Wo bí o ṣe le pè fún ààbò lọ́wọ́ iléèṣẹ́ ológun tí o bá wà nínú ewu

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy
Ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria ti sọ pe awọn ti ṣagbekalẹ ikanni ti yoo mu ikansira-ẹni laarin awọn ati araalu rọrun lati le kọju ija sawọn agbebọn, paapaa nipinlẹ Zamfara ati Kebbi.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ologun gbe sita nipa wi pe awọn ti bẹrẹ sii gbogun ti awọn agbesunmọmi ati ajinigbe lẹkun ariwa-ila oorun Naijiria, jẹ ko di mimọ pe awọn ti ṣagbekalẹ ikanni ibanisọrọ ti awọn eeyan yoo pe lọfẹẹ, lai na owo kankan.
Wọn ni eyi yoo jẹ ki awọn oṣiṣẹ ologun mọ nigba ti araalu ba wa ninu ewu, ti wọn si nilo aabo pajawiri.
Wọn ni ọkan lara awọn alekun igbesẹ ti awọn n gbe lati dojukọ aisi eto aabo ni orileede Naijiria ni gbigbe ikanni ibara-ẹni-sọrọ ọhun jade, lati le koju ipenija to n koju araalu.
Bi iṣoro awọn agbesunmọmi ṣe n fojoojumọ peleke si, ni ileeṣẹ ologun sọ pe o faa ti wọn fi da eto lati pana eto Wilderness Operation Command silẹ.
Eto naa to n ṣabojuto eto aabo lẹkun naa, ileeṣẹ ologun sọ pe ọna abayọ tuntun ree ti yoo ṣe iranwọ fun eto ikansira-ẹni laarin awọn ologun ati araalu ti wọn ni adojukọ lawọn ilu naa.
“Ẹrọ ibanisọrọ tuntun 080-000-2020-2 lati fi lelẹ ki araalu le maa pe e tabi fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si lasiko ti wọn ba wa ninu ewu fun iranwọ pajawiri,” atẹjade ọhun sọ bẹẹ.
Ikọ Operation Hadarin Dajin wa pe araalu lati maa ṣamulo anfaani tuntun yii, lati le jẹ ki wọn ni iroyin ati imọ, eyi to ṣe pataki ninu gbigbogun ti awọn agbebọn.
Awọn agbebọn ti n pa awọn eeyan ti wọn si ti n ji awọn eeyan gbe lẹkun ariwa ila oorun Naijiria lati ọdun to pẹ diẹ sẹyin.
Koda, ni ọsẹ yii, wọn pa ọba ilẹ Gobi ni Gatawa lẹyin ti wọn jiigbe – eyi to fa ariwo ni Naijiria, paapaa fọnran rẹ to jade sita nibi ti wọn ti n fiya jẹ ẹ ko to di pe wọn pa a.
Ijọba Naijiria ati awọn ileeṣẹ eleto aabo lọpọ igba ni wọn ti n sọ pe awọn n sa ipa ati akitiyan lati dẹkun iwa ipaniyan ati ijinigbe, paapaa lati dẹkun awọn agbebọn, ṣugbọn ti iṣoro ọhun tubọ n peleke sii.















