Ìjọba Nàìjíríà kéde àlékún owó ìwé ìrìnna 'Passport'

Oríṣun àwòrán, Nigeria Immigration Service
Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti kede fífi owo kun owo gbigba iwe irinna bẹrẹ lati ọjọ kinni oṣu kẹsan an.
Eyi lo wa ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ẹka to n sọ bode, DCI Kenneth Udo fi síta fun awọn akọroyin.
O ni ijọba gbe igbesẹ yii lati ri pe oju lowo iwe irinna ní wọn n pese fun ọmọ Naijiria.
Udo salaye siwaju pe iwe irinna oni oju iwe mejidinlogoji to wa fun ọdun marun-un to jẹ ẹgbẹrun marindinlogoji naira tẹlẹ ti sun siwaju si ẹgbẹrun lọna aadọta naira.
Bakan naa, iwe irinna oju iwe mẹrinlelọgọta to wa fun ọdun mẹwaa to jẹ ẹgbẹrun aadọrin naira tẹlẹ ti sun siwaju si ẹgbẹrun lọna ọgọrun un naira.
Atẹjade naa tun jẹ ko di mimọ pe owo iwe irinna fun awọn araalu to wa ni oke okun ko yi pada.
Udo ni o ṣeese ki igbesẹ yii ni ọpọ ọmọ Naijiria lara sugbọn o fi da awọn eeyan loju pe igbesẹ naa da lori pipese oju lowo iwe irinna.

Oríṣun àwòrán, Others
Kí awọn araalu n sọ bayii?
Ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo ti jade sita lori ayelujara, ti wọn si n fẹhonu sita lori igbesẹ ìjọba lati fowo kun owo iwe irinna.
@Tosindeyforyou sọ pe ohun ti ìjọba ṣe lọwọ yìí ko dara to rara.
"Kí lo de tí nnkan n gbe owo lori ni orilẹede Naijiria?
@Jagabanolu ni iwa palapala ni igbesẹ yii
"Ni ilu to n san 70k gẹgẹ bii owo oṣu ni iwe irinna tí jẹ 50k.
"Wọn mọmọ gbe igbesẹ lati fi han pe awọn alagbara lo ṣe akoso wa."
@lidocaine_v2 ni kilode tí ìjọba ko lo owo miiran
"Ṣe a ko ti jiya to ni?"
@CuriousCourtnie ni gbogbo tí ìjọba n se ni lati ni awọn araalu lara lati kuro lorilẹede















