi sofin pẹlu iyawo rẹ.

Agbẹjọro Tan sọ fun ile ẹjọ wi pe Tan ni saisan iporuuru ọkan nigba to gbin igbo sinu ọkọ iyawo rẹ.

Ṣugbọn ile ẹjọ sọ pe esi ayẹwo awọn dokita lori Tan ko fidi rẹ mulẹ pe o ni iporuuru ọkan.

Lilọ sẹwọn ni ijiya ki wọn ka oogun tabi egboogi oloro mọ eeyan lọwọ ni Singapore nigba ti idajọ iku wa fun ẹnikẹni ti wọn ba gba mu pe o n fi oogun oloro ṣe kata-kara.