Báǹkì àpapọ̀ yarí pé òun kò ní ṣiṣẹ́, àyàfi bí wọ́n bá tú òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jí gbé sílẹ̀

Aworan BAnki naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Banki apapọ orilẹede Libya ti dawọ iṣẹ rẹ gbogbo duro lẹyin ti awọn kọlọrọsi ajinigbe kan ji kan lara awọn oṣiṣẹ agba ni banki naa gbe ni ilu Tripoli.

Banki apapọ orilẹede Libya naa sọ pe awọn ajinigbe ji Ọgbẹni Musab Msallem to jẹ adari ẹkọ imọ ayelujara ni banki naa gbe ni ile rẹ lọjọ Aiku .

Wọn ni ọpọ awọn oṣiṣẹ banki naa lawọn kan ti n dun mọhurumọhuru mọ pe wọn yoo ji gbe.

Banki apapọ orilẹede Libya sọ pe awọn ko ni bẹrẹ iṣẹ pada, titi di igba ti awọn ajinigbe naa ba tu Ọgbẹni Msallem silẹ.

Banki apapọ orilẹede Libya da duro gedegbe ni bi o tilẹ jẹ pe orilẹede naa lo ni i. Oun si ni ileeṣẹ iṣuna kan ṣoṣo ti ajọ agbaye da mọ fun sisan owo epo orilẹede naa si.

Eyi n waye lẹyin ọsẹ kan ti awọn agbebọn ya bo banki apapọ naa, gẹgẹ bi ileeṣẹakoroyinjọ AFP ṣe ṣalaye.

Gẹgẹbi iroyin awọn ileeṣẹiroyin abẹle ti AFP tọka si, awọn agbebọn naa ṣe eyi lati ko gomina banki naa, Seddik al-Babir, ni papapmọra ki o le kọwe fi ipo rẹ silẹ.

Lati ọdun 2012, iyẹn ọdun mẹrinla sọ̀ẹyin ni Ọgbẹni al-Kabir ti wa nipo gẹgẹ bi gomina banki apapọ orilẹede Libya, bẹẹni oniruuru ika aleebu ni wọn ti na sii lori akoso iṣuna epo rbi orilẹede naaati ilana iṣuna orilẹede hun.

Lati igba ti olori orilẹede naa tẹlẹ, Muammar Ghadafi ti jade laye lọdun 2011, ni ẹsẹ eto ọrọ aje orilẹede naa ti n tase ara wọn.oniruuru awọn igun iṣejọba lo wa lorilẹede naa. Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ijọba meji lo wa lorilẹede Libya, ijọba ti ajọ iṣọkan agbaya da mọ, iyẹn to wa ni Tripoli, pẹlu ijọba to wa labẹ idahi Ọgagun Khalifa Hafta, lẹkun ila oorun orilẹede ọhun.