Àwa ni ìyanṣẹ́lódì táwọn dókítà gùnlé ń ṣàkóbá fún - àwọn aláìsàn kọminú

Ìyanṣẹ́lódì tí àwọn dókítà ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ ìyẹn Association of Resident Doctors (NARD) gùnlé láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ, ọdún 2024 ló ti ń ṣàkóbá fún àwọn èèyàn tó nílò ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Ní ìpínlẹ̀ Kano, ọ̀pọ̀ àwọn aláàárẹ̀ ló ń kọminú pé àwọn kò rí dókítà tọ́jú àwọn látàrí ìyanṣẹ́lódì náà.
Àwọn dókítà ní àwọn gùnlé ìyanṣẹ́lódì láti jẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ jí gìrì sí gbígba ìtúsílẹ̀ ọ̀kan lára wọn, dókítà Ganiyat Popoola, tó ti wà ní àkàtà àwọn ajínigbé láti inú oṣù Kejìlá, ọdún 2023.
Ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ní ilé ìwòsàn Aminu Kano Hospital ló ti ń wá ìtọ́jú lọ sí àwọn ilé ìwòsàn aládàni.
Ọkùnrin kan tó gbé aláìsàn lọ sílé ìwòsàn náà ní àwọn dókítà kò ṣe ìtọ́jú èèyàn òun, ó ní wọ́n sọ fún òun pé àwọn ń yanṣẹ́ lódì àti pé ìṣllẹ̀ pàjáwìrì nìkan ni àwọn lè mójútó báyìí.
“Kìí ṣe ohun tó dára rárá, ó dùn wá, àmọ́ kò sí nǹkankan tí alè ṣe àyàfi ká gbé èèyàn wa lọ sílé ìwòsàn mìíràn.
“Ní tèmi, ìyanṣẹ́lódì yìí kìí ṣe ìdí tí àwọn dókítà kò fi ní máa tọ́jú àwọn aláìsàn, wọ́n kàn fẹ́ fi fa ìjọba létí ni àti pé àwọn aláìsàn tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ ni ìpinnu wọn yìí ń ṣe àkóbá fún báyìí.
“Ìyanṣẹ́lódì tí wọ́n gùnlé kò ní kí ìjọba rí ẹni tí wọ́n jí gbé gbà sílẹ̀, kò sì ní kí àwọn ajínigbé tú akẹgbẹ́ wọn sílẹ̀, ará ìlú ni wan kàn ń fi ìyanṣẹ́lódì náà kóbá.”
Obìnrin mìí tún sọ pé láti ìgbà tí òun ti dé ilé ìwòsàn, òun kò rí dókítà tọ́jú àwọn nítorí ìyanṣẹ́lódì náà.
Ó ṣàlàyé pé kò sí nǹkan tí òun lè ṣe nítorí kò sí owó lọ́wọ́ àwọn láti lọ sí ilé ìwòsàn aládàni.

Bákan náà ni ọmọ ṣe ṣorí ní ilé ìwòsàn olùkọ́ni University of Port Harcourt Teaching Hospital (UPTH) bí àwọn aláìsàn ṣe ń sọ ipa tí ìyanṣẹ́lódì náà ń ní lára wọn.
Wọ́n ní àwọn kò rí àwọn dókítà tó ń ṣe ìtọ́jú àwọn tẹ́lẹ̀ láti tọ́jú àwọn tẹ́lẹ̀ mọ́ àyàfi àwọn àgbà dókítà ní ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn nọ́ọ̀sì tó ń dá àwọn èèyàn lóhùn.
Arábìnrin Patricia, tó ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn náà ní ó ń pẹ́ kí àwọn tó rí dókítà, kò sì rọrùn rárá tí àwọn èèyàn sì nílò láti padà sílé nítorí àwọn dókítà náà kò máa dá àwọn èèyàn púpọ̀ lóhùn.
Patricia ní ohun tó lé ní wákàtí méjì ni òun ti lò lé sí iye ìgbà tí òun fi ń dúró láti rí dókítà tí òun sì ní ìrètí pé wọ́n máa dá òun lóhùn.
Ní ìlú Abuja, akọ̀ròyìn BBC Pidgin fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìwòsàn tó jẹ́ i ìjọba ni kò sí àwọn dókítà níbẹ̀.
Ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní ẹkùn Wuse tí ẹsẹ̀ kìí gba èrò níbẹ̀ ló dá páropáro pẹ̀lú àwọn aláìsàn péréte tó fẹ́ rí dókítà.
Òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà ní ẹni tó bá fẹ́ rí dókítà nílò láti wá láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó ń bọ̀, nígbà tí àwọn dókítà yóò padà sẹ́nu iṣẹ́.

Ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní ẹkùn Wuse tí ẹsẹ̀ kìí gba èrò níbẹ̀ ló dá páropáro pẹ̀lú àwọn aláìsàn péréte tó fẹ́ rí dókítà.
Òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà ní ẹni tó bá fẹ́ rí dókítà nílò láti wá láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó ń bọ̀, nígbà tí àwọn dókítà yóò padà sẹ́nu iṣẹ́.
Aláìsàn kan tó wá fún ìtọ́jú nílé ìwòsàn náà sọ fún BBC Pidgin pé òun yóò mórí lé ilé ìwòsàn ti ẹkùn Garki nítorí wọn kìí lọ fún ìyanṣẹ́lódì níbẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ìwòsàn ìjọba ni òhun náà, ìjọba ti gbé ilé ìwòsàn ọ̀hún fún aládàni kan àmọ́ owó tí aláìsàn ń san níbẹ̀ pọ̀ ju àwọn ilé ìwòsàn tó jẹ́ ti ìjọba mìíràn lọ.
Ǹjẹ́ ìyanṣẹ́lódì yìí bí ohun tí àwọn dókítà náà ń fẹ́?
Alága ẹgbẹ́ àwọn dókítà ní ilé ìwòsàn olùkọ́ni University of Port Harcourt Teaching Hospital, Dókítà Noble Dumbari Mbooh ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé akẹgbẹ́ àwọn kò ì tíì gba ìtúsílẹ̀, ọ̀pọ̀ ará ìlú ló ti mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà báyìí àti pé ìjọba àpapọ̀ ti ṣèlérí láti wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà.
Mbooh ní òun k]ò ní sọ ohunkóhun lórí òfin ìjọba àpapọ̀ pé ẹni tí kò bá ṣiṣẹ́ kò ní gba owó oṣù àmọ́ òun gbàgbọ́ pé ìyanṣẹ́lódì tí àwọn gùnlé ń so èso rere fún àwọn lórí ọ̀rọ̀ akẹgbẹ́ àwọn tó wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé.
Ó ní tó bá jẹ́ pé ìjọba ṣe ohun tó yẹ láti ri pé wọ́n gba ìtúsílẹ̀ rẹ̀ láti oṣù Kejìlá ọdún tó kọjá, àwọn kò ní máa lọ fún ìyanṣẹ́lódì báyìí àti pé bí akẹgbẹ́ àwọn ṣe máa kúrò ní àkàtà àwọn ajínigbé ni àwọn ń wá.
Ó ní ìrètí àwọn ni pé nígbà tí ìyanṣẹ́lódì àwọn fi máa wá sópin lọ́jọ́ Ajé, Dókítà Ganiyat Popoola ma ti gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àkàtà àwọn ajínigbé.
Ó sọ pé àwọn máa ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn adarí ẹgbẹ́ àwọn láti mọ ìgbésẹ̀ tó kù tí àwọn yóò gbé nígbà tí ìyanṣẹ́lódì fi ma wá sópin.
Ìjọba àpapọ̀ yóò lo òfin 'kò síṣẹ́, kò sówó' fún àwọn dókítà tó yanṣẹ́lódì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede Naijiria ti sọ pe inu awọn ko dun lori ipinnu awọn ọmọ ẹgbẹ dokita to n gbe ninu ọgba ileewosan ṣe bẹrẹ iaynṣẹlodi ọlọjọ meje.
Ileeṣẹ eto ilera sọ pe ko tọ ọ bi awọn dokita naa ṣe yan iṣẹ lodi lai fi gbogbo akitiyan ijọba lori awọn nnkan ti wọn n fẹ ṣe.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ eto ilera, Ado Bako, fi sita, o ni ijọba ti sẹtan lati ṣamulo ofin “Ko si iṣẹ, ko sowo” fun gbogbo ọjọ ti iyanṣẹlodi naa ba fi waye.
Nnkan ti eyi tumọ si ni pe, ijọba yoo yọ owo gbogbo iye ọjọ ti awọn dokita naa ko fi ṣiṣẹ kuro lara owo oṣu wọn.
Bako sọ pe igbesẹ yii ko tumọ si pe ti gboju kuro lara awọn ẹdun ọkan awọn dokita naa, ṣugbọn o jẹ ọna alti ri i daju pe eto ilera ati iwosan fun anfaani araalu, ko dawọ duro.
Ọjọ Aje ni awọn dokita naa bẹrẹ iyanṣẹlodi ọhun lati fi ẹhonu han lori bi akẹgbẹ wọn, Dokita Ganiyat Popoola, ṣe ti wa ni ahamọ ajinigbe lati oṣu Kejila, ọdun to kọja.
Ọgbẹni Bako sọ pe awọn n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ alaabo lati doola dokita naa.
O ni awọn rọ awọn dokita lati tẹsiwaju ninu idunadura pẹlu ijọba.
Taa ni Dókìtà Ganiyat Popoola tí ẹgbẹ́ dókítà torí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì?
Awọn dokita ni ile iwosan ijọba lorilẹede Naijiria ti gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ meje kaakiri orilẹede Naijira lati kesi ijọba lori ọkan lara akẹgbẹ wọn, Ganiyat Popoolan ti awọn ajinigbe jigbe lọdun to kọja.]
Ninu oṣu kẹjila ọdun 2023 ni awọn ajinigba ji Dokita Ganiyat Popoola, ẹni to jẹ dokita ni ile iwosan National Eye Center niluu Kaduna pẹlu ọkọ rẹ ati aburo rẹ
Awọn ajinigbe yii tu ọkọ silẹ ninu oṣu kẹta ọdun 2024 sugbọn wọn kọ lati tu dokita ati aburo rẹ silẹ.
Owo toto Ogoji milọnu naira ni awọn ajinigbe yii n bere fun lọwọ mọlẹbi.
Ta a ni Dókítà Ganiyat Popoola?

Oríṣun àwòrán, NARD
Ile iwosan ijọba apapọ to n ri si itọju oju nipinlẹ Kaduna ni Dokita Ganiyat Popoola ti n ṣiṣẹ ki wọn too ji i gbe, oun si ni o n ri si akọsilẹ nile iwosan naa.
Bakan naa ni Dokita Popoola tun jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ dokita obinrin ni Naijiria.
Ọmọ marun-un ni Dokita Ganiyat Popoola bi.
Ọkọ rẹ, Nurudeen Popoola naa jẹ nọọsi, o si tun jẹ oṣiṣẹ nileeṣẹ ọmọ ogun oju ofurufu, nibi to ti di ipo 'Squadron Leader', mu.
Ọmọkunrin kan, AbdulMugniy Folaranmi, to jẹ ọmọ ẹgbọn Dokita Ganiyat ti wọn jọ ji wọn gbe, wa ni ipele akọkọ ni ileewe awọn ọmọ ogun oju ofurufu, (Airforce Institute of Technology, Kaduna).
Gẹgẹ bi Dokita Ebueburho Majirie, ṣe ṣalaye, o ni mọlẹbi Popoola ti san miliọnu lọna ọgọfa (120m) fun awọn ajinigbe ọhun, wọn si tun ko awọn nnkan miran fun wọn pẹlu, ki wọn le fi awọn ti wọn ji gbe naa silẹ.
Lori idi to fi ti pe oṣu mẹjọ ki akojọpọ awọn dokita too bẹrẹ ariwo pe ki wọn fi Popoola silẹ, Alukoro apapọ fun ẹgbẹ naa, Dokita Dele Abdullahi, sọ fun BBC pe,
‘’Awọn ẹbi n wa ọna ti wọn fi le fi ọgbọn gba wọn silẹ tẹlẹ, ṣugbọn nisinyi, wọn ti yọnda wa lati gbiyanju ọna abayọ tiwa naa’’
Ẹ fi ara dà wá - Àwọn dókítà bẹ àwọn èèyàn Naijiria

Oríṣun àwòrán, Others
Alaga ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, Dokita Noble Dumbari, lati ileewosan ẹkọṣẹ iṣegun to wa ni Port Harcourt, sọ fun BBC pe ki i ṣe pe idaṣẹsilẹ naa wu awọn, ai si ọna mi-in lo fa a.
Nigba to n sọrọ naa fun BBC lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii, Dokita Dumbari ṣalaye pe ijọba ko fẹẹ dahun si ohun ẹbẹ awọn.
" A o ti i ri esi gidi gba lati ọdọ ijọba, lẹyin ti a wọde lori ijinigbe ọkan lara wa. Eyi lo fa a ti a fi fẹẹ lo iyanṣẹlodi yii lati mu ijọba ji giri si ojuṣe wọn, nitori ijọba lagbara lati tu akẹgbẹ wa silẹ ninu igbekun.
" Ti a ba sọ pe idaṣẹsilẹ patapata, o tumọ si pe gbogbo iṣẹ ti awọn dokita n ṣe yoo dawọ duro lasiko iyanṣẹlodi naa, titi kan awọn ti wọn nilo itọju pajawiri, wọn ko ni i ri itọju kan.
" Awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka imọ ọtọọtọ (Consultants) yoo maa ba iṣẹ lọ, ṣugbọn awa dokita ko ni i ṣiṣẹ, eyi yoo si mu iṣẹ nira fun wọn, nitori awa ni a n ṣe ọpọ iṣẹ naa.
" A n rọ awọn to n gba itọju lati fi ara da wa lori iyanṣẹlodi yii, ki i ṣe ohun ti a kan deede gbe kalẹ’’
Dokita Dumbari lo ṣalaye bẹẹ.














