Wo tọkọtaya tó ń gbá tẹníìsì orí tábìlì tó fẹ́ gbàmì ẹ̀yẹ fún Nàìjíríà ní ìdíje Paris Paralympics 2024

Tọkọtaya Christian ati Kayode Alabi

Oríṣun àwòrán, BBC Sport

Àkọlé àwòrán, Tọkọtaya Christian ati Kayode Alabi
    • Author, Emmanuel Akindubuwa
    • Role, BBC Sport Africa
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi idije Paralympics 2024 tii ṣe idije awọn elere idaraya to ni ipenija ara ti n kan ilẹkun gbọngbọn ni tọkọtaya Christiana ati Kayode Alabi n foju sọna lati gbami ẹyẹ fun Naijiria nibẹ.

Aṣiwaju ni Kayode ati Christiana ni isọri ti wọn wa ninu ere idaraya tẹniisi ori tabili ni ilẹ Afirika.

Christiana gba amí ẹyẹ fadaka ninu idije Commonwealth Games lọdun 2022 nigba ti ọkọ rẹ gba goolu meji ninu idije African Para Championship lọdun to lọ.

Lọdun 2017 ni irinajọ ifẹ wọn bẹrẹ lasiko igbaradi fun idije Commonwealth Games lọdun naa.

Kayode ni "2017 ni igba akọkọ ti Christiana wa si igbaradi fun idije tẹniisi ori tabili nilẹ okeere.

Mo si ri pe arẹwa obinrin ni."

Ṣugbọn kii ṣe lẹsẹkẹsẹ naa ni Christiana gba fun Kayode.

Bo tilẹ jẹ wi pe ilu Asaba nipinlẹ Delta ni Christiana n gbe, awọn mejeeji n pe ara wọn lori foonu.

Amọ, Christiana naa pada wa si ilu Eko lọdun 2019 lati maa gbe níbẹ.

"Nnkan ko rọrun rara fun mi niluu Asaba, lẹyin naa ni Kayode gba mi ni imọran pe ki n maa bọ l'Eko," Christiana lo sọ bẹẹ.

Lẹyin o rẹyin, ọdun 2022 ni wọn ṣe igbeyawo, bo tilẹ jẹ pe awọn kan ṣe ariwisi si Igbeyawo ọhun.

Christiana ṣalaye pe "awọn eeyan kan sọ pe bawo ni eeyan meji to ni ipenija ara ṣe le fẹ ara wọn, ṣugbọn awọn ẹbi wa gbaruku ti wa."

Bayii ni Kayode ati Christiana bẹrẹ irinajo ifẹ wọn gẹgẹ bi lọkọ laya.

"Christiana ti ṣe akọnimọọgba fun mi ni oriṣiiriṣii idije.

A maa jọ n ṣiṣẹ papọ ni, eyi to difa fun bi a ṣe jọ lọ fun idije Paralympics 2024 bakan naa," Kayode lo sọ bẹẹ.

"Ifẹ lo so wa pọ, amọ ipinnu wa lo n jẹ ka lọ siwaju"

Tọkọtaya Christiana ati Kayode Alabi nibi igbeyawo wọn.

Oríṣun àwòrán, Kayode & Christiana Alabi

Àkọlé àwòrán, Tọkọtaya Christiana ati Kayode Alabi nibi igbeyawo wọn.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Arun rọmọ lapa rọmọ lẹsẹ lo ṣakoba fun Kayode ati Christiana ti wọn fi di ẹni to ni ipenija ara.

Kẹkẹ t'awọn ti ara wọn ko ya maa n lo ni Christiana n lo lati fi rin nigba ti Kayode maa n lo nnkan lati rin tori ẹsẹ rẹ kan ni arun naa ṣakoba fun.

Christiana ni oun nìkan ni ọmọde to ni ipenija ara lawujọ ti oun ti dagba, eyi ti ko jẹ ki o rọrun foun rara.

"Mi o le lọrẹ, niṣe ni oju maa ti mi, ti mi o si ni le darapọ pẹlu awọn akẹgbẹ mi lati ṣere," Christiana ṣalaye.

Kayode ni tiẹ sọ pe awọn ọrẹ oun kan maa n pọn oun sẹyin nigba ti oun n dagba.

"O maa n nira fun mi lati wọ ọkọ lọ sile ẹkọ tabi sibi igbaradi ere idaraya.

Emi ni mo maa n wọ ọkọ kẹyin nigba naa tori ipenija ti mo ni," Kayode lo sọ bẹẹ.

Bo tile jẹ pe Kayode ati Christiana ti n gbe papọ gẹgẹ bi tọkọtaya, wọn ni awọn si tun n koju orisirisi iṣoro tori ipenija ara awọn.

Kayode ni awọn maa n koju iṣoro nipa ọkọ wíwọ lọ si ibi igbaradi awọn tori o maa n nira lati ri ọkọ to le gbe awọn pẹlu kẹkẹ ti iyawo oun fi n rin.

Akọsilẹ fihan pe ida awọn eeyan to ni ipenija ara to le ni 96% ni ko ni anfani si ohun amayedẹrun ti wọn nilo nilo ni Naijiria.

Amọ, Christiana maa n dunnu wi pe iṣọkan wa laarin oun ati ọkọ rẹ, bo tilẹ jẹ pe iṣoro ti wọn n koju pọ.

O ni Kayode n gbiyanju bẹẹ ni o si maa n ran oun lọwọ gan an.

Christiana ni Kayode lo maa n lọ ba oun ra nnkan mii toun ba nilo wa nigba ti oun o ba fẹ lọ sita.

O ni awọn si tun mọ bawọn ṣe n ṣe eto ọrọ owo laarin awọn mejeeji.

Tọkọtaya to fẹ gba ami ẹyẹ

Christiana gba ami ẹyẹ fadaka ni idije 2022 Commonwealth Games ni Birmingham

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Christiana gba ami ẹyẹ fadaka ni idije 2022 Commonwealth Games ni Birmingham.

Kayode ati Christiana ti mura si igbaradi wọn lati le gbami ẹyẹ ninu idije 2024 Paralympics niluu Paris.

Lẹyin igbaradi ti wọn n ṣe pẹlu awọn akẹgbẹ wọn, tọkọtaya yii tun maa n wo fidio igbaradi wọn nile lati le mọ ibi ti wọn ku si.

Awọn mejeeji jọ maa n le ara wọn lere ni.

Christiana lo kọkọ pegede lati kopa ninu idije Paralympics 2024.

Kayode ni eyi lo jẹ koriya foun naa lati karamọ ati pegede fun idije Paralympics ti yoo waye niluu Paris.

Inu Christiana dun pe awọn mejeeji ni wọn ti wẹ yan kan-in kan-in lati kopa ninu idije Paralympics 2024.

Christiana sọ pe "afojusun mi lati goke, lati mu iyi wa fun ẹbi mi ati orilẹede Naijiria ati ọkọ mi ẹni to ti n gbaradi pẹlu mi."

Wakati meji ni wọn maa fi n gbaradi ni aarọ.

Lẹyin ti wọn ba ni isinmi lọsan an, wọn yoo tun pada sibi igbaradi wọn ni irọlẹ.

Gbogbo akitiyan wọn da lori ati gba ami ẹyẹ ninu idije Paralympics to n bọ.

Bi Kayode ati Christiana ti foju sọna lati ṣoju Naijiria ninu idije Paralympics 2024, ohun to daju ni pe ọrọ ifẹ wọn yoo jẹ ohun iwuri fun ọpọ eeyan ni Naijiria ati kaakiri gbogbo agbaye.