Àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ṣe agbódegbà bí afurasí apànìyàn tó pa èèyàn 42 ṣe sá kúrò ní àhámọ́ ti wọ gbaga

Afurasi ọdaran naa, Collins Jumaisi Khalusha

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Awọn ọlọpaa ṣi fi Khalusha si atimọle lasiko ti iwadii wọn ṣi n lọ lori iku ọgọrọ eeyan to waye nibẹ.
    • Author, Ian Wafula
    • Role, BBC News
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wọn ti da awọn ọlọpaa mẹjọ lorilẹede Kẹnya duro lori ẹsun pe awọn lo ran afurasi ọdaran apanijaye kan kuro ni ahamọ awọn ọlọpaa.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Kenya ṣalaye pe ọwọ tẹ afurasi ọdaran kan ti orukọ rẹ n jẹ Collins Jumaisi Khalusha, o si jẹwọ pe oun loun ṣekupa obinrin mejilelogoji, ninu eyi ti iyawo oun gan alara wa, laarin ọdun 2022 si ọdun 2024 ti ọwọ tẹẹ.

Agbẹjọro fun afurasi ọdaran ni irọ irọ ni ọrọ naa, o ni ṣe ni awọn ọlọpaa fi iya jẹ afurasi naa lati le sọ awọn ohun ti ko ṣe.

Inu ahamọ agọ ọlọpaa ni afurasi ọdaran naa wa lati oṣu keje ọdun 2024 ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ; amọ lọjọ Iṣẹgun ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe Ọgbẹni Khalusha atawọn mejila miran ti sa lọ kuro ni ahamọ ọlọpaa pẹlu iranlọwọ awọn eeyan kan to wa ni agọ ọlọpaa naa.

Iwe akọsilẹ ohun to ṣẹlẹ kan eyi to wa ni agọ ọlọpaa naa ṣalaye pe awọn ọlọpaa ṣe akiyesi pe awọn afurasi kan ti salọ ni nnkan bii agogo marun un owurọ agogo orilẹede naa nigba ti awọn ọlọpaa n gbe ounjẹ owurọ fun awọn afurasi to wa lahamọ naa.

Awọn afurasi mẹtala naa sa lọ lẹyin ti wọn ge irin ti wọn fi so orule ahamọ naa ti wọn si gba ori ogiri to yi agọ ọlọpaa na lọ.

Awọn mejila to sa lọ pẹlu Ọgbẹni Khalusha jẹ awọn ọmọ orilẹede Eritrea ti wọn mu fun wiwọ orilẹede naa lọna ti ko ba ofin mu.

Awọn ọlọpaa mẹjọ to wa lẹnu iṣẹ lasiko ti awọn afurasi ọdaran naa salọ ti lọ rọọkun nile bayii, bẹẹni iwadi si ti bẹrẹ lori rẹ gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede naa ṣe sọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọgbẹni Khalusha to jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn wọ gbaga ọlọpaa lẹyin ti awọn agbofinro ri awọn oku eeyan mẹsan ti wọn ti ge ẹya ara wọn wẹwẹ ni ibudo iwakusa kan ni ilu Nairobi tii ṣe olu ilu Kenya.

Ọjọ ori awọn eeyan to ku naa wa laarin ọdun mejidinlogun si ọgbọn ọdun, ilana iku kan naa ni wọn si fi pa gbogbo wọn.

Iku awọn eeyan wọnyi fa ọpọ ariwo lorilẹede Kenya, ti ọpọ si n kọminu lori bi awọn agbofinro ṣe kuna lati kẹfin iṣẹ buruku yii, ati bi o ṣe rọrun fun awọn ọlọpaa lati mu afurasi naa laarin ọjọ mẹta ti wọn ko si le ri ọdaran yii ki o to ṣe ọṣẹ gbogbo wọnyii.

Agbẹjọro fun ọgbẹni Khalusha, Amofin John Maina Ndegwa ṣalaye fun fun BBC loṣu keje: “o ni wọn fi tipatipa mu oun lati jẹwọ ẹṣẹ ti oun ko ṣẹ ni. Iri rẹ ṣe afihan ẹni to wa ninu iporuru ọkan.”

Gẹgẹbi iroyin ti ileeṣẹ akoroyinjọ AFP gbe jade, afurasi naa farahan ni ile ẹjọ kan ni ilu Nairobi ni ọjọ Ẹti to kọja nibi ti adajọ Majisireti to gbọ ẹjọ naa ni ki wọn fi si ahamọ fun ọgbọn ọjọ lati fun ọlọpaa lanfani lati pari awọn iwadii gbogbo ti wọn n ṣe.